You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"A fẹ́ ṣe àyípadà ìwé òfin Nàìjíríà"
Awọn eekan ọmọ orilẹede Naijiria kan ti jiroro pẹlu aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu lori ọna ati gbe iwe ofin tuntun kalẹ fun orilẹede Naijiria.
Lara awọn eekan naa ti wọn tan ka ẹka gbogbo Oloye Emeka Anyaoku, to figbakan ri jẹ akọwe agba fun ajọ iṣọkan orilẹede Commonwealth.
Igbimọ yii gbe amọran ṣiṣe iwe ofin tuntun fun orilẹede Naijiria kalẹ fun aarẹ Naijiria lẹyin ti wọn jiroro lori awọn wahala ati iṣoro to n koju orilẹede orilẹede Naijiria lọwọlọwọ.
Ọkan lara awọn ọmọ igbimọ naa, Kọmuredi Shehu Sani, to figbakan ri jẹ sẹnetọ to ṣoju ẹkun aringbungbun Kaduna ṣalaye fun BBC pe wọn fun aarẹ Tinubu ni amọran agbekalẹ iwe ofin tuntun nitori pe wọn lero pe oun gan ni orirun ọpọ iṣoro ti orilẹede Naijiria n koju lọwọlọwọ.
Sẹnetọ Sani ni lara awọn iṣoro naa ni eto abo, ọrọ oṣelu ati ajọṣepọ laarin awọn ẹya ati ede gbogbo to wa lorilẹede Naijiria ati iwa ijẹkujẹ lagbo ijọba.
O ni igbimọ naa ko gbagbọ pe orilẹede Naijiria nilo ile aṣofin meji lẹka apapọ, bẹẹni ko yẹ ki awọn minisita ju aadọta lọ. O ni bi o ṣe yẹ ki o ri niyi pẹlu bi eeyan ba gbe obitibiti owo ti wọn n na lori ilana iṣejọba to wa nmilẹ pẹlu iwe ofin ti Naijiria n lo lọwọlwọ yẹwo.
Sẹnetọ Shehu Sani ni awọn iṣẹ idagbasoke ati igbayegbadun awọn mẹkunu lo yẹ ki wọn maa na ọpọlọpọ awọn owo to n lọ si amojuto ilana iṣejọba wọnyii fun.
O ni igbagbọ igbimọ naa ni pe, ko si ohun rere kan to le ba ọrọ aje Naijiria labẹ iṣakoso iwe ofin ti Naijiria n lo lọwọlọwọ.
Gẹgẹbi ọrọ to sọ, aarẹ orilẹede Naijiria, Bla Ahmed Tinubu ti gba lati boju wo awọn amọran ti igbimọ naa gbe tọọ wa, pẹlu ileri pe oun yoo pe Oloye Emeka Anyaoku pada laipẹ lori ọrọ naa.