Ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu àwọn adarí ológun àti aláàbò tuntun tí Tinubu yàn

Ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti buwọlu orukọ awọn adari ileeṣẹ ọmọogun ati ileeṣẹ alaabo ti aarẹ Bọla Tinubu ṣẹṣẹ dibo yan.

Ile ṣe ayẹwo ati iforowanilenuwo fun awọn adari eto abo Naijiria tuntun naa lọjọbọ.

Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Godswill Akpabio ṣalaye pe wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo nibi ijoko idakọnkọ ti ile naa ṣe.

Lọjọ Aje ni Aarẹ Tinubu kọwe ranṣẹ si ile naa pe ki wọn ṣe ayẹwo fun awon ti oun ṣẹṣẹ yan lati mojuto eto abo ni Naijiria.

Ọkọọkan awọn olori ẹka ologun naa titi kan ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn bọ si gbangba lati ṣalaye ọna ti wọn yoo gba mojuto ọrọ abo lorilẹede Naijiria, iyen bi ile ba buwọlu iyansipo wọn.

Awọn adari ileeṣẹ ọmọogun ti ile buwọlu

Ni ọjọ kọkandinlogun osu kẹfa ni Aarẹ Tinubu yọ awọn alamojuto eto abo ati ileeṣẹ ologun to wa nipo kasiko ti ijọba ana fi kogba wọle kuro nipo.

Awọn ogagun agba tuntun ti aarẹ yan, ti awọn aṣofin apapọ si buwọlu lọjọbọ niwonyi:

  • Ọgagunagba C.G. Musa – Olori ikọ ọmọogun ati alaabo lapapọ (CDS)
  • Ọgagunagba T.A. Lagbaja – Olori ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ (COAS)
  • Ọgagunojuomi E.A. Ogalla -Olori ileeṣẹ ọmọogun oju omi
  • Ogagunofurufu H.B. Abubakar -Olori ileeṣẹ omoogun ofurufu.
  • Ọgaagba ọlọpaa Kayode Ẹgbẹtokun - Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa
  • Ọgagun E.P.A. Undiandeye – Olori ileeṣẹ otẹlẹmuyẹ ọmọogun ( CDI)