Ìdí rèé tí Bàálù Herbert Wigwe fi já ní Amẹ́ríkà èyí tó rán òun, aya àti ọmọ rẹ̀ sọ́run lójijì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹka ijọba Amẹrika to n risi irinna nilẹ Amẹrika, NTSB, ti kede ohun to se okunfa iṣẹlẹ ijamba ọkọ baalu to ṣekupa ọga ile ifowopamọ Access lorilẹede Naijiria, Herbert Wigwe pẹlu mọlẹbi rẹ.

Ileesẹ naa ni aini amojuto ati asise lati ọwọ awakọ baalu naa lo mu ki baalu ọhun ja.

NTSB tun fẹsun kan ileeṣẹ to n ṣe akoṣo ọkọ ofurufu naa pe wọn kọ lati ṣe ohun to yẹ lara baalu naa.

Bakan naa, o ni wọn tun gbe oju kuro ninu nnkan to jẹ ki wọn mojuto fun aabo awọn eeyan to n lo ọkọ ofurufu naa.

Awọn alaye yii lo wa ninu atẹjade esi iwadii wọn lori iṣẹlẹ ijamba to naa to sẹlẹ ni oṣu keji ọdun 2024.

Iwadii ọhun ṣalaye pe ọkọ baalu naa pẹlu nọmba idanimọ N130CZ ja lulẹ lasiko to n fo lọwọ pẹlu ọpọ aleebu lara.

Gẹgẹ bii iwadii ṣe ṣafihan rẹ, awọn oniwadii naa sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba naa pe awakọ baalu naa tun tẹsiwaju pẹlu irinajo lẹyin to ri pe aleebu wa lara ọkọ naa, ti agbara rẹ ko si lee ka mọ.

Ijamba ọhun waye ni California-Nevada lọjọ Kẹsan an ọdun 2024, ti eeyan mẹfa si padanu ẹmi wọn, to fi mọ Wigwe, iyawo rẹ, Doreen ati ọmọ rẹ ,Chizi ati Abimbola Ogunbanjo.

Oniwadii tun ṣafihan pe ileeṣẹ ọkọ baalu naa kuna lati jẹ ki awakọ baalu ṣe ayẹwo irinajo ṣaaju ki wọn to gbera, to si jẹ pe ohun gan lo ṣokunfa iku awọn olooogbe naa.

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Herbert Wigwe

Alẹ ọjọ kẹsan an oṣu keji ọdun 2024, ni orukọ ọga agba Access Bank, Herbert Wigwe, ti n tan kalẹ, paapaa lori ayelujara

Amọ pupọ ni ko mọ ohunkohun nipa ọkunrin naa, ju pe o jẹ ọga agba ọkan lara awọn banki to tobi julọ ni Naijriia.

Wigwe to ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga agba banki naa, pada di ọga lọdun 2014 lẹyin ti oludokowo pọ rẹ, Aigboje Aig-Imoukhuede fi ipo naa silẹ lọdun 2014.

Ọdun 1966 ni wọn bi Herbert Onyewumbu Wigwe, niluu Port Harcourt, nipinlẹ rivers.

O gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu iṣiro owo lati University of Naijiria, to w ani Nsukka nipinlẹ Enugu lọdun 1987.

O gba iwe ẹri keji ninu imọ nipa eto ile ifowopamọ ati iṣuna lọdun 1991, ni University College of North Wales, nipasẹ ẹkọ ọfẹ ti ijọba ilẹ Britain.

Lẹyin naa lo kawe nipa akoso ọrọ aje ni Fasiti ilu London.

Wigwe bẹrẹ iṣẹ oluṣiri owo nileeṣẹ Coopers & Lybrand, ko to o darapọ mọ ile ifowopamọ Guaranty Trust Bank nibi to ti ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Lọdun 2002, Ọgbẹni Wigwe ati ẹni ti wọn jọ n dokowo pọ, Aigbpje Aig-Imoukhuede, ra Access Bank.

Laarin ọdun 2002 si 2017, banki naa kuro ni ipo karundinlaadọrin ni Naijiria, si ipo kẹrin laarin awọn banki to tobi julọ.

Orukọ iyawo Wigwe ni Chizoba, wọn si bi ọmọ mẹrin funra wọn