Kí ni ìdájọ́ ilé ẹjọ́ àgbáyé, ICJ lórí ẹjọ́ tí South Africa pè tako ìwà ìpànìyàn ọlọ́gọ́ọ̀rọ̀ tí Israel hù, túmọ̀ sí?

    • Author, Dominic Casciani
    • Role, Home & legal correspondent

Ilé ẹjọ́ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, International Court of Justice (ICJ) ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ padà lórí ẹ̀sùn tí orílẹ̀ èdè South Africa fi kan pé orílẹ̀ èdè Israel kàn ń pa àwọn ènìyàn danu lásán lórí ogun tó ń wáyé ní Gaza, tí wọ́n sì ní kí ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún Israel láti ṣe ìdádúró ìkọlù tó ń wáyé ní Rafah.

Israel ní ẹjọ́ tí South Africa pè tako àwọn kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé àwọn máa fèsì lọ́jọ́ Ẹtì.

Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà ìyẹn International Court of Justice (ICJ) ni wọ́n ti ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ìgbà tí South Africa ti pe ẹjọ́ náà.

Lóṣù Kìíní ọdún yìí ni ICJ ti kọ́kọ́ gbé ìdájọ́ kan kalẹ̀ – kókó kan pàtàkì tó jẹyọ ni ìwòye ilé ẹjọ́ tó ní ẹ̀rí àtàwọn nǹkan tó rọ̀ mọ́ tó rọ̀ mọ́ ẹjọ́ tí South Africa gbé síwájú àwọn tó ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ẹ̀tọ́ tí South Africa ń jà fún ààbò jẹ́ ohun tó ṣe é gbàgbọ́.

Èyí ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tú bó ṣe wù wọ́n, tó fi mọ́ àwọn lámèyítọ́ lẹ́ka ètò òfin, láti fi túmọ̀ pé ilé ẹjọ́ ti pinnu pé ẹ̀sùn tí àwọn kan fi ń kan Israel pé ó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣekúpa àwọn èèyàn lọ́nà àìtọ́ ní Gaza jẹ́ ohun tó ṣe é gbàgbọ́ tàbí jẹ́ òótọ́.

Ìtumọ̀ tí àwọn èèyàn fún ọ̀rọ̀ yìí tàn káàkiri tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó jáde nínú àtẹ̀jáde àjọ UN, àwọn àjọ tó ń polongo tako Israel àtàwọn iléeṣẹ́ ìròyìn tó fi mọ́ BBC.

Ẹ̀wẹ̀, nígbà tó di oṣù Kẹrin, Joan Donoghue, ààrẹ ilé ẹjọ́ ICJ nígbà náà sọ fún BBC pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ àti pé ìdájọ́ kọ́ nìyẹn.

Ó ní dípò bẹ́ẹ̀, ohun tí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ náà ni àwọn fi sọ pé South Africa ní ẹ̀tọ́ láti gbé ẹjọ́ tako Israel wá sí ilé ẹjọ́ àti pé àwọn èèyàn Palestine ní ẹ̀tọ́ láti dá ààbò bò wọ́n lọ́wọ́ pípa wọ́n lọ́nà àìtọ́ - ẹ̀tọ́ lọ́wọ́ ìjàmbá tí kò lè ṣe é ṣe àtúnṣe sí mọ́.

Awọn adajọ ṣalaye pe awọn ko le sọ bayii boya iṣẹlẹ ki wọn mọmọ ba ibi kan waye sugbọn pinnu pe awọn nnkan ti orilẹede South Africa sọrọ nipa, ti wọn ba le fidi rẹ mulẹ, o le bọ ṣi abẹ ile ofin bi ba nnkan jẹ Ajọ agbaye United Nation.

Ẹ jẹ ka wo ibi ti igbẹjọ yii ti bẹrẹ ati bi igbẹjọ ṣe n lọ.

Ẹka ICJ ni wọn da silẹ wa ojutu si awọn ija to ba n jẹyọ laarin awọn orilẹede lagbaye labẹ ofin agbaye.

Eyi tumọ si pe wọn ti fẹnu ko laarin awọn orilẹede lori awọn nibi ipade apapọ lori iṣekupani ọlọgọrọ.

Adehun nlan ti wọn fẹnu ko le lori lẹyinj ogun agbaye keji, eyi to n tiraka lati dena pipa ọgọrọ eeyan

Losu kejila to kọja, orilẹede South Afrika ṣe ifilọlẹ igbesẹ kan nibi ilẹẹjọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran, (ICJ) lati fidi rẹ mulẹ pe Israel n ṣekupani lọgọrọ gẹgẹ bii o ṣe kan ogun to n gbe ti ikọ ologun Hamas lagbagbe Gaza.

O fẹsun kan ọna ti Israel n gba ja ogun naa jẹ “iwa iṣekupani lọgọrọ” nitori gẹgẹ bii ẹjọ orilẹede South Afrika ipinnu wa lati “pa awọn eeyan Palestine to wa ni agbegbe Gaza run”.

Amọ orilẹede Israel tako awọn ẹsun yii, o ni gbogbo ẹjọ naa lo tako iṣẹlẹ to wa nilẹ.

South Afrika nilo lati fi ẹri to daju mulẹ pe ipinnu wa lati ṣekupani lọgọrọ. Israel yoo wa ṣe ayẹwo awọn ẹri naa ni ẹyọ kọkan, ki wọn si ja niyan pe awọn igbesẹ rẹ lasiko ogun to waye laarin ilu, eyi to ba ni lẹru pupọ, o wa lati da bobo ara wọn ni ọna to tọ lọwọ ikọ ologun Hamas, eyi ti ọpọ awọn orilẹede ka wọn si ikọ agbesumọmi.

Orilẹede South Afrika wa n bere lọwọ awọn adajọ nile ẹjẹ ICJ lati kọkọ kede awọn igbesẹ ilana ẹjọ naa

Eyi ni ede ti wọn n lo fun aṣẹ ileẹjọ ICJ – eyi ti n ṣe aṣẹ ti adajọ pa pe ki wọn dawọ duro lori igbesẹ kan, lati dena sise ijamba si ara wọn, ko to di pe wọn gbe idajọ lori ẹjọ naa kalẹ.

Wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún Israel láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó máa dá ààbò bo àwọn ènìyàn Palestine tí kò sì ní mú ìpalára tí kò ní ìràpadà bá wọn.

Fún odidi ọjọ́ méjì ni àwọn agbẹjọ́rò fún orílẹ̀ èdè méjéèjì ń ṣe atótónu lórí pé ṣé Gaza ní àwọn ẹ̀tọ́ tí ilé ẹjọ́ nílò láti dá ààbò bò.

Ìdájọ́ yìí, tí àwọn mẹ́tàdínlógún jíròrò lórí rẹ̀ (tí ọ̀pọ̀ wọn lòdì sí) wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní.

“Níbi tí ìgbẹ́jọ́ yìí dé dúró, wọn ò ní kí ilé ẹjọ́ dájọ́ láti fì’di rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀tọ́ tíi South Africa ń bèèrè fún wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀,” ICJ sọ.

“Ohun tí ilé ẹjọ́ nílò láti ṣe ní láti wò ó pé ṣé ẹ̀tọ́ tí South Africa ń bèèrè fún ààbò rẹ̀ jẹ́ ohun tó tọ̀nà.

“Gẹ́gẹ́ bí ìwòye ilé ẹjọ́, àwọn ẹ̀rí àtàwọn nǹkan tó rọ̀ mọ́ ẹjọ́ tí South Africa pè tó sì sí ń bèèrè ààbò fún àwọn ènìyàn Palestine jẹ́ ohun tí fẹsẹ̀ múlẹ̀.”

Fífi ẹnu kò pé àwọn Palestine tó wà ní Gaza ní ẹ̀tọ́ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lọ́wọ́ ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́, wọ́n pinnu pé àwọn ènìyàn náà wà nínú ewu tó lè kó ìpalára ayérayé báwọn - àti pé Osrael ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti dènà ìpànìyàn ọlọ́gọ́ọ̀rọ̀.

Ilé ẹjọ́ kò ì tíì gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé Isarel jẹ̀bi ìpànìyàn ọlọ́gọ́ọ̀rọ̀ lọ́nà àìtọ́ – àmọ́ ṣé àwọn ọ̀rọ̀ tí ICJ túmọ̀ sí pé ó ṣeéṣe kí wan jẹ̀bi ẹ̀sùn náà? Èyí ló fa awuyewuye tó ń wáyé lórí ohun tí ilé ẹjọ́ sọ yìí túms sí gan.

Ní oṣù Kẹrin, àwọn agbẹjọ́rò Britain 600 tó fi mọ́ àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ tẹ́lẹ̀ rí mẹ́ri, kọ lẹ́tà ránṣẹ́ sí olóòtú ìjọba UK níbi tí wọ́n ti ń bèèrè pé kí UK ṣe ìdádúró títa nǹkan ìjà ogun fún Israel mọ́ pé wọ́n lè fi pa àwọn èèyàn lọ́nà àìtọ́.

Èyí mú kí àwọn agbẹjọ́rò UK tí wọ́n jẹ́ ti Israel (UKLFI). Àwọn agbẹjọ́rò náà tí iye wọn tó 1,300 ní nǹkan tí ICJ sọ ni pé àwọn Palestine tó wà ní Gaza ní ẹ̀tọ́ ààbò lọ́wọ́ ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́ – èyí tó túmọ̀ sí pé ẹjọ́ náà ta kókó díẹ̀, tí kìí sì ṣe nǹkan tó ṣe é fojú rí.

Ọ̀pọ̀ lẹ́tà àti àròyé lọ wáyé lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Bákan náà ni ẹjọ́ náà dé iwájú ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin lórí ìjíròrò bóyá kí UK fi nǹkan ìjà ogun ránṣẹ́ sí Israel.

Adájọ́ tẹ́lẹ̀ rí ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní UK, Lord Sumption sọ f;un ìgbìmọ̀ náà pé èrò òun ni pé, gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà àwọn agbẹjọ́rà UKLFI ṣe sọ ni pé ICJ ń gbé ìdája rẹ̀ lórí òfin tí kò ṣe é fojú rí, pé àwọn èèyàn Gaza ní ẹ̀tọ́ láti ri pé wọn ò máa pa wan lọ́nà àìtọ́.

Nígbà tó ń fèsì Natasha Hausdorff TÓ Jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò UKLFI ní ní òun kò gba nǹkan tí Lord Sumption sọ wọlé.

Ọjọ́ kan lẹ́yìn ni Joan Donoghue tó jẹ́ agbẹjọ́rò ICJ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó ti fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ báyìí kópa lórí ètò HARDtalk BBC tó sì ṣàlàyé ohun tí ilé ẹjọ́ ṣe.

“Ilé ẹjọ́ kò ì tíì pinnu – èyí sì ni àtúnṣe sí ohun tí wọ́n ń sọ lórí ìròyìn... pé ẹ̀sùn pé ìpànìyàn ọlọ́gọ́ọ̀rọ̀ ń wáyé jẹ́ ohun tó ṣe é gbàgbọ́.

Bóyá ẹ̀rí wà pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bàǹtàbanta báyìí wà nílẹ̀ kọjá ìbéèrè tí ilé le pinnu lé lórí.