You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn mẹ́rin farapa yánayàna níbi òde orin Asake nílùú London.
Awọn ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ti ni eniyan mẹjọ ti farapa ti awọn mẹrin mii si wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.
Bi aago mẹsan abọ asalẹ ni wọn pe awọn ọlọpaa wa si gbọngan Brixton 02 nibi ti ode orin naa ti waye.
Ọpọlọpọ awọn ẹniyan ni wọn farapa.
Ode orin ni ko le tẹsiwaju ti o si jẹ ọkan ninu ode orin mẹta ti olorin takasufe Asake yoo ṣe ni gbọngan 02 Academy.
Awọn fọnran la'tori ẹrọ ayelujara fihan pe ọpọlọpọ eniyan ni wọn wa si gbọngan 02 lori ẹrọ ayelujara Twitter ti ẹnikan sì sọ wi pe o le ni ẹgbẹrun eniyan ti ko ra tikẹti lati woran ti wọn si n gbiyanju lati wọle sinu gbọngan naa.
Ṣaaju ki ode orin to bẹre Aṣakẹ ti kede lori ìkànnì ayelujara Twitter rẹ pe ki awọn ololufẹ rẹ ti wọn ko ba ni tiketi ma ṣe wa woran orin oun.
Jason Okundaye ẹniti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni awọn oṣisẹ gbọngan 02 Academy ko ni ẹkọ ibara ẹni sọrọ. Eyi lo jẹ ki oun pada si ile oun nitori aisi abo to peye. Ọga ọlọpaa, Ade Adelekan sọ wi pe ileeṣẹ ọlọpa yoo ṣe iwadii tonitoni lati mọ okunfa iṣẹlẹ ti o mu ki eniyan mẹrin farapa yanayana. Aṣakẹ olorin takasufe ti orukọ rẹ gangan n jẹ Ahmed Ololade ni wọn bi si ilu Eko, ti apeja rẹkọdu orin rẹ to sọ ọ di olokiki jẹ "MR Money".