You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Egypt Air: Kí ló dé tí ikú tó pá Remilekun lọ́nà Egypt sì London ṣe di àdììtú?
Fakinfa lori iku arabinrin ọmọ orileede Naijiria kan to wọ baalu Egypt Air lọ si London ti o ṣadede ku ko to de ibi to n lọ ti gba ori ayelujara ni Naijiria.
Arabinrin Remilekun Meshioye la gbọ pe o wọ baalu ileeṣẹ ofurufu Egypt Air lati Eko lọ si London.
Ninu iroyin top gbode, Remilekun ṣadede ṣaarẹ ninu ọkọ ofurufu ti wọn si gbe lọ si ile iwosan ni Cairo.
Cairo ni wn lo ku si ti ko si si eeyan kankan to le sọ pato ohun to ṣekupa a.
Ẹbi, ọrẹ aati awọn ọmọ orileede Naijiria miran ti mu ọrọ ileeṣẹ ofurufu Egypt Air bẹnu ti wọn si ni wọn gbọdọ ṣalaye ohun to ṣekupa arabirin naa ati idi ti wọn fi pa oku rẹ ti si Cairo.
Idahun sawọn ibeere yi la gbiyanju lati wa taa si ri awọn nkankan dimu lalaye lori iṣẹlẹ yi.
Nibo ni baalu to gbe Remilekun ti gbera?
Papakọ ofurufu Murtala Muhammed ni ilu Eko ni baalu Egypt Air to gbe Remilekun Meshioye ti gbera lọjọ Kẹrin oṣu Kẹsan 2023.
Ilẹ Gẹẹsi ni ibudo ikẹyin to ti fẹ bọlẹ ninu baalu amọ baalu Egypt Air to gbe kọkọ ni lati duro wakati diẹ ko to tẹsiwaju ni Cairo lọ si London.
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe niṣe lo jẹ iyalẹnu fawọn mọlẹbi Remilekun nigba ti wọn gbọ pe arabinrin yi ko ba baalu de ni papakọ ofurufu Heathrow lasiko tawọn n duro de.
Punch sọ pe Arabinrin Olufunmilola Olaniyi Alabi to jẹ ẹgbọn Remilekun sọ pe awọn kan si ọfisi ileeṣẹ ofurufu Egyt Air tawọn wọnyi ko si kọkọ kọbi ara si ọrọ naa.
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn kan si ọfisi Egypt Air ni Cairo ti wọn si sọ pe lootọ ni Remilekun ko ba baalu de si London nitori o ṣaarẹ ni Egypt.
Egypt nilu Cairo ni wọn ti gbe Remilekun lọ si ilee iwosan to si pada jẹ Ọlọrun nipe.
Mọlẹbi Remilekun wa sọ pe ileeṣẹ ofurufu naa lawọn ti kan si ileeṣẹ aṣoju ilẹ Naijiria ni Cairo ti wọn si ti gbe oku Remilekun fun wọn.
Alaye yi ni mọlẹbi sọ pe o ku diẹ kaato nitori wọn ko kan si awọn titi di igba tawọn bẹrẹ si ni beere ibi ti Remilekun wa.
Amọ ohun ti ileeṣẹ ofurufu Egypt Air n sọ nipe ojuṣe fifi ọrọ to mọlẹbi wa lọdọ ileeṣẹ aṣoju Naijiria tawọn gbe oku le lọwọ.
Ki ni awọn alaṣẹ Naijiria sọ si ọrọ to wa nilẹ yi
Ileeṣẹ Iroyin BBC kan si agbẹnusọ ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ilẹ okere ni Naijiria iyẹn arabinrin Francisca Omayuli la ti tan imọlẹ si ọrọ to wa nilẹ yi.
Nigba taa pe lori ago o sọ pe ka fi awọn ibeere wa ṣọwọ wi pe oun yoo fesilori rẹ laipẹ.
Titi di akoko taa n ṣe akojọpọ iroyin yi, Fransisca ko ti fesi sawọn ibeere wa to da lori alaye ni pato ohun to ṣokunfa iku Remilekun ati pe ṣe lootọ lawọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu fi ọrọ to aṣoju Naijiria ni Egypt leti nipa iku Remilekun?
Bakan naa la ni ko mu alaye wa lori ẹni to yẹ ko fi ọrọ iku Remilekun to mọlẹbi leti ti ko tete ṣe bẹ debi pe awọn ẹbi rẹ n daamu titi ti wọn fi pada mọ wi pe Remilekun ku si Egypt.
Ni kete to ba mu idahun sawọn ibeere yi wa la o sẹ afikun rẹ ninu iroyin wa lati le jẹ ki ọrọ iku Remilekun yi lojutu si awọn to n wa idahun si ọpọ ibeere nipa rẹ.