Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nìpa Abdulrahman Lekki, ammúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sanwo-Olu tó jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Akọwe agba fun ẹka ijọba to n pese ẹkọ ọfẹ nipinlẹ Eko, Abdulrahman Lekki ti jad laye.

Kọmisana fun ayika ati omi nipinlẹ Eko, Tokunbo Wahab lo kede ipapoda naa loju opo X lọjọru, Ọgbọnjọ Oṣu kẹwaa.

O ni “Ọdọ rẹ lati wa, ọdọ rẹ ni a o pada si. Pẹlu ọkan ti tobi ti a fi kede iku ọrẹ wa, Abdulrahman Lekki, ẹni to jẹ akọwe agba fun ileeṣẹ ijọba to n risi ẹkọ ọfẹ nipinlẹ Eko.

“O kopa nla lati ri pe awọn ọdọ ni anfani si eto ẹkọ, ti a o si ṣafẹri eeyan wa to lọ.

“AbdulRahman ki i se akẹgbẹ mi nikan, oluranlọwọ lo jẹ fun mi, ọrẹ to n duro ti ni pupọ, to si gbogbo awọn ni ayika si mọ riri rẹ.

“Ohun to fi silẹ ko ni di ohun igbagbe, ti yoo si wa ni ọkan wa gbogbo wa ti ayeraye.”

Bakan na ni ẹka to n risi oṣiṣẹ nipinlẹ Eko fi atẹjade sita lori iku Lekki, ti wọn si ni o jade laye lẹyin aisan ranpẹ.

“Owurọ Ọgbọnjọ oṣu kẹwaa ni AbdulRahman Lekki jade laye. Ki Ọlọrun ba wa forijin.”