Ṣé lóòótọ́ ni Naijiria nílò àtúnṣe ọrọ̀ ajé tí Tinubu ń ṣe?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alekun ti ba owo gbogbo nnkan lorilẹde Naijiria, eyi to mu ki araalu maa kerora pe ijọba Tinubu n ni awọn lara.

Ṣugbọn iṣakoso yii ko yee sọ pe atunṣe ọrọ aje loun gunle, ati pe ki nnkan le baa daa fun Naijiria lọjọ iwaju ni o ṣe le koko lasiko yii.

Wọn ni ki araalu maa rọju.

Lori ariwo inira ọhun ni awọn ọmọ Naijiria wa, ti Banki Agbaye tun fi kilọ lọsẹ to kọja, pe ijọba Tinubu ko gbọdọ dawọ atunṣe naa duro.

Wọn ni bijọba ba fi dawọ atunṣe yii duro, nnkan yoo buru ju bo ṣe wa yii lọ.

Banki agbaye sọ pe o yẹ ki Naijiria tẹsiwaju ninu atunṣe yii fun ọdun mẹwaa si mẹẹẹdogun ni, ki ọrọ aje to dẹnukọlẹ le dide pada.

Ikilọ ileefowopamọ agbaye naa lo si mu ki awọn amoye nipa ọrọ aje bẹrẹ si i ṣe ariyanjiyan, nitori ero wọn ko dọgba lori ọrọ ọhun.

‘Ìgbésẹ̀ tí kò bójúmu lèyí fún Naijiria’

Onimọ nipa ọrọ aje ni Ọjọgbọn Maryam Abdu, lati Yunifasiti ipinlẹ Kaduna.

Obinrin naa bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Banki Agbaye sọ nipa ọrọ aje Naijiria, ati atunṣe to n lọ lọwọ.

" Ni ti ododo,emi ko ri idi kan ti wọn yoo fi sọ pe igbesẹ to daa leyi, lẹyin inira to n koju awọn eeyan.

’’Bawo niyẹn ṣe le jẹ bẹẹ? Inira to n koju awọn eeyan ti pọju.

" Ti ẹ ba lọ si England tabi America, nnkan ko ri bayii."

Ọjọgbọn Maryam Abdu lo sọ bẹẹ.

O ni bi owo epo ba tẹsiwaju lati maa wọn si i, bẹẹ naa ni ele ori rẹ yoo maa pọ si i, ko si si bi ọrọ aje yoo ṣe dagba, yoo tubọ maa buru si i ni gẹgẹ bo ṣe sọ.

‘Onísùúrù yóò padà jèrè, ìfaradà tó lérè lèyí’

Fun Ọmọwe Bashir Muhammad Acida, ti Yunifasiti Usman Danfodiyo, ipinlẹ Sokoto, o ni igbesẹ to ni ere lọjọ iwaju ni iṣakoso yii gunle.

Ọmọwe Bashir to n ṣiṣẹ lẹka imọ nipa ọrọ aje ni unifasiti naa,sọ pe oun faramọ aba ti Banki Agbaye da naa.

O ni awọn araalu lo ku si lọwọ, lati mọ ọna ti wọn yoo fi kapa inira to rọ mọ atunṣe ọrọ aje naa.

" O da bii ki eeyan bimọ ni, wa a ran an lọ sileewe, to ba kawe tan yoo maa ṣiṣẹ, yoo wa lominira ara rẹ, obi rẹ yoo si nisinmi, yoo si tun maa jere ọmọ naa’’

Bẹẹ ni Ọmọwe Bashir Muhammad Acida wi.

Ṣe ṣaaju ni ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti ni oun yoo maa tẹsiwaju ninu atunṣe ọrọ aje ti araalu n pariwo si naa.

Ṣugbọn boya yoo waa pẹ to ọdun mẹwaa si mẹẹẹdogun ti banki agbaye n sọ ni ẹnikan o le sọ.

Awọn atunṣe ti Banki agbaye tori rẹ gboriyin fun Tinubu ni:

*Owo iranwọ ori epo to yọ kuro: Eyi to ti mu owo epo wọn kọja iriri awọn ọmọ Naijiria.

*Igbiyanjuy lati jẹ ki owo Naira le duro, ko si niyi laaarin awọn owo lagbaaye.

* Ati igbiyanju lati maa ta ohun ti Naijiria n ṣe si oke okun.