Mnangagwa borí ìbò ààrẹ Zimbababwe fún sáà kejì

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa ti borí ètò ìdìbò fún sáà kejì ní orílẹ̀ èdè náà.

Àjọ èlètò ìdìbò orílẹ̀ èdè Zimbabwe ní ààrẹ Emmerson Mnangagwa ní ìbò ìdá méjìléláàdọ́ta níbi àpapọ̀ ìbò tó wáyé níbẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ alátakò ní orílẹ̀ èdè náà ní màkàrúrù tó pọ̀ wáyé níbi ètò ìdìbò náà, tí àwọn olùwòye ètò ìdìbò láti ilẹ̀ òkèrè náà sì ní ètò ìdìbò ọ̀hún kò gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.

Mnangagwa ni ààrẹ kẹta ti yóò jẹ ní Zimbabwe. Lẹ́yìn tí ìdìtẹ̀ gbàjọba gbé Robert Mugabe kúrò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ni Mnangagwa di ààrẹ níbẹ̀.

Ọ̀wọ́n gógó gbogbo nǹkan, ìṣẹ́ àti òṣì tó fi mọ́ àyípadà ojú ọjọ́ ń bá àwọn ènìyàn Zimbabwe fínra.

Nígbà tí Mnangagwa kọ́kọ́ jẹ ààrẹ lọ́dún 2017, ọ̀ọ̀nì ni wọn máa ń pè é nítorí bí ó ṣe burú tó, tó sì ṣèlérí àyípadà ọ̀tun fún orílẹ̀ èdè náà.

Ṣùgbọ́n Zimbabwe wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ní àkọ́ọ́lẹ̀ ọ̀wọ́n gógó jùlọ ní àgbáyé, tí iye ọ̀wọ́n gógó sì jẹ́ ìdá 101% nínú oṣù Keje ọdún yìí.

Bákan náà ni àìníṣẹ́ àwọn ènìyàn ní orílẹ̀ èdè náà sì tún lágbára si tó sì jẹ́ pé ìdá márùndínlọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà ló ní iṣẹ́ lọ́wọ́.

Ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó ní òun yóò ṣe àmójútó náà kò ní ìyàtọ̀ bí ó ṣe jẹ́ wí pé kò fẹ́ẹ̀ sí àyípadà kankan láti ìgbà tí Mugabe ti kúrò nípò.

Àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀ èdè Zimbabwe (ZEC) ní olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Citizen’s Coalition for Change (CCC), Nelson Chamisa rí ìbò ìdá mẹ́rìnlélógójì n’bi àpapọ̀ ìbò náà.

ZEC ní ìbò 2.3m ni Mnangagwa ní nígbà tí Chamisa sì ní ìbò 1.9m.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní èrú wà nínú ìbò náà, ilé ẹjọ́ ti jan èsì ìbò ọ̀hún ní òǹtẹ̀.

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú CCC, Promise Mkwananzi gbe sórí ẹ̀rọ ayélujára X rẹ̀ pé ẹgbẹ́ àwọn kò gba èsì ìbò tí wọ́n kójọ láì ṣe àyẹ̀wò tó tọ́ le lórí wọlé.

Mkwananzi sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn AFP pé ẹgbẹ́ àwọn kò buwọ́lu èsì irọ́ tí wọ́n gbé jáde àti pé àwọn k]o gbà á wọlé rárá.

Ó ní ẹgbẹ́ àwọn máa fi ìgbésẹ̀ tí àwọn yóò síta láìpẹ́.

Àwọn olùwòye ètò ìdìbò láti EU, Commonwealtj àti àwọn orílẹ̀ èdè Mẹ́rìndínlógún Southern African Development Community (SADC) ní àwọn ní ìwòye tó pọ̀ lórí ètò ìdìbò náà.

Lára àwọn nǹkan tí wọ́n tọ́ka sí bíi àìṣedédé níbi ètò ìdìbò náà ni títọwọ́ bọ ìwé àkọ́ọ́lẹ̀ ètò ìdìbò, ìdúnkokò mọ́ àwọn olùdìbò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà ṣáájú ètò ìdìbò náà àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú CCC fẹ̀sùn kàn pé ọ̀pọ̀ ìpàdé àwọn tó yẹ kó wáyé ni àwọn ọlọ́pàá fi òfin dè láti oṣù kìíní ọdún tí wọ́n ti dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ CCC ogójì ni àwọn ọlọ́pàá gbé lásìkò tí ẹgbẹ́ náà ń ṣe ìpolongo ìbò lọ́wọ́ ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Harare.

Ọjọ́rú ni ètò ìdìbò náà bẹ̀rẹ̀ àmọ́ ìbò dídì wọ ọjọ́bọ̀ nítorí tí àwọn ohun èlò ìdìbò kò tètè dé àwọn ibìkan tí ètò ìdìbò máa ti wáyé.

Pẹ̀lú bí Mnangagwa ṣe borí ìbò yìí, ó túmọ̀ sí pé ẹgbẹ́ òṣèlú Zanu- PF ti ṣe ìjọba fún ọdún mẹ́tàlélógójì lẹ́yìn ìgbà tí orílẹ̀ èdè Zimbabwe gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì lọ́dún 1980.

Bákan náà ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Zanu-PF tún rí àga 136 nínú 210 tó wà ní ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè náà nígbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú CCC sì ní ọmọ ilé 73.