You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí rèé tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ fi lé Eleruwa, Ọba Adebayo Adegbola kúrò lórí ìtẹ́, kí Makinde tó yàn-án padà lẹ́yìn ọdún mẹ́fà
Yoruba ni ori ti yoo dade, ko ni se alai dade, ọrun ti yoo lo ilẹkẹ, ko ni se alai lo o, ibadi ti yoo si lo Mọ̀sàajì, asọ ọba to jina korokoro, ko kuku ni se alai lo.
Yoruba si ni ayanmọ ko gboogun, ori ni ẹlẹjọ nitori ori ti Tayelolu gbe wa sile aye, o yatọ patapata si ti Kehinde.
Bẹẹ ni ọrọ itan igbesi aye Eleruwa tilu Eruwa, Ọba Adebayo Adegbola ri.
Ọba Adegbola ni ori gbe de ipo ọba lọdun 2011, ti gbogbo ilu si fi tijo tilu ki kaabọ sori itẹ.
Amọ igbẹjọ dide lori iyansipo oriade naa, ti wọn si se ẹjọ naa fun ọdun pipẹ, ti Ọba Adegbola fi lo ọdun mọkanlelogun lori itẹ.
Igbẹjọ naa si lo kọkọ dide nile ẹjọ giga nipinlẹ Oyo, wọn tun gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ Kotẹmilọrun, ti Kabiyesi si n fidi rẹmi.
Ọdun 2019 si ni ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ Kotẹmilọrun ti Ọba Adegbola pe, to si ni ẹjọ rẹ ko lẹsẹ nilẹ.
Ile ẹjọ to ga julọ si le Ọba Adegbola kuro lori itẹ gẹgẹ bi Eleruwa tilu Eruwa.
Fun iyalẹnu ọpọ eeyan, titi di osu keji ọdun 2025 ti a wa yii, wọn ko fa ọmọ oye miran kalẹ lati jẹ Eleruwa, gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ Oyo se wi.
Amọ ni Ọjọru, ọjọ Karun osu kẹta ọdun 2025 yii, ni ijọba ipinlẹ Oyo kede Ọba Adebayo Adegbola pada gẹgẹ bii Eleruwa tuntun lẹyin ọdun mẹfa to ti kuro lori itẹ.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba tu itan wo yẹbẹyẹbẹ lati ran yin leti awọn koko ẹsun ti ile ẹjọ kotẹmilọrun we mọ Ọba Adegbola lọrun lọdun 2019, to fi ni ko yẹ lori itẹ Eleruwa.
Alaye lori idajọ ile ẹjọ to ga julọ to yọ Eleruwa Ọba Adebayo Adegbola loye
Ni ọdun 2019 ni ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ṣe agbekalẹ idajọ to rọ Eleruwa, Ọba Adebayo Adegbola, loye.
Igbimọ onidajọ ẹlẹni marun un ti adajọ Muhammad Dattijo dari wọn yi awijare Ọba Adegbola atawọn mẹfa mii danu.
Ṣaaju ni Eleruwa atawọn eeyan mẹfa mii ti pe ẹjọ kotẹmilọrun nile ẹjọ to ga julọ lẹyin ti ile ẹjọ giga to wa niluu Ibadan nipinlẹ Oyo ati ile ẹjọ kotẹmilọrun ti yọ oriade naa nipo.
Amọ, igbimọ onidajọ ẹlẹni marun un nile ẹjọ to ga julọ fontẹ lu idajọ ile ẹjọ giga ilu Ibadan ati ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ninu idajọ wọn.
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria sọ ninu idajọ rẹ pe ẹjọ kotẹmilọrun ti Eleruwa pe ko lẹsẹ nilẹ rara.
Adajọ Kudirat Kekere-Ekun to ka idajọ naa sọ pe olupẹjọ ko ni awijare kankan bi o ti wu ki o mọ.
Adajọ sọ pe ipo ọba Eleruwa ko tọ si Ọba Adegbola tori ki i ṣe ọmọ ile ọba Laribikusi to jẹ ọkan lara idile ọba meji to n jẹ Eleruwa niluu Eruwa
Lọdun 2011 ni Adajọ Muktar Abimbola ti ile ẹjọ giga ilu Ibadan paṣẹ iyọnipo Ọba Adegbola, lẹyin ti adajọ naa sọ pe Kabiyesi naa gori oye lọna aitọ.
Adajọ sọ pe ipo ọba Eleruwa ko tọ si Ọba Adegbola tori ki i ṣe ọmọ ile ọba Laribikusi to jẹ ọkan lara idile ọba meji to n jẹ Eleruwa niluu Eruwa.
Ile ẹjọ ni Ọba Adegbola ki i ṣe ọmọ oye lati idile ọba Laribikusi to kan lati jọba lẹyin ti Eleruwa tẹlẹ, Ọba Bolanle Olaniyan waja lọdun 1994.
Ti ẹ o ba gbagbe, lọdun 2013 ni ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Ibadan fontẹ lu idajọ ile ẹjọ giga to rọ Ọba Adegbola loye.
Awọn to pe Eleruwa lẹjọ ni Ọgbẹni James Olatunde Idowu lorukọ ara rẹ ati idile ọba Laribikusi, Alhaji Rasheed Oyedepo Ajao ati gomina ipinlẹ Oyo.
Awọn eeyan mẹfa to tako idajọ ile ẹjọ kotemilọrun naa, ti wọn si gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ to ga julọ ni Ọba Adebayo-Adegbola (Eleruwa).
Awọn yoku ni Oloye Samuel Salako Adewusi, Oloye Femi Atanda, Jagun of Eruwa, Oloye I.O. Olabode, Olukuton of Eruwa, Oloye Idowu Okeowo.
Bakan naa, Asipa ilu Eruwa, Oloye E. Ojebisi ati Ọgbẹni Kasali Sangotikun wa ;lara wọn.
Awọn to pe Eleruwa lẹjọ ni Ọgbẹni James Olatunde Idowu lorukọ ara rẹ ati idile ọba Laribikusi, Alhaji Rasheed Oyedepo Ajao ati gomina ipinlẹ Oyo.