You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ Nàìjíríà, ẹ padà sóko kí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ lè wálẹ̀ - Buhari
Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Muhammadu Buhari ti kepe ọmọ Naijiria lati pada soko latari ọwọngogo ounjẹ to gbode bayii.
Buhari sọ pe eleyii lo le mu ki ọwọngogo ounjẹ to gbode kan bayii walẹ ni Najiria.
Aarẹ ana sọrọ yii lẹyin to gbadura ni Yidi tan nibi ayẹyẹ ọdun Ileya niluu Daura, nipinlẹ Katsina.
Buhari ni ‘’mo lo asiko yii lati kepe awọn ọmọ Naijiria wi pe ki wọn gbiyanju lati da duro fun ra wọn.
Ẹ jẹ ka pada lọ si oko , ki a le ri ounjẹ jẹ.
Awọn apẹẹrẹ ati ami wa pe a lagbara lati pada si ibi iṣẹ agbẹ.
Kii ṣe asiko ti a gbọdọ kaarẹ niyii, pẹlu bi ounjẹ ṣe wọn gogo kaakiri Naijiria bayii.’’
Buhari tun rọ awọn ọmọ Naijiria wi pe ki wọn maa ra awọn nnkan ti wọn ṣe ni Naijiria.
Aarẹ ana orilẹede Najiria sọ pe ‘’ijọba ti ṣe agbekalẹ oniruuru eto fun idagbasoke orilẹede wa.
Mo wa fi asiko yii rọ awọn eeyan papaa julọ awọn ọdọ lati kopa pataki ninu idagbasoke ati itẹsiwaju Naijiria.’’
Buhari ko ṣai fi idunnu han si bawọn ọmọ Naijiria kan ti pada soko lati maa gbin ounjẹ tawọn eeyan yoo maa jẹ.
Aarẹ Naijiria tẹlẹ sọ pe awọn ijọba to ti ṣaaju ti fi ipilẹ to dara lelẹ fun ọjọ ọla to dara fawọn to n bọ lọjọ iwaju.
Buhari tun kọminu lori bi ọmọ Naijiria ṣe n pọ si lojoojumọ lai nọọni bi ilu ṣe ri.
Aarẹ ana ni eleyii le ṣakoba fawọn iran to n bọ lọjọ iwaju.
O ni ijọba ni lati nawo si eto ẹkọ ati ilera sii pẹlu bi awọn eeyan ṣe n pọ si lojoojumọ.