Owó tíjọba àpapọ̀ jẹ́ Osun tó N6bn, gómìnà, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti Davido ni wọn ń pawọ́pọ̀ sanwó òṣìsẹ́ - Bode George

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni nnkan bii oṣu kan sẹyin ni ẹnu bẹrẹ si i kun Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, pe o fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP to gbe e wọle.

Awuyewuye naa gbilẹ nigba naa, ọpọ eeyan si n sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ni gomina Osun naa n ba sọrọ lati di ara wọn.

Gomina Adeleke pada sọ pe irọ ni eyi, ati pe PDP loun tọkan-tọkan lọjọ kọjọ.

Ariwo ọrọ naa si ṣe bẹẹ lọ silẹ wẹlo lai mọ otitọ ọrọ to wa nidi isẹlẹ naa.

Ṣugbọn Oloye Bode George, eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati ọkan lara ọmọ igbimọ majẹobajẹ ẹgbẹ oselu naa, ti ṣalaye pe Adeleke fẹẹ fi PDP silẹ nigba naa loootọ.

O ni ọrọ ti oun ba a sọ ni ko jẹ ko lọ mọ.

Kí ni Bode George sọ fún Gómìnà Ademola Adeleke?

Nigba to n ṣalaye ọrọ yii lori eto ori redio kan, nipa bi Adeleke se fẹ kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP, Alagba Bode George sọ pe:

'' Nigba to pe mi lorii foonu, o sọ fun mi pe oun fẹ fi ẹgbẹ PDP silẹ. Eyi jọ mi loju pupọ, o si ya mi lẹnu.

'' Mo waa sọ fun un pe Ọlọla julọ, ro o daadaa o. Ṣe o mọ pe o ko gbọdọ ṣe aṣiṣe kankan bayii.

'' Ṣe o ranti bi ẹgbọn rẹ, Serubawọn, ṣe lọ. Bi iwọ naa ba ṣe nnkan kan ti ẹgbẹ fi dibo abẹle, ti wọn fa ẹlomi-in kalẹ, o lọ niyẹn o.''

Alagba Bode Geoge tẹsiwaju, pe oun mọ pe Adeleke n gbiyanju fun ipinlẹ Osun, o si ni ifẹ awọn eeyan rẹ lọkan.

O ni ijọba apapọ ko sanwo to yẹ ko san fun awọn ijọba ibilẹ l'Osun lati bii oṣu marun-un si mẹfa bayii.

Gomina Ademola Adeleke pẹlu ẹgbọn rẹ ati Davido lo ni wọn n sowọ pọ ti wọn si n sanwo awọn oṣiṣẹ naa lapo ara wọn.

Owo to to biliọnu marun-un si mẹfa lo ni ijọba apapọ n jẹ ijọba Osun, ti kootu si ti paṣẹ pe ki wọn san an, ṣugbọn ti wọn ko mu aṣẹ naa ṣẹ.

''Lẹyin ọrọ ti mo ba a sọ ni mo ri Demola ni ipade ẹgbẹ wa, o si wa di mọ mi, o dupẹ lọwọ mi, o ni oun ko fi ẹgbẹ silẹ mọ.

'' O n ṣe ẹtọ rẹ bii ọmọ ẹgbẹ, o si n wa si ipade bayii.''

Bẹẹ ni Oloye Bode George sọ.

''PDP kì í ṣe 'Èmi ló kàn', ẹni tó bá fẹ́ẹ́ díje gbọ́dọ̀ ṣetán láti figagbága''

Nigba to n dahun ibeere lori awọn eeyan ti yoo dupo aarẹ ninu ẹgbẹ PDP ni 2027, Alagba Bode George sọ pe aaye wa fun ifigagbaga.

O ni bi Goodluck Jonathan, Peter Obi tabi ẹnikẹni ba ṣetan lati dije dupo, ki ẹni naa tete mọ pe PDP ko da bii APC rara.

Alagba Bode George ṣalaye, pe ninu APC, a ti mọ ẹni to mu kọkọrọ aṣeyọri dani, ti yoo sọ ẹni ti yoo bọ sori aleefa.

O fi kun un pe APC ni wọn ti n ṣe Emi lo kan, o ni aaye iru rẹ ko yọ ni PDP rara, nitori dandan ni ki ẹni ti yoo ba ẹnikeji dupo wa.

Baba sọ pe bi Jonathan ba fẹẹ waa dupo aarẹ, aaye wa fun un, nigba to jẹ ọmọ ẹgbẹ ni, ko si figba kan kuro ninu PDP ri.

O ni ọrọ rẹ tilẹ le da bii ti Donald Trump l'America, to jẹ aarẹ ri to tun pada waa jẹ ẹ lẹyin ti Joe Biden ti jẹ to si ti lọ.

Ṣugbọn yoo kọkọ ba ẹnikan dupo ọhun naa bi Geoge ṣe wi.

Alagba George sọ pe PDP ki i deede ti ẹnikan lẹyin, afi to ba jẹ ẹni ọhun ni aarẹ to wa lori aleefa lọwọ lo ku.

Fun awọn to si n ṣe oju meji ninu PDP, ti wọn fi apa kan sin APC, ati awọn to n sa kiri ninu ẹgbẹ oṣelu lai si iwoye tuntun, Alagba George sọ pe eeyan ko le sin Ọlọrun ati Esu pọ.

O lo yẹ ki ẹgbẹ gbe igbesẹ lorii ṣeku-ṣẹyẹ ti wọn n ṣe.