Kìnìún wọ ilé onílé, ó pa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá

    • Author, Joseph Winter
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ kìnìún ní ìlú Nairobi, orílẹ̀èdè Kenya.

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ẹranko aginjù ní Kenya, Kenya Wildlife Service, KWS sọ pé ní ilé tí àwọn ọmọ náà n gbé, tí kò jìnà síbi igbó ọba tí kìnìún ọ̀hún wà, ló ti ṣe ìkọlù sí i.

Wọ́n ní ọmọdé mìíràn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ló pe àkíyèsí wọn, tí KWS sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣàwárí ọmọ náà tí wọ́n sì rí òkú rẹ̀ ní ẹ̀bá odò Mbagathi.

KWS ní àwọn ṣì ń wá kìnìún tó ṣekúpa ọmọ ọ̀hún, táwọn sì ti gbé ikọ̀ olùwádìí dìde láti ṣàwárí ẹranko náà.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé àwọn ti gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ kó wáyé mọ́.

Ọgbà àwọn ẹranko aginjù ni kò jìnà ju ìwọ̀n máìlì mẹ́fà sí inú ìlú, tó sì ní àwọn ẹranko bíi kìnìún, àgùnfọn, àmọ̀tẹ́kùn, ẹkùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nínú rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ odi yí ọgbà nàá kàá lọ́nà mẹ́ta láti dènà káwọn ẹranko má ba à lè máa ya wọ ìlú, wọn kò mọ odi sí apá gúúsù láti le fún àwọn ẹranko náà ní àǹfàání láti máa jáde lọ bọ̀.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí táwọn kìnìún yóò ṣe ìkọlù sáwọn èèyàn ní Kenya pàápàá lórí oúnjẹ àmọ́ kìí sábà la ẹ̀mí èèyàn lọ.

Ní ọdún tó kọjá, fọ́nrán CCTV kan ṣàfihàn bí kìnìún ṣe pa ajá òyìnbó ńlá kan ní ilé ìgbé tó wà lẹ́bàá ọgbà ẹranko náà.

Àjọ KWS tún sọ pé ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ erin.

Ní agbègbè Nyeri tó wà ní ọgọ́rin máìlì sí apá àríwá Nairobi ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Wọ́n ní erin náà ń jẹ nínú igbó Mere kó tó di pé ó ṣèkọlù sí ọkúnrin náà, tí ọkùnrin náà sì farapa ní igbáàyà.

Ní ilé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú ló pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Àfikún ìròyìn látọwọ́ Ruth Nesoba àti Gladys Kigo ní Nairobi