Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Abuja pàṣẹ ìdádúró òfin tí NAFDAC fi de ọtí pẹlẹbẹ inú ọ̀rá

Ile igbimọ aṣọju-ṣofin orileede Naijiria to wa niluu Abuja ti paṣẹ idaduro ofin ti ajọ NAFDAC to n ṣakoso awọn ounjẹ jijẹ ati oogun ni Naijiria fi de ọti pẹlẹbẹ inu ọra titi digba ti iṣẹ iwadii yoo fi pari lori rẹ.

Igbimọ to n bojuto ajọ (NAFDAC) lo sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade ti alaga igbimọ naa, Regina Akume buwọ lu, o sọ pe awọn nilo lati ṣe iwadii kikun, lati mọ ọna ti awọn le gba labẹ ofin lati fofin de awọn ọti pẹlẹbẹ ati ọti inu igo kekere naa.

Akume ni awọn yoo wa ọna ti wọn yoo gba lati ma ṣe jẹ ki awọn ọti ọhun ma le wa ni arọwọto awọn ọmọde ati awọn ọmọ ile-ẹkọ.

Siwaju sii lo sọ pelara awọn ipinnu wọn ni lati jẹ ki ajọ NAFDAC ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bii iṣẹ, pẹlu bo tun ṣe sọ pe dida iṣẹ silẹ ati igbanisiṣẹ ṣe pataki ninu eto ọrọ aje orileede.

Akume tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn n wa ọna lati ma ṣe ṣoju saaju laarin ajọ NAFDAC ati awọn ileeṣẹ to n gbe ọti pẹlẹbẹ jade, nipa eto aabo awọn ọmọde.

Alakoso agba fun ajọ NAFDAC lorileede Naijiria, Ọjọgbọn Mojisọla Adeyẹye ti sọ ṣaaju pe ọna lati daabo bo awọn ọmọde, ọdọ ati awọn alaabọ lawọn n wa.

Adeyẹye kọminu lori igbesẹ ti awọn ileeṣẹ to n gbe awọn ọti pẹlẹbẹ naa jade, lẹyin to ni awọn ti jọ panupọ lori bi wọn yoo ṣe dena bi awọn ọmọde ṣe n mu awọn ọti naa, eyi ti wọn tun le ka si aṣilo oogun.

Ṣugbọn ninu ọrọ tiẹ, alakoso agba fun ẹgbẹ to n ṣakoso awọn ileeṣẹ to n pese nnkan lorileede Naijiria, Manufacturers Association of Nigeria (MAN), Ṣẹgun Ajayi-Kadir jẹ ko di mimọ pe niṣe lo yẹ ki ajọsọ ti yoo mu ọna abayọ lati dena bi ọti mimu ṣe n wa ni arọwọto awọn ọmọde.

O ni ki wọn ṣagbeyẹwo bi wọn ṣe fẹẹ fopin si ṣiṣẹ ọti pẹlẹbẹ jade, to si ni eyi le fa ki oriṣiriṣi ẹgboogi oloro tun jade lọpọ yanturu saarin ọja

Ajayi-Kadir fi kun ọrọ rẹ pe niṣe lo yẹ ki gbogbo awọn ti ọrọ kan jokoo papọ lati fẹnuko lori bi ọti ọhun ko ṣe nii si ni arọwọto awọn ọmọde, nitori pe awọn agbalagba ni wọn ṣe e fun.