You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ńjẹ́ o ti gbọ́ nípa ẹ̀rọ tó ń dènà wárápá? Àlàyé rèé lórí rẹ̀
Ọmọdekunrin kan, Oran Knowlson, ti di ẹni akọkọ l'agbaye ti wọn dan iṣẹ abẹ gbigbe ẹrọ igbalode kan sinu ọpọlọ rẹ, lati dena aisan warapa to n gbe e subu lọpọ igba.
Ẹrọ igbalode naa ni wọn sọ pe, o ti mu adinku ba bi ọmdekunrin naa ṣe maa n ṣubu lulẹ pẹlu ida ọgọrin.
Iya ọmọ naa, Justine salaye fun BBC pe, igbesẹ naa dun mọ oun ninu, bẹẹ ni wọn si ti bẹrẹ sini gbe igbe aye to nitumọ ju ti atẹyinwa lọ.
Iroyin fidi ẹ mulẹ pe, osu Kẹwaa, ọdun to kọja ni wọn ṣe iṣẹ abẹ naa nile iwosan Great Ormond Street Hospital towa ni ilu London, nigba ti Oran wa lọmọ ọdun mejila.
Ọmọ ọdun mẹta ni Oran wa, nigba ti ẹya aisan warapa kan, Lennox-Gastaut syndrome, ti bẹrẹ sini ba a finra, leyi to ti mu akude ba igbe aye ọmọde rẹ.
Iya ọmọ naa salaye fun BBC, ohun to ju rẹ ri nigba ti aisan warapa naa bẹrẹ sini ṣe ọmọ rẹ, o tọka sii pe, aimoye igba ni Oran maa n ṣubu, to si maa n farapa.
"Bakan naa lo maa n daku lọ rangbandan nigba miran, ki wọn to kesi awọn eleto ilera pajawiri lati wa ba wọn ji ọmọ naa ko to pada saye."
O ṣalaye siwaju sii pe, awọn aisan min to wọpọ fun awọn akanda ẹda ati ADHD ni ọmọ naa tun n koju, ṣugbọn aisan warapa naa lo jẹ eyi to lagbara ju.
Bí ẹ̀rọ náà ti ń ṣiṣẹ́ sí
Warapa lo maa n waye nigba ti ọpọlọ ba sọṣẹ silẹ lojiji, nipa bi imunawa rẹ yoo ti daru, bẹẹ ni ẹrọ igbalode naa si wa fun didawọ eyikeyi aṣiṣẹ isẹ duro.
Justine tii se iya Oran sọ fun BBC pe, ki iṣẹ abẹ naa to waye ni oun ti fẹran lati jẹ ki ọmọ oun tun pada wa ni alaafia to peye, nipa bi yoo ti bọ lọwọ aisan foniku fọla dide.
Arabinrin ọhun ṣalaye wi pe wakati mẹjọ ni wọn fi ṣe iṣẹ abẹ naa losu kẹwa ọdun 2023, ati wi pe wọn de ẹrọ naa mọ Oran lagbari, lẹyin ti wọn yọ awọn egungun to wa nibẹ kuro.
Iwadi fihan wipe, wọn ti figbakanri ṣe iru iṣẹ abẹ ọpọlọ fun awọn ọmọde ti aisan warapa ba n ṣe, ṣugbọn to je wipe ibi igba aya ni wọn maa n de ẹrọ naa mọ, pẹlu waya ti yoo maa ṣisẹ woọ inu ọpọlọ.
Martin Tisdall to jẹ oṣiṣẹ eleto ilera ṣalaye fun BBC pe, imọ naa ni wọn nigbagbọ pe yoo fun wọn ni ẹkunrẹrẹ imọ nipa boya irufẹ ẹrọ naa yoo lee dena aisan warapa.
O ni ilana ọhun lo jẹ eyi to tuntun, bẹẹ lo si wulo fun awọn ọmọde toripe ninu agbari ni ẹrọ naa yoo wa, kii ṣe ni igba aya, pẹlu ireti pe yoo mu adinku ba eyikeyi ipalara to ba ṣeeṣe ko tipasẹ iṣẹ abẹ naa jẹyọ tabi ti ẹrọ naa ba fẹ sọṣẹ silẹ.
Lẹyin ti iṣẹ abẹ naa waye, won fun Oran ni gbedeke asiko osu kan ki ara rẹ lee mokun daada lẹyin ti ẹrọ naa ti bẹrẹ ninu ọpọlọ rẹ.
Oran kii ni imọlara ti ẹrọ naa ba n ṣiṣẹ, bakan naa, o lee tun agbara ẹrọ naa ki nipasẹ lilo ina elentriki pẹlu ẹrọ agbeseti to fin gbọ orin, leyi tiko si dii lọwọ lati ṣe awọn nkan mii to ba fẹ.
Justine tii se iya ọmọ naa ṣalaye fun awọn oniroyin lasiko abẹwo wọn, lẹyin osu meje ti Oran la ipele iṣẹ abẹ naa kọja, pe iyatọ ailalẹgbẹ ti wa, nipa bi ẹrọ oun ti pinwọ bi warapa ṣe maa n gbe e subu lairo tẹlẹ.
Justine sọ pe “Alaafia rẹ ti n padabọ sipo diẹ die, toripe asiko isubu rẹ lalẹ naa ti dinku”
Martin Tisdall ko sai tun tọka sii pe inu wọn dun wi pe, Oran ati awọn ẹbi rẹ ti pada n gbe igbe aye alayọ nipa bi ilera ọmọ naa ti gbe pẹẹli sii.
Tisdall tọka sii pe, gbogbo igba ni awọn nọọsi maa n wa nitosi Oran boya ti nkan ba fẹ yiwọ, sugbọn ti wọn ko tii nilo wọn latigba naa.
O ni awọn ọmọde bii mẹta miran ti irufẹ eya aisan warapa, Lennox-Gastaut syndrome ba n fi lape ni yoo la ipele iṣẹ abẹ naa kọja.
Bi ọjọ iwaju igbesẹ naa yoo ti ri
Erongba ọjọ iwaju igbesẹ ọhun ni ikọ naa, ti ṣalaye wi pe wọn fẹ sọ di ojulowo, nipa bi ayipada yoo ti wonu isọwọ ṣiṣẹ ọpọlọ, lati lee mu adinku ba bi aisan warapa ṣe n gbe awọn eeyan subu.
Justine iya ọmọ naa sọ pe, idunu nla ni ọrọ naa mu ba ẹbi wọn, bi wọn ṣe mọ daada pe isẹ abẹ naa ko lee pa aisan naa pata pata, ṣugbọn ti wọn nireti pe yoo pinwọ aisan naa fun Oran diẹ diẹ.
Wọn ti ṣamulo irufẹ iṣẹ abẹ ọhun lati tọju aisan warapa ri ni ile iwosan kan nilẹ America.