Ó gba ìpè lọ́dọ̀ọ́ iléeṣẹ́ ọ̀tẹ̀lẹ̀múyẹ́ Isreal tó sọ pé: Wọ́n ní ká ju àdó olóró lù yín,wákàtí méjì péré lẹ́ ni láti sá kúrò- Gaza/Isreal

    • Author, Alice Cuddy
    • Role, Journalsit
    • Reporting from, BBC News, Jerusalem

Ipe wọle sori ago Mahmoud Shaheen ni afẹmọju.

Lọjọ Kọkandinlogun oṣu Kẹwa 2023 ni nkan bi ago mẹfa aabọ owurọ.

O si ti pe ọjọmejila gbako ti Israel ti n kogun ja Gaza.

Aja kẹta ile oniyara mẹta rẹ́ to n gbe ni adugbo Zahra ni Ariwa Gaza lo wa.

Titi di akoko yi, adugbo rẹ ko gburo ado oloro ti Israel n ju sawọn agbegbe mii.

O gbọ ohun awọn eeyan nita tawọn eeyan si n pariwo pe ''Ẹni lati sa asala''

''Tori wọ o ni pẹ sọ odo aloro lu ibi tẹ wa''

Bo ṣe n sa jade kuro ninu ile rẹ to re sọda titi lati wa ibi sa pamọ si ni ipe wọ ori ago rẹ.

Wọn o kọ orukọ ẹni to n pe e sibẹ.

''Lati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Israeli la ti n pe''

Ohun arakunrin kan lo sọ bẹ fun gẹgẹ bi Mahmoud ṣe wi.

Ipe naa ko ju wakati kan lọ-ko si si ipe kankan to gba nile aye rẹ to dẹru baa ju eyi lọ.

A o ju ado oloro lu ile alaja pupọ mẹta.

Ẹni to pe Mahmoud darukọ rẹ lẹkunrẹrẹ to si sọ ede larubawa si.

''O sọ fun mi pe oun fẹ sọ ado oloro ju ile alaja pupọ mẹta ...o si paṣẹ pe ki n kuro lagbegbe ibẹ''

Ile Mahmoud ko si ninu ewu amọ pẹlu ipe to gba yi, o di dandan ko seto bawọn ọkẹ aimọye eeyan yoo ṣe kuro nibi ti wọn fẹ sọ ado yi si.

O pa ọkan pọ to si sọ fun arakunrin to n ba sọrọ lori ago to pe orukọ ara rẹ ni Abu Khaled lati ma ṣe ja ipe naa.

Mahmoud loun ko mọ idi ti wọn fi yan oun lati jẹ iṣẹ ikilọ fawọn eeyan to wa layika amọ o ni oun gbiyanju gbogbo ipa oun lati ri pe awọn eeyan ribi sa nibẹ.

Oun ati awọn alabagbe rẹ jijọ ko awọn eeyan kuro nibi ile naa ti gbogbo wọn si jijọ wa nibẹ ti ado oloro ṣe sọ ni iṣoju wọn koro.

Lasiko ogun yi ileeṣẹ ologun Israel ti pe awọn eeyan Gaza nigba mii lati kilọ fun wọn pe awọn yoo sọ ado oloro lu wọn.

Alaye Mahmoud ṣafihan iru bi ikilọ yi ṣe n waye leyi ti a ko nimọ nipa rẹ ṣaaju asiko yi.

BBC kan si ọgbẹni Mahmoud lẹyin ti ọpọ awọn araadugbo Zahra tọka si gẹgẹ bi ẹni to n gba iru ipe yi.

A ko le ribi fidi ọrọ mulẹ ohun ti wọn jijọ sọ lori ipe naa eyi to sọ fun lẹyin ọsẹ mẹta ti wọn ba sọrọ lori ago.

Ṣugbọn ohun to sọ farapẹ nkan tawọn eeyan oju opo Facebook kan sọ lọjọ naa ati pe o papọ mọ aworan satalaaiti to ṣafihan adugbo naa ṣaaju ati lẹyin igba ti wọn ju ado oloro lu u.

A mọ wi pe lọjọ taa n wi yi, aimọye eeyan lo di alainile bi Israel ti ṣe sọ ado oloro lu ile ibugbe marundinlọgbọn to si pa odindi adugbo kan rẹ mọlẹ.

Awọn to di alainile yi sa asala pẹlu ẹru diẹ ti wọn ri ko ti wọn si fọnka kaakiri Gaza.

IDF to jẹ ileeṣẹ ologun Israel sọ pe awọn aaye ibi tawọn ọmọ ogun Hamas wa nikan lawọn n sọ ado oloro lu ati pe awọn a maa tẹle ilana to ba ofin agbaye mu.

''Yin ọta ikilọ ki a ba a le mọ pe lootọ lo fẹ sọ ado oloro lu wa''

Mahmoud sọ pe o dabi ere ni nigba ti arakunrin naa bẹrẹ si ni sọrọ lori ipe yi.

Awọn to wa ni itosi sọ pe o ṣeeṣe ki o jẹ ayederu ipe.

Lati igba ti ogun ti bẹrẹ lawọn atẹjiṣẹ ti n kilọ fawọn eeyan lati sọra fun ipe ayederu.

Mahmoud ni oun sọ fun ẹni to wa lori ipe naa lati yin ọta ikilọ kawn baa le mọ pe lootọ lo n kilọ pe kawọn kuro lagbegbe naa.

O loun ro pẹ bawọn to ba wa loju oorun ko ba gbọ ariwo awọn eeyan layika, wọn o ṣa gbọ iro ọta to ba dun.

Bi ere o sọ pe awọn ri ti wọn yin ọta ikilọ to ṣeeṣe ko wa lati ọwọ diroonu kan.

O sọ pe o ba ile kan to wa ni itosi ibi tawọn wa.

''Mo sọ fun pe ko tun imi yin ṣaajuko to ju ado oloro.''

Mahmoud sọ pe kia lo yin ẹlẹẹkeji naa.

Bayiiti Mahmoud wa ri aridaju pe kii ṣe ere, o gbiyanju lati fi ẹjọ da onitọhun duro ki o to yin ado oloro naa.

Mo sọ fun pe ''Ma dalẹ wa nipa yinyin ado oloro lu wa lasiko ta baa n sa jade''

Arakunrin naa sọ pe oun yoo fun Mahmoud lasiko si.

Mahmoud loun ranti pe o ni ''Oun ko fẹ ki eeyan kankan ku''

Esi ti Mahmoud fun pada ni pe oun ko fẹ ki eeyan kankan tiẹ farapa bo ṣe lu wu ko kere mọ.

O ni oun ko ja ipe naa ti oun si n saare kaakiri adugbo la ti maa kesi awọn eeyan ki wọn kuro ninu ile.

Mahmoud sọ pe awọn araadugbo naa n ba oun kesi awọn eeyan lati jade ki ado oloro to ja lu wọn mọle.

Ọkẹ aimọye eeyan lo sa asala si oju titi ni adugbo to ṣe pe wọn kii gbọ ariwo tẹlẹ.

Asọ ti ẹlomii wọ sun ati jalabia lo wa lara ọpọ to ribi sa jade.

Adugbo yi to wa ni ariwa odo Wadi Gaza ni ibi ti Israel sọ fun awọn araalu pe ki wọn sun lọ nigba ti ogun ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Ọpọ ile ati ṣọọbu itaja lo kun ibi to fi mọ ile ẹkọ fasiti ati awọn ọgba igbafẹ.

Nibi awọn ọgba igbafẹ to wa nibẹ lawọn eeyan ko ara wọn jọ si lẹyin ti ikilọ yi waye.

Mahmoud ni ko ye oun idi ti wọn fi fẹ ju ado oloro si adugbo rẹ.

O loun gbiyanju lati sọ fun arakunrin naa pe ko ma ṣe ju ado oloro lu awọn.

O ni ''mo beere lọwọ rẹ pe ki lo de tofi fẹ ju ado oloro si ile wa?

O fesi pada fun Mahmoud to si ni ''O ni awọn nkan toju wa n ri ti ẹ o ba wa foju ri''

Arakunrin naa ko sọ itunmọ ọrọ bi owe to sọ.

''Aṣẹ to wa lati ọdọ awọn to ju emi ati ẹlọ ni asi ti gba aṣẹ pe ka sọ ado loro yi silẹ''

Nigba ti wọn ko awọn eeyan kuro lagbegbe naa arakunrin naa to si wa lori ago pẹlu Mahmoud wa sọ fun pe awọn yoo bẹrẹ si ni ju ado oloro lu awọn ile naa.

Aya Mahmoud ja. O beere lọwọ rẹ pe ''ti wọn ba wa lọ ṣeṣi ju ado oloro ju ile mi nkọ?''

Arakunrin naa ni ko ṣe suuru diẹ.

Ko pẹ ti ọkọ baalu ilẹ Israeli kan fo kọja ladugbo wọn.

Mahmoud ranju kalẹ ti wọn si fi sọ ado oloro lu ọkan ninu awọn ile to sunmọ ti tiẹ,

''Ile taa fẹ ree, ẹ sun sẹyin.''

Bayi larakunrin naa ṣe sọ fun Mahmoud lori ago bi ile bẹrẹ si ni dawo.

Lẹyin igba naa, wọn ju ado oloro lu ile meji to ku.

Aworan agbegbe yi tawọn eeyan ya ṣafihan awoku ile mẹtẹẹta naa ati awọn araadugbo to n rin kaakiri pẹlu iyalẹnu lẹyin ti ado oloro wo lu ile wọn.

Ọrọ ti eeyan kan kọ soju opo Facebook sọ ni nkan bi ago mẹjọ abọ ku diẹ pe wọn ti wo ile alaja pupọ mẹtaa patapata.

Mahmoud loun ranti pe ohun arakunrin naa sọ nigba ti wn pari iṣẹ pe ''a pa wọn rẹ patapata!''

Bẹ́ẹ naa larakunrin naa sọ lori ago pe o le pada sile, ati ṣetan bayii.

Mahmoud ni nkan to ṣẹlẹ yi daru mọ oun loju.

Ilu Gaza lo ti n gbe lati nkan bi ọ́dun mẹẹdogun to si n mojuto iṣẹ dokita oniwosan eyin rẹ ati awọn ọmọ rẹ.

''Mo sọ fun pe adugbo ti kii ṣe adugbo ologun ni Zahra.Ko si ajoji nibi.Mo gbiyanju lati jẹ ki ọrọ mi ye.Kii ṣe adugbo to sunmọ ibode a o si koju ikọlu kankan ri,Adugbo to jina si wahala ni ibi''

Eeyan kan kọ si oju opo adugbo naa ni Facebook pe ki awọn eeyan wa ṣe iranwọ ounjẹ ati awọn nkan eelo miran fawọn ti ado oloro kọlu ile wọn.

Awọn eeyan bẹrẹ si ni wa ibi ti wọn o foripamọ si.

Awọn adoola ẹmi naa si bẹrẹ si ni ko gbogbo panduku ile to wo lulẹ kuro lọna.

ti wọn si pa ina to sọ lẹyin ti ado oloro ba awọn ile naa.

Awọn ti ile wọn ṣẹku lẹyin ikọlu yi pada sile.

Ọkan awọn kan balẹ ti wọn si ro pe ko si ewu mọ.

Ọkan ninu wọn sọ fun wa pe''A pada sile taa si ro pe wọn o ni ju ado oloro lu wa mọ''

O ba ipe lori foonu ti ko gbe orukọ jade

Lọjọ taa n wi yi naa, Mahmoud ba ipe kan ti ko ri gbe lori ago rẹ lẹyin igba to ki irun Isha tan lalẹ.

Ko si orukọ ẹni to ni nọmba naa lori ipe ''missed call yi''

Aya rẹ ja. ''O sọ si mi lọkan pe wọn yoo tun ju ado oloro lu awọn ile ti ibugbamu yoo si waye.Amọ mi o mọ ibi ti yoo ti waye.Ẹru bami pe ṣe kii ṣe ile mii ni wọn fẹ doju kọ bayiitabi eyi to sunmọ mi?''

Foonu rẹ tun dun jade ni kopẹ. Ọtọ larakunrin to baa sọrọ lọtẹyi.

Ohun naa sọ pe awọn ri pe onilaakaye eeyan ni Mahmoud jẹ tori naa lawọn ṣe tun pe pada lẹyin iṣẹlẹ lo waye lowurọ.

Daoud ni ẹni naa pe orukọ ara rẹ.

Gbogbo bi arakunrin naa ṣe n darukọ rẹ to si n sọ nipa ọmọ rẹ fun ko irẹwẹsi ba ọkan Mahmoud.

Gẹgẹ bi Mahmoud ṣe sọ, arakunrin wa gbiyanju lati ṣalaye nkan to n ṣẹlẹ ni Gaza fun.

''O bẹrẹ si ni sọ fun mi pe 'ṣe o ri bi Hamas ṣe fi ọbẹ dunbu awọn ọmọde yẹn?''

Mahmoud fesi pada pe ''ilana ẹsin wa ko faaye gba iru nkan bẹẹ''

O loun parọwa si ohun to wa lori foonu naa lati ma ṣe fi iya jẹ alaṣẹ amọ o ni oun mọ pe pabo ni yoo ja si.

Mahmoud sọ pe arakunrin naa sọ fun oun pe awọn yoo sọ ado oloro sawọn ile mii lalẹ ọjọ yẹn ati pe yoo ni lati sọ fun awọn eeyan pe ki wọn kuro ninu ile wọn lẹẹkan si.

O kọkọ ro pe ile to sunmọ awọn mẹta ti wọn wo ṣaaju lo kan ati awọn ile mii to wa lẹgbẹ rẹ.

O sọ fun mi pe ''A fẹ ki o lọ sọ fun awọn eeyan ki wọn kuro lagbegbe ile wọn''

mo si sọ fun pada pe ''O ni lati fun mi lasiko si''

Mahmoud bẹrẹ isẹ ni pẹrẹwu.

O ni ''a ko gbogbo awọn eeyan koda a tun ko awọn eeyan to wa ni ile kan nitosi ibẹ kuro tori wọn sunmọ ibi ti wọn fẹ sọ ado oloro si''

Ni igba taa n wi yi, inu okunkun lọpọ ibi wa ni Zahra.

Ina foonu ni ọpọ fi n palẹmọ.

Awọn kan ribi ko ẹru ti wọn ti di silẹ kalẹ ṣugbọn awọn mii ko ri nkankan mu jade.

Olugbe ibẹ kan Abdullah al-Khatib, sọ pe ''A o mọ ibi ta an lọ.A kan sa jade lae mu nkankan lọwọ''

Eeyan kan to fi ọrọ ranṣẹ siwa loju opo whatsapp ṣapejuwe nkan to waye lalẹ ọjọ naa bayi pe ''A o ri nkankan .Gbogbo nkan to wa lori ọkan mi ni bi emi ati mọlẹbi mii yoo ṣe wa lalaafia''

Orisi ọgbọn ni Mahmoud ṣa n da lati ri pe oun ra asiko sii fawọn eeyan lọwọ arakunrin Daoud to n ba a sọrọ titi ti gbogbo eeyan fi de ibi ti ko lewu.

Bẹẹ wọn si tun wa ninu ọkọ wọn lati le ferege ti wahala ba bẹ silẹ.

Ile mẹta ni wọn sọ ado oloro si.

Bi Mahmoud ṣe n wo iṣẹlẹ yi lọkunrin to wa lori ago si n sọ fun pe awọn yoo wo ile mẹta mii sii ti awọn araadugbo yo si pada si ile wọn lẹyin igba naa.

Ibi to ti n sọ eleyi ni wọn tun gbe aṣẹ mi yọ si wọn lojiji.

Mahmoud ranti pe wọn ni ''Gbogbo ile to wa lapa iwọ oorun oju ọna naa ni wọn yoo wo bayii.''

Ile taa n wi yi ju ile alaja pupọ ogun lọ ati aimọye idile.

Mahmoud sọ fun arakunrin naa pe ''Awọn eeyan kan wa ti a o ti ribi fi to leti pe ile wọn wa ninu ewu.

''Fun wa lasiko si, koda bo jẹ titi aarọ ki wọn baa le ribi jade abi nibo lo fẹ ki gbogbo awọn eeyan wọnyi gba lọ?

Esi ti o fọ fun Mahmoud ni pe ''Aṣẹ ti gun,a o si sọ ado oloro si gbogbo awọn ile alaja pupọ wọnyi nii laarin wakati meji''

Igbe ni Mahmoud mu bẹnu to si kesi gbogbo awọn eeyan lati bẹrẹ si ni jade ninu awọn ile wọnyii.

Awọn ara adugbo juwe bi onikaluku ṣe n sa asala ti awọn ọmọde si n sunkun yọbọ. Awọn obi ati ọmọ mii ko ri ara wọn mọ ninu are asapajude to waye.

Pẹlu bi onikaluku ṣe n bẹru Mahmoud ṣi wa lori foonu pẹlu arakunrin yi to si n gbiyanju lati ra asiko si ki wọn ma ba ju ado oloro nigba ti wọn da.

Ẹni to n ba sọrọ lodi keji ko bikita rara. O ṣaa n sọ tiẹ lọ ni.

''Koda o sọ fun mi pe, mi o ni sọ ado oloro lu yin ayafi to ba fun mi ni iyọnda.''

Mo sọ fun un pe ''Rara. Mi o le fun ọ ni iyọnda.

Mi o fẹ ko ju ado oloro lu eeyan kankan.Mo maa gbiyanju lati gbe awọn eeyan kuro nibi ewu amọ to ba wu ọ lati ju ado oloro ma sọ fun mi pe o nilo iyọnda mi lati ju u''

''Kii ṣe Mahmoud shaheen ni yoo ju ado oloro lu Zahra''

Iya agbalagba to ni ipenija aara kan n gbe ninu ọkan lara awọn ile to wa lẹyin.

Mahmoud ati awọn to wa ni itosi rẹ sọ fun awọn araadugbo lati sare gidi gaan pẹlu ọkọ wọn ki wọn baa le ri iya naa gbe jade.

Ọkan wọn kotun balẹ lori ile itọju awọn agbalagba kan nibẹ.

''Amọ arakunrin to wa lori foonu sọ pe gbogbo ile to wa nibẹ loun yoo ju ado oloro si''

Mahmoud sọ pe ohun tawọn ri kii ṣe ibugbamu kekere bi kii ṣe biba gbogbo awọn ile igbe jẹ patapata.

''Alẹ taa n wi yi roro fun awọn olugbe Zahra''

Awọn aworan ati fọnran fidio tawọn ara adugbo ṣalabapin ṣafihan nkan ti o ku lẹyin ikọlu yi.

Loju opo Facebook, eeyan kan sọ pe ni ago mẹsan kọja iṣẹju mọkanla''gbogbo ile alaja pupọ to wa ni Zahra ni wọn n ju ado oloro lu bayii. A fi ki Ọlọrun ṣaanu wa''

Eeyan kan to ba BBC sọrọ loju opo Whatsapp sọ pe ''A o mọ ibi taa gba lọ-awọn kan ni ka lọ si awn ileẹkọ, awọn kan ni ka lọ si ibudo awọn ogunlende Al-Nuseirat. Nibi taa wa yi ni ado oloro n rọjo le wa lori''

Mahmoud beere lọwọ arakunrin naa pe nibo ni ki oun ko awọn araadugbo lọ.

O ni ''Ninu ko gbe wọn lọ si ila oorun tabi ki wọn si lọ si iwọ oorun.A ti ko wọn lọ si ila oorun yoo le diẹ tori Zahra sunmọ Al Mughraqa lati ibẹ- ibẹyẹn kii ṣe ibi ti eeyan le lọ tori ewu to wa nibẹ.Awọn eeyan tiẹ n bẹru lati lọ si tẹlẹ gaan ''

''O sọ fun mi pe gbe wọn lọ si iwọ oorun ni opopona Palestine.''

''Mo da laba pe boya ki wọn lọ si fasiti Palestine o si sọ pe bẹẹni''

Mahmoud ko awọn eeyan lọ si ibẹ to fi mọ awọn to sa asala wa si Zahra nigba ti wọn ju ado oloro lu ile ti wọn ni ariwa Gaza.

Awọn ara adugbo mii naa jẹri si pe awọn lọ si fasiti ọhun koda fidio ti eeyan kan ṣalabapin loju opo Facebook ṣafuihan bawọn eeyan ṣe n rinti wọn si n wa ọkọ lọ si ibẹ.

Ẹni to ya fidio naa n ṣadura tẹle wọn lẹyin lọ sibẹ.

Mahmoud ko gbe ipe ṣugbọn wọn pe pada sori ago alabagbe rẹ

Mahmoud sọ pe inu ibẹrubojo lawọn eeyan fi duro ni fasiti naa.

O lawọn n gbọ iro ado oloro kikan kikan lati jina .

Nigba to di asiko kan, ẹni to n ba sọrọ lori foonu beere pe ṣe ina batiri ṣi ku lori foonu rẹ.

O loun sọ pe ida 15% lo ku lori ẹrọ alagbeka oun.

O sọ fun Mahmoud pe ko ma jẹ ko jo tan, oun yoo pe pada laipẹ.

Ipe to tẹle ipe yi lẹyin igba naa kii ṣe kekere.

'' Wọn o pe lati sọ fun mi pe ''Bayii a ṣetan lati ju ado oloro lu ile mii ati omiran ati omiran.Wọn ko sinmi ipe ti wọn si ni awọn ko ni ye pe ayafi ti awọn ba ṣetan ikọlu''

Lasiko kan, ẹrọ alagbeka alabagbe kan dun ti ẹni to pe sori ago si ni oun fẹ ba Mahmoud Shaheen sọrọ.

Mahmoud mọọmọ jina si iyawo ati ọmọ rẹ ni gbogbo asiko to n ṣiṣẹ yi ki wọn ma ba wa ninu ewu lati ọdọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ Israel.

Nigba to de fasiti o ri pe alaafia ni wọn wa o si tun kuro lọdọ wọn lẹẹkan si.

Ko si oorun fawọn eeyan Zahra.Mahmoud nigbogbo eeyan n foju sun pe ko jẹ ka wọn mọ nkan to tun n ṣẹlẹ.

''Wọn n bi mi pe dokita, ṣe wọn tipe pada lati sọ pe a le pada sile wa bayii?ṣe wọn ti sọ ibi to kan ti ado oloro yo otun ti dun bayii?''

Ilẹ mọ.

Eeyan kan kọ ọrọ si oju opo Facebook pe nilẹ to mọ ni nkan bi ago mẹjọ aarọ kọja yi, wọn ṣi n ju ado oloro silẹ.

Fidio tawọn eeyan ya mọjumọ ṣafihan bi oju sanmọ ṣe pọn.

Mahmoud ati arakunrin to pe ara rẹ ni Daoud ko sinmi ọrọ titi ti gbogbo adugbo fi dakẹ lọọlọ.

Lẹẹkan naa ko ba pe Mahmoud mọ

''Wọn o sọ fun wa pe ka pada sile, ka kuro nibi taa wa tabi ka si wa ibi gba lọ.Tori naa awọn eeyan duro titi di ọsan,igba naa ni wọn to bẹrẹ si ni gbera''

Ni wakati ati ọjọ to tẹle iṣẹlẹ yi, awọn eeyan Zahra bẹrẹ si ni tuka ti onikaluku si n wa ibi gba lọ.

Mahmoud sọ pe ''Koda awọn ti ile wọn ṣi wa nibẹ, ko si nkan amayedẹrun kankan ti wọn le ṣamulo..gbogbo nkan lo bajẹ.Ile burẹdi,ile itaja,ko si omi, ko si ina''

Ile Mahmoud ko wo patapata bo tiẹ ṣe pe o farapa ninu ikọlu naa.

Adugbo to ti n ṣe iṣẹ gẹgẹ bi dokita oniṣegun itọju eyin lati nkan bi ọdun mẹẹdogun sẹyin ti parẹ patapata.

Ko si nkankan to ṣẹku fun ni Zahra.

O ti gbe mọlẹbi rẹ lọ si agbegbe ibomiran ni Gaza nibi to ti fori pamọ si ile ọrẹ rẹ to kun fun awọn eeyan.

''Mi o ronu mọ nipa ile iwosan mi tabi ile mi mọ.Gbogbo nkan to wa lọkan mi bayii ni baa ṣe ruu la''

Ko si nkankan ninu afẹ aye.Laarin iṣẹju aaya, gbogbo rẹ yoo poora.

Lootọ ni pe Israel kilọ fawọn eeyan Gaza ki wọn to sọ ado oloro lu wọn lọpọ igba amọ awọn eeyan ni wọn o fi ikilọ yi sita lasiko fun awọn lati le palẹmọ.

IDF sọ fun BBC pe ''lara igbiyanju wa lati tu ikọ Hamas ka la fi n ṣe ikọlu si awọn aaye ti ologun Hamas wa kaakiri Gaza.''

Wọn ni ''iru ikọlu bayii a maa waye ni ibamu pẹlu ofin agbaye to fi mọ gbigbe igbesẹ lati ri pe awọn araalu ko farapa pupọ''

Ilẹeṣẹ ilera ti Hamas n dari ni Gaza sọ pe o le ni eeyan ẹgbẹrun mẹwaa ti o pade iku lọwọ ikọlu Israel lati igba ti ogun yi ti bẹrẹ.

O le ni ida mẹrin wọn to jẹ awọn ọmọde.

Ikọlu igbẹsan ti Israel bẹrẹ gberasọ lẹyin ikọlu ọjọ Keje oṣu Kẹwaa ti Hamas ṣe si wọn eyi to ṣokunfa iku eeyan to le ni 1400 to fi mọ awọn ọmọde ati obinrin ati awọn mii to wa ni igbekun.

Ọpẹlọpẹ akitiyan Mahmoud igbagbọ ni pe ko si eeyan kankan to padanu ẹmi rẹ lọjọ taa n wi yi.

Amọ ijẹri rẹ si bi iru ikọlu yi ṣ n waye jẹ itọka si iporuru ọkan to maa n deba awọn eeyan Paestine bi wọn ṣe n ri ile ati ọna wọn to n parẹ mọlẹ.

BBC ti ba aimọye idile to gbe ladugbo Zahra sọrọ.

Agbegbe tawọn oniṣẹ ọwọ oniṣowo n gbe.

Tawọn ẹbi a maa jẹ falafel ati Pizza leti okun.Ti awọn ọmọde a si maa gba bọọlu lafẹmọju ti wọn a si tun maa gbọ irun pipe kaakiri adugbo.

Ninu apa keji apilẹkọ yi, ao kan si awọn to gbe ni adugbo yi ti wọn pe ibẹ ni ile ko to di pe gbogbo rẹ parẹ mọjumọ.

Awọn to fikun iroyin yi: Muath Al Khatib ati Dima Al Bablie ẹka BBC News Arabic

Aworan: Mike Hills

Ayẹwo ijẹri si fidio : Shayan Sardarizadeh

Samuel Horti lo ṣe olootu rẹ.