Wo ewu tó wà nínú kí èèyàn máa wẹ̀ nínú òjò

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ojo ṣe pataki ninu igbesi aye ọmọ ẹda, a maa n mu omi ojo, a si tun maa n fi wẹ, bakan naa ni a maa n lo omi ojo fun awọn nnkan mii.

Iṣẹ iwadii fi han pe nnkan bi biliọnu ọdun mẹrin sẹyin ni ojo kọkọ rọ lori ilẹ aye.

Awọn ọmọde to fi mọ awọn agba mii gan an maa n wẹ ninu ojo.

O le wu iwọ naa lati bẹ sinu ojo ti ojo ba bẹre sii rọ, ṣugbọn ikilọ ti jade wi pe ewu wa ninu ki eeyan maa wẹ ninu ojo.

Dokita onimọ nipa awọ ara, Umar Abdullahi, ni ile ẹkọ giga fasiti ABU ni Zaria ti fidi rẹ mulẹ pe ''loootọ lọpọ eeyan maa n ro pe omi to mọ gaara ni omi ojo, ṣugbọn iṣẹ iwadii ti fi han pe eleyii ko ri bẹẹ tori omi ojo lewu gan an lọna meji.

Ọna akọkọ ti omi ojo gba lewu ni pe awọn kokoro aifojuri le wa ninu rẹ lẹyin to ba rọ le paanu tabi orule tan.

Bakan naa ni o tun le fa otutu fun eeyan to ba n wẹ ninu rẹ, ati pe omi ojo tun maa n ni ipa ti ko dara lori awọ ara eeyan tori ko mọ gaara.''

''Acid'' pọ ninu omi ojo

Ewu mii to wa ninu omi ojo ni pe asiidi pọ ninu rẹ gan an debi wi pe o le ṣakoba fun agọ ara eeyan.

Apọju asiidi ninu omi ojo gẹgẹ bi awọn dokita ṣe sọ le jẹ ki awọ ara eeyan maa gbẹ, o si tun le fa awọn arun mii lori awọ ara.

Gbogbo nnkan yii n ṣẹlẹ tori oriṣiiriṣii nnkan to maa ti n dapọ mọ omi ojo ki o to de ori ilẹ.

Omi ojo maa n fa ''bacteria''

Ti eeyan ba n wẹ ninu ojo, omi to n da lati ori orule ni wọn maa n saba tẹri si.

Eyi to tumọ si pe oriṣiiriṣii kokoro aifojuri to fi mọ ''bacteria'' ni yoo ti dapọ mọ omi naa lori orule ki o to da silẹ.

Oriṣiiriṣii idọti to wa lori orule to fi mọ igbẹ ẹyẹ ni yoo ti dapọ mọ omi ojo to n da silẹ lati ori orule.

O ṣee ṣe ki eeyan gbe omi ojo mi lasiko ti eeyan ba n wẹ ninu ojo, eyi si le mu ki eeyan ṣe aisan latari awọn kokoro aifojuri to wa ninu omi ojo.

Otutu

Kii ṣe omi ojo gan an lo maa n fa otutu bi ko ṣe awọn kokoro to wa ninu omi naa.

Ohun to tun da bii rẹ ni pe otutu to maa n mu eeyan lasiko ti eeyan ba n wẹ ninu ojo ko ni jẹ ki ara gbona, eyi si le jẹ ki eeyan ko arun kan tabi omiran.

Kẹmika PFAS pọ ninu omi ojo

Iwadii tun ti fi han pe kẹmika kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni PFAS pọ ninu omi ojo.

Kẹmika yii ni iwadii fi han pe o le ṣakoba fun ago ara eeyan.

Kẹmika PFAS yii lawọn panapana maa n lo lati fi pa ina nibi ti ijamba ina ba ti ṣẹlẹ.

Iwadii fi han wi pe kẹmika yii le debi wi pe o le fa arun itọ ṣuga tabi jẹjẹrẹ sinu ara eeyan.

Ọjọgbọn Crispin Halsall to jẹ onimọ sayẹnsi ni fasiti Lancaster ni UK sọ pe lọjọ iwaju ni ọpọ maa to ri ipa buruku ti wiwẹ ninu ojo ni lori agọ ara wọn.

Imọran lori lilo omi ojo

Ọpọ eeyan lo maa n lo omi ojo yala fun mimu tabi fun wiwẹ.

Dokita Abdullahi ṣalaye pe ''ọpọ eeyan lo gbagbọ wi pe oogun ni omi ojo.

Amọ ti eeyan ba fẹ mu omi ojo, o ni lati gba a sinu ike to mọ ki o si se e lori ina ki o to o mu un.''

Dokita Abdullahi tun kilọ fawọn eeyan lati yago fun ojo akọkọ titi de ori ikẹta lasiko ti ojo ba ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Dokita tun gbawọn eeyan ni imọran lati wẹ pẹlu omi ẹrọ tabi omi to mọ nigba kugba ti wọn ba fi omi ojo wẹ ki awọ ara wọn maa ba gbẹ furu furu.

Bakan naa ni dokita tun gba awọn eeyan ni imọran lati lo ipara si gbogbo ara wọn lẹyin ti wọn ba wẹ ninu ojo tan ki ara wọn le jọlọ pada.