'Tinubu yóò ṣẹ àwọn èèyàn kan tó bá fẹ́ ṣàṣeyọrí'

Ni bayii ti Aarẹ Bola Tinubu ti bẹrẹ si ni jawe lọ rọkun nile fun awọn oṣiṣẹ ijọba kan, awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan kan ti sọ pe Aarẹ ni lati ṣetan lati ṣẹ awọn eeyan to ba fẹ ṣaṣeyọri.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle Ledership sọrọ, akọwe ẹgbẹ Campaign for Democracy, CD, Olufemi Lawson, sọ pe awọn ohun ti Tinubu n ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii n fi han pe o ti ṣetan lati tun Naijiria ṣe.

O ni “lai wo ti oju ti awọn kan fi wo bi Aarẹ ṣe jawe lọ rọkun nile fun gomina CBN ati alaga EFCC, awọn igbesẹ naa jẹ eyi to maa ṣe awọn awọn araalu lanfani.”

“Lati akoko yii lọ, Aarẹ Bola Tinubu gbọdọ maa ṣe awọn nnkan ti yoo fi han pe o ti ṣetan lati doju ija kọ iwa ajẹbanu ni Naijiria."

Gẹgẹ bi ohun to sọ, ireti awọn ọmọ Naijiria pọ ninu ijọba tuntun yii, Aarẹ si ni lati tete bẹrẹ iṣẹ lori awọn ileri to ṣe lasiko ipolongo ibo.

O yẹ ki Buhari ti gba iṣẹ lọwọ Emefiele tipẹtipẹ

Ẹwẹ, agbẹnusọ ẹgbẹ Coalition of United Political Parties, CUPP, Mark Adebayo sọ pe ohun to dara ni Aarẹ Tinubu ṣe bo ṣe yọ gomina CBN, Godwin Emefiele bii jiga.

O ni “ko yẹ ki gomina CBN ana lo ọjọ keji ni ọọfisi rẹ ni kete to ti kede pe oun naa fẹ du ipo Aarẹ Naijiria lasiko to ṣi wa lori oye gẹgẹ bi gomina banki naa.”

“To ba jẹ pe Aarẹ ana, Buhari mọ ohun to n ṣe ni, o yẹ ko ti gba iṣẹ lọwọ Emfiele tipẹtipẹ.”

“Bẹẹ naa ni ọkunrin ọhun tun paarọ owo naira, eyi to ṣe lati gbogun ti akitiyan awọn oloṣelu kan to n du ipo Aarẹ.”

“Igbesẹ naa pa ọpọlọpọ okoowo run, bẹẹ lawọn araalu kan ṣo ẹmi wọn nu nitori rẹ latari inira ti wọn dojukọ; wọn lowo ni banki amọ wọn ko le gba owo naa.”

Wayi o, Aarẹ Tinubu ti sọ pe ijọba oun yoo tu awọn araalu lara lai ṣe awawi kankan.