Adeleke kò yọ Adájọ́ àgbà, ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ló yí ọ̀rọ̀ po - Olórí ilé Aṣòfin

O ti to ọjọ mẹta kan ti awuyewuye ti n su yọ lori ọrọ adajọ agba nipinlẹ Osun, Adepele Ojo, ti awọn eeyan kan n pariwo pe wọn ni ko lọ rọọkun nile na.

Koda, ọrọ naa ti da isu ata yan-an yan-an silẹ laarin awọn osisẹ lẹka eto idajọ nipinlẹ naa ati adajọ agba funra rẹ.

Awọn osisẹ yii si ni wọn faake kọri pe lilọ ni adajọ agba naa yoo lọ nitori ọpọ ẹsun ti wọn fi kan-an.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan obinrin naa ni pe o gbẹsẹ le awọn ẹtọ to jẹ tawọn osisẹ, to si tun n fi ọwọ lile mu awọn lẹnu isẹ.

Se ni awn osisẹ yii si taku lọjọ ti Adajọ agba fẹ wa sibi isẹ pe ko ni wọle, ti awn ọlọpaa si fi afẹfẹ tajutaju le wọn lọ.

Lẹyin eyi ni awọn osisẹ lẹka eto idajọ naa kede pe awọn bẹrẹ iyansẹlodi tori Ojo se fẹ pada sẹnu isẹ.

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC, PDP kojú ara wọn lórí yíyọ adájọ́ àgbà

Lasigbo yii lo mu ki BBC Yoruba de ipinlẹ Osun lati tanna wadi awọn ohun to n fa awuyewuye nidi yiyọ adajọ naa.

Nigba to n salaye bi rogbodiyan yii se gbalẹ kan, agbẹnusọ fun olori ile asofin pinlẹ Osun, Olamide Tiamiyu mi irọ lasan ni ọrọ to n ja rain pe wọn ti yọ adajọ agba, Adepele Ojo.

Tiamiyu ni awọn araalu lo n kigbe tọ ile asofin wa pẹlu oniruuru awn ẹsun ti ko dara nipa obinrin naa.

O ni ẹgbẹ alatako lo n pin awọn iroyin ẹlẹjẹ naa kaakiri, gomina Ademola Adeleke ko si figba kankan kede pe oun ti yọ adajọ agba.

Amọ o wa fọwọ idaniloju sọya pe ile asofin ti se akojọpọ awn ẹsun ti awọn araalu n mu wa nipa adajọ agba naa, ti wọn si ti fi ransẹ si ajọ eleto idajọ lati se agbeyẹwo rẹ.

Amọ sa, ninu fidio yii, asoju ẹgbẹ oselu APC ati alaga ẹgẹ awọn osisẹ lẹka eto idajọ nipinlẹ Osun naa sọrọ nipa oju ti wọn fi wo laasigbo yii .

Kókó ẹ̀sùn àjẹbánu mẹ́fà rèé tí adájọ́ àgbà hù tó ṣe pọn dandan láti lé e lọ - Ilé aṣòfin Osun

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Asofin Adewale Egbedun ti fesi si ẹsun ti ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA ati agbẹjọro agba Femi Falana fi kan ile igbimọ aṣofin Osun lori ọrọ iwadi ẹsun ti wọn fi kan adajọ agba nipinlẹ Osun, Adepele Oyebola Ojo.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, Olamide Tiamiyu fi lede ni Ogunjọ oṣu kọkanla ọdun 2023, o jẹ ko dimọ pe ile igbimọ aṣofin ko ni erongba kankan lati dabaru eto ofin ilẹ Naijiria to ni ibasẹpọ pẹlu ẹgbẹ awọn agbẹjọro.

Ile igbimọ aṣofin ni nnkan ti awọn n ṣe lo ba ilana ti ofin fi la kalẹ mu, to si wa ninu iwe ofin ọdun 1999 pe awọn anfani lati ṣe iwadi iwa ọdaran.

“Ile igbimọ aṣofin ti gba ọpọlọpọ iwe ẹsun to n ka ẹsun iwa ibajẹ si Adajọ agba sọrun, yoo si lodi si isẹ ti ilu ran wa gẹgẹ bi aṣofin, ti a ba kọ lati ṣe iwadi.

Wo àwọn ẹ̀sùn tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Osun kà sí ẹsẹ̀ Adájọ́ àgbà Adepele Ojo

Ile igbimọ aṣofin ni ẹsun to wa niwaju Adajọ agba Adepele Ojo lo jẹ mẹfa, ti wọn fi sita fun gbogbo araalu lati ri.

  • Gbigbe owo to wa fun kikọ yara ikawe ẹka eto idajọ gba ibomiran lọ
  • Gbigbe owo ajẹmọnu to to miliọnu marun Naira, (N5,000,000) to wa fun asọ rira, (Robe Allowance) to jẹ ti adajọ kan nile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, gba ibomiran.
  • Pipasẹ pe ki awọn osisẹ ẹka eto idajọ kan lọ rọọkun nile na lai fi to ajọ to wa fun akoso awọn osisẹ lẹka eleto idajọ leti ati gbigbe owo oṣu wọn gba ibomiran lọ
  • Gbigbe owo to tọ si apo ijọba lati ara owo tawọn araalu n san nidi sise ibura nile ẹjọ (Affidavits) gba ibomiran lọ pẹlu bi adajọ agba naa se da yan agbasẹse lati maa gba owo naa wọle. Ẹgbẹrun kan naira ni agbasẹse naa n gba wọle lori eyi sugbọn to n san igba Naira ati aabọ (N250) pere fun ijọba.
  • Kikọ lati tẹle idajọ ileẹjọ to da osisẹ ẹka eto idajọ kan lare pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan pe o ko owo toto ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira jẹ.
  • Dibaru awọn owo ti wọn gba lọwọ awọn adigunjale ti wọn mu niluu Ikirun gba ibomiran lọ.

Ile igbimọ aṣofin ni awọn mọ pe ilana ti ofin ọdun 1999 gbe kalẹ fidi rẹ mulẹ pe Gomina tabi Ile igbimọ ko lẹtọ lati yọ Adajọ agba lai si ọwọ ẹgbẹ awọn agbẹjọro ninu.

Ile aṣofin Osun ko sinu awọn olujẹjọ ti Adajọ Adepele pe lẹjọ ni Ibadan.

Ile igbimọ aṣọfin Osun ni iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin to gba ilu pe ile igbimọ n gbero lati lati yọ adajọ agba tabi wọn ti yọ Adajọ Adepele Ojo lai kan si ẹka ileẹjọ lorilẹede Naijiria.

Wọn jẹ ko di mimọ pe Ile igbimọ aṣofin ko sinu awọn olujẹjọ ti Adajọ Adepele pe lẹjọ lọ siluu Ibadan.

Ile igbimọ aṣofin Osun wa jẹ ko di mimọ pe oun ko ni jawọ ninu titu asiri iwabajẹ sita ti awọn ba kẹfin rẹ nibikibi nipinlẹ naa.

Bakan naa ni wọn salaye pe awọn ko ni lodi si agbekalẹ ofin ti Naijiria ti gbe kalẹ lati ṣe ohun to lodi sofin.