Gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Dare Melody pàdánù ìyàwó rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Akọrin ẹmi, Damilare Odunuga, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Dare Melody ti padanu iyawo rẹ, Adedoyin.

Adedoyin jade laye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024.

Dare Melody lo gbe iroyin naa si oju opo ayelujara rẹ, to si ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ.

O ṣapejuwe iyawo rẹ gẹgẹ bii Iyawo, iya, aburo ati ọrẹ rẹ.

“Ọjọ dudu ni ileeṣẹ DM MULTIMEDIA, a n se idaro iku iyawo alaga ileeṣe wa, Dare Melody.

“Pẹlu ibanujẹ ọkan ni a fi n sọ fun yii nipa iku iya wa, iyawo ati ọrẹ, Adedoyin Odunuga, ẹni to jade laye ni owurọ ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2024. Ti ti aye ni o wa lọkan wa”

Ninu oṣu keji ọdun 2023 ni Dare Melody ra ọkọ bọgini fun iyawo rẹ lori ayelujara.

Ta ni Dare Melody?

Akọrin ẹmi ni Damilare Odunuga, ẹni ti ọpọ mọ si Dare Melody, wọn bi ni Ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwaa ni ọdun 1977 ninu Ijebu Ode.

Ọdun 1998 ni o bẹrẹ orin kikọ, to si ti se ọpọ aṣeyọri ninu orin kikọ.

O ti ṣe igbeyawo, to si ti bimọ mẹta.