You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tọkọtaya pa ọmọ wọn tó ń fẹ́wọ́ l'Ondo, sin òkú rẹ̀ sì abẹ́ igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ilé wọn
Ọkunrin kan, Monday Elala ti ṣekupa ọmọ rẹ ọkunrin, to si sin oku ọmọ naa si abẹ igi ọgẹdẹ kan ni ẹyin ile ti wọn n gbe nipinlẹ Ondo.
A gbọ pe ọmọ ọdun mẹrinla pere ni oloogbe ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Tope Elela, ki baba rẹ to ṣekupa a.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.
Bo tilẹ jẹ ọlọpaa kọ lati mẹnuba ẹkunrẹrẹ iṣẹlẹ naa o ni ilu Ajowa Akoko ni iṣẹlẹ ọhun ti waye l'Ondo.
Gẹgẹ bi ohun ti ọlọpaa sọ, afurasi naa ati iyawo rẹ lo pawọpọ lati gbẹmi ọmọ ọdun mẹrinla ọhun.
Ọlọpaa fi kun pe awọn tọkọtaya naa gbẹmi oloogbe naa latari pe o n jale eyii to fi n ba orukọ idile wọn jẹ.
Ọlọpaa pari atẹjade naa pe iyawo afurasi naa ti wọn pawọpọ gbẹmi ọmọ wọn ti na papa bora amọ iwadii ti n lọ lọwọ.
Emi kọ ni mo pa ọmọ mi - Afurasi
Nigba ti ọlọpaa n fi oju awọn afurasi lede ni olu ọọfisi rẹ to wa ni Igbatoro, niluu Akure, afurasi naa sọ fun awọn akọroyin pe ki ṣe oun lo pa ọmọ naa.
O ni lootọ ni pe oloogbe ọhun maa n jale, to si maa n dero atimọle ọlọpaa lọpọ igba, eyii to n doju ti orukọ oun ladugbọ.
Gẹgẹ bii alaye rẹ, ọmọ naa tun jale ninu oṣu Kejila ọdun 20204 eyii to mu ko dero agọ awọn Amotekun.
Afurai naa sọ suwaju si pe awọn oṣiṣẹ Amotekun ti kọkọ na oloogbe ọhun daadaa ki oun to lọ gba beeli wale.
Amọ nigba ti wọn dele, oun tun pada ba ọmọ naa wi ti gbogbo wọn si sun sile wọn.
Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ keji, oku rẹ ni wọn ba ninu yara ki oun ati iya rẹ to lọ sin oku naa si abẹ igi ẹgẹde to wa lẹyin ile wọn.