Ilé iṣé ọlọ́pàá Osun f'òfin de báńgà yínyìn àti 'carnival' lásìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti fi ofin de tita, rira ati yinyin banga lasiko pọpọsinsin ọdun yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Opalola Yemisi Olawoyin lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.

Ileeṣẹ ọlọpaa kilọ fawọn eeyan ipinlẹ Osun lati ma ta tabi ra ohunkohun bii banga tabi ohunkohun to le ṣe ipalara fawọn eeyan tabi ba dukia jẹ lasiko ọdun yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni eleyii le ṣakoba fun eto abo araalu paapaa julọ ladugboo, nile ijọsin, nibi igbafẹ ati ni ibudokọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun sọ fawọn eeyan ipinlẹ naa pe oun ti fofin de sise ajọdun "carnival" lasiko ọdun yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa kilọ fawọn ọdọ pe ẹnikẹni to ba korajọ pọ lati ṣe ohunkohun bii "carnival" tabi ohun to jọ ọ pe yoo foju wina ofin.

Ọlọpaa ipinlẹ Osun wa rọ awọn to ba fẹ ṣe "carnival" lati gba gbọngan tabi ile fun iru nkan bẹẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ikilọ yii ṣe pataki tori awọn ọdaran kan le fi iru apejọ bẹẹ boju lati ṣiṣẹ ibi wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn obi, alagbatọ, at'awọn olori ẹsin lati kìlọ fawọn ọmọ wọn pe ki wọn ma kọ eti ikun si ikilọ yii, bi bẹẹ kọọ, wọn o da ara wọn lẹbi.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ọsun, CP Isyaku Mohammed ti ki gbogbo eeyan ipinlẹ naa ku ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna.