You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mi ò kú o, mi ò sí rí ẹ̀wọ̀n he rárá – Gbajúmọ̀ òṣèrè, Dele Odule figbeta lórí àwọn tó ń gbé ìròyìn ikú rẹ̀ kiri
Agba oṣere tiata Yoruba, Dele Odule, ti ke gbajare sita pe oun ko tii ku o, ati pe aye loun wa.
Dele Odule lo sọrọ naa ninu fidio kan to di lede loju Instagram rẹ, nibi to ti bu ẹnu atẹ lu awọn kọlọrọsi to n gbe iroyin aburu kiri nipa oun.
Agba oṣere naa sọ siwaju si pe ayederu akọroyin mii tun gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa oun pe oun ti ri ẹwọn he.
O ni "Orukọ mi ni Dele Odule, mo kan fẹ sare tan imọle si ahesọ ọrọ kan to milẹ titi laarin ọjọ diẹ sẹyin ti ayederu akọroyin kan to pe ara rẹ ni Ope Ajiboye ṣe to wi pe ọta mi o ti ku.
"O gbe fọto si aarin ọrọ yanmayanma kan to sọ kalẹ to wa kọ RIP si. Ko si nnkankan to ṣe mi o, mo wa laaye, alaafia si ni mowa."
Gbajumọ Oṣere tiata naa ni oun ko le sọ idi pato ti ẹnikẹni yoo fi maa ro iku si oun.
Dele sọ pe iwa ti ẹni to gbe iroyin naa jade hu jẹ eyii to buru jai, ti ko si yẹ ọmọluabi.
O tun mẹnuba iroyin mii pe ẹnikan fi aworan oun lede pẹlu mamugaari ijọba lọwọ pe wọn ti ṣedajọ ẹwọn fun oun latari pe oun ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde.
Dele tẹsiwaju pe ẹni naa gbe fọto ẹni ti wọn n mu lọ sinu ọkọ Black Maria jade lori ayelujara, ti ẹni naa si gbe ori oun si ori ̣ọdaran naa pẹlu akọle pe "Dele ri ẹwọn he o!"
O ni "O ṣe yẹ ko ri bẹẹ, ṣe ẹyin kii n ri nnkan to dara ni? O ṣe jẹ iyẹn ni ẹ maa n ri nipa awọn oṣere na? Ṣe ẹ gbadun?"
Lẹyin naa lo kilọ fun gbogbo awọn to n gbe irufẹ iroyin bẹẹ kiri ki wọn lọ jawọ nitori ẹni to ba n kọju ija si oun n kọju ija si Ọlọrun, yoo si ṣoro lati fa oun walẹ lati oke tente ti Eledua ti fi oun si.
O tun fi akoko naa ki gbogbo awọn ololufẹ rẹ fun ifẹ ati atilẹyin wọn fun oun lati ọpọ ọdun sẹyin.