You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléẹjọ́ wọ́gilé ìbò Rukayat Shittu ẹni ọdún 26 tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Kwara
Ileẹjọ to n ri si awuyewuye to jẹyọ ti wọgile ibo Rukayat Shittu, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn obinrin to bori ibo sile igbimọ asoju aṣofin ipinlẹ Kwara.
Shittu to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ajọ eleto idibo INEC kede gẹgẹ bi oludije to jawe olubori fun ẹkun Owode-Onire nijọba ibilẹ Asa ninu ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara to waye lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta ọdun 2023 yii.
Abdullahi Yinusa Magaji to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP lo pe ẹjọ tako Rukayat lori esi idibo naa.
Bakan naa ni Magaji pe ajọ INEC to kede Rukayat gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori naa lẹjọ ati ẹgbẹ oṣelu APC.
Adajọ Ademola Enikuomehin to jẹ ọkan lara awọn adajọ mẹta to ṣagbatẹru igbẹjọ naa paṣẹ pe ki atundi ibo waye ni ibudo idibo marun un.
Igbimọ igbẹjọ naa ṣalaye pe olupẹjọ kuna lati fidi rẹ mulẹ pe ki ileẹjọ yi ibo danu ni ibudo idibo mejila.
Amọ, atundi ibo yoo waye ni ibudo idibo marun un nibi ti igbimọ igbẹjọ ti yi ibo danu.
Bayii ni igbimọ igbẹjọ ti wọgile esi idibo naa wi pe ko fẹnu gun ibi kan.
Igbimọ igbẹjọ naa paṣẹ pe ki atundi ibo ọhun gbọdọ waye laarin oṣu mẹta si akoko idajọ yii.