Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun ni awọn agbebọn to gbẹmi eeyan to le lọgọrun ni Benue kọkọ kọju ija si ki wọn to kọlu araalu
Gomina ipinlẹ ọhun, Hyacinth Alia lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun ati ọlọpaa ti ṣeleri lati ṣewadii awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa lọna ati goju wọn wina ofin
____________________________
Ileeṣẹ Meta to ni WhatsApp, Facebook ati Instagram ti kede wi pe oun yoo bẹrẹ ipolowo ọja lori WhatsApp.
Meta ni igbesẹ yii wa lati jẹ ki awọn to n ṣe fidio ta lori ayelujara, awọn olokowo atawọn ileeṣẹ lanfaani lati maa jere lori WhatsApp.
Ileeṣẹ Meta kede ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje pe isọri mẹta gboogi lawọn eeyan ti le maa ri owo lori itakun WhatsApp bayii
_________________
Awa oṣere to le lọgọrun ni a polongo ibo fun Tinubu fun odidi oṣu meji gbako, amọ ko fun wa ni nnkankan
Agba oṣere tiata Yoruba, Ganiu Nafiu ti ọpọ mọ si Alapini Oosa lo sọ bẹẹ, koda o ni oun kabamọ pe oun ṣatilẹyin Tinubu
Fun ẹkunrẹrẹ iroyin yii