You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébọn pa èèyàn mẹ́sàn án, jí 117 míì gbé nílùú kan ṣoṣo
Agbebọn ti ṣekupa eeyan mẹsan an o kere tan, ti wọn si tun ji awọn 117 mii lọ niluu Danmuntari to wa ni Danko-Wasagu, nipinlẹ Kebbi.
Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa sọ fun BBC pe irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu ti a wa yi ni ikọlu ọhun waye.
Lara awọn ti awọn agbebọn naa ṣekupa ni obinrin alaboyun kan ati ọmọ kekere jojolo ọwọ rẹ, gẹgẹ bii ohun ti awọn ti ọrọ naa ṣoju sọ fun BBC.
Wọn sọ fun BBC pe "Lọsan gangan ni wọn yi wa ka ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn lakọlakọ pẹlu ariwo, asiko ti awọn eeyan ilu bẹrẹ si n sa kijokijo ni ibọn ba eeyan mẹsan an ti wọn si ku.
"O ṣeni laanu pe ibọn ba obinrin kan ati ọmọ rẹ ti ko tii ju ọmọ ọsẹ meji pere lọ."
Ọkan lara awọn eeyan ilu ọhun to ti salọ si agbegbe Baina bayii tun fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC.
O ni ṣe lawọn n mura lati lọ si oko ti awọn si n ṣe awọn iṣẹ pẹpẹpẹ kan ki wọn to ri awọn agbebọn naa ti wọn wọle lori alupupu.
Ọkunrin naa ṣalaye pe "Gbogbo ibi ni wọn n gba wọle, bi awọn kan ṣe gba iha ariwa, awọn kan gba ila oorun, awọn mii n gba guusu ati iwọ oorun ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn ki wọn to pa ọpọ eeyan.
"Ibọn ba obinrin kan to loyun toun ọmọ kekere to wa lọwọ rẹ, pẹlu awọn mẹsan an miran."
Oṣojumikoro naa fi kun pe "A ko gbọ nnkankan lati ọdọ ijọba, a tilẹ ti n wo o boya wọn ko ka wa mọ ara eeyan ipinlẹ Kebbi mọ nitori o yẹ ki a ti gbọ lati ọdọ wọn.
"Ijọba ko ṣe nnkankan, a ko tii ri ẹṣọ alaabo kankan lati daabo bo wa, wọn ko tii mu ẹnikẹni ninu wọn bẹẹ ni a ko gbọ nnkankan lati ọdọ wọn."
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ilu naa ti dahoro lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Awọn olugbe ilu ọhun sọ pe igba kẹta ree ti awọn agbebọn yoo ya bo ilu wọn lati ji awọn eeyan eeyan gbe ti wọn yoo si ṣeku pa ọpọ nibẹ.
Gbogbo akitiyan BBC lati kan si ijọba ipinlẹ Kebbi lasiko ti a n ko iroyin yii jọ lo ja si pabo.
Wayi o, bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ni oun n gbiyanju, ti oun si n ṣe aṣeyọri lori eto abo, bakan naa ṣi ni ọmọ ṣe ori lori eto abo iha ariwa Naijiria.