You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìbọn ni wọ́n fi tú orí bàbá mi lásìkò t'áwọn agbébọn kọlú ìjọ St. Francis ìlú Owo - Àwọn olùjọ́sìn sọ ìrírí wọn lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Awọn olujọsin ijọ Aguda St Francis Xervier Catholic Church nilu Ọwọ nipinlẹ Ondo ṣi n ṣalaye iriri wọn lasiko ti awọn agbebọn kọlu ile ijọsin naa ni ọdun 2022 nibi ti eeyan ogoji ti di ero ọrun, ti ọpọ miran si fi ara ṣeṣe yannayanna.
Iṣẹ isin bẹrẹ pada ni ile ijọsin naa ni ọjọ isinmi ajinde ni ọjọ kẹsan oṣu kẹrin ọdun 2023, nibi ti ọpọ olujọsin ti tu jade lati jọsin nibẹ bi o tilẹ jẹ pe pupọ wọn lo ṣi n daro iṣẹlẹ naa.
Ninu awọn ti BBC ba sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọrọ ohun ti oju wọn ri lọjọ naa.
Ọkan lara sọ bi oju rẹ ṣe ri iku baba rẹ lasiko iṣẹlẹ naa.
‘Baba ati iya mi ko lanfani ati oreofẹ ti mo ni lati wa laye lẹyin iṣẹlẹ naa’
Chinedu Onuoha wa lara awọn olujọsin ni ijọ Aguda St Francis Ọwọ lọjọ ti awọn agbebọn kọlu ijọ naa.
Ni iwaju rẹ bayii lawọn agbebọn ti yinbọn pa ọpọlọpọ eeyan ti wọn si tun ṣe ọpọlọpọ leṣe ninu eyi ti baba ati iya rẹ wa.
Gẹgẹ bi Chinedu ṣe sọ, igun kọlọfin kan ti oun pamọ si ni ori fi ko oun yọ lọwọ iku lasiko ti ọta ibọn fi n fo kaakiri lọjọ naa.
“Baba ati iya mi ko loore ọfẹ ati moribọ lọwọ iku bi emi. Ibọn ba mama mi ni ẹgbẹ, wọn fi ibọn fọ ori baba mi lasiko to n gbiyanju lati fọ ori fẹnsi ile ijọsin naa sa asala fun ẹmi rẹ.”
Chinedu ṣalaye siwaju sii pe lẹyin iṣẹlẹ naa, oun kọkọ ri iya oun nibi ti ẹjẹ ti n ṣan jade lara rẹ loju ọgbẹ ọta ibọn to wa lara rẹ oun si sare gbe e lọ si ile iwosan ki oun to pada wa si ile ijọsin naa lati wa baba oun.
Amọṣa ẹgbẹ ogiri ile ijọsin naa lo ti ri baba rẹ ninu agbara ẹjẹ.
End of Àwọn ìròyìn míràn míràn tí ẹ tún lè ká
“Mama mi ko ye e. Ile iwosan akọkọ ko gba a lọwọ wa ki a to gbe e lọ si ile iwosan miran ni ilu Akurẹ, ṣugbọn oju ọna lo ti dakẹ.”
Nigba ti o ṣalaye de aaye kan, omije n bọ loju Chinedu. O sọrọ lori alafo ti awọn obi rẹ fi silẹ nipa iku aitọjọ yii ṣe n ni ipa ribiribi ninu mọlẹbi rẹ.
“Ọmọ mọkanla ni awọn obi mi fi silẹ lọ, mẹfa ninu wọn lo ṣi wa nile iwe lasiko ti ikọlu naa waye. Awa ti a jẹ agbagba laarin wọn lo n gbe bukata wọn lori bayii.”
O ni iranwọ ti awọn ri gba latọdọ ijọba fun iṣẹlẹ ko fi bẹẹ pọ rara.
O fi kun un pe ibeji ni iya oun, ibeji rẹ ko si tii gbadun lati oṣu mẹwaa ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ si iya oun.
‘Ẹsẹ mi mejeeji ni wọn ge nitori ikọlu naa’
Arabinrin Magret Attah naa wa lara awọn ti ori koyọ ninu ikọlu awọn agbebọn ni ijọ aguda St Francis nilu Ọwọ.
Tẹrin tọyaya loun naa fi wọ ile ijọsin lọjọ buruku esu gbomimu naa laimọ pe ọjọ yii ni oun yoo fi ẹsẹ oun mejeji rin gbẹyin.
Nitori ọgbẹ to fara gba lasiko ikọlu naa, nṣe lawọn dokita ni lati ge ẹsẹ rẹ mejeeji kuro lati le e doola ẹmi rẹ to si di ẹni to n lo kẹkẹ wheelchair bayii.
“Ara mi ti n ya. Iriri naa le diẹ ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹmi ṣi wa lẹyin iṣẹlẹ bẹẹ”
Arabinrin Magrett Attah ṣalaye fun BBC pe awọn ọmọ oun lo n ti oun kiri lori kẹkẹ naa.
O ni laipẹ laijina oun yoo ra ẹsẹ igbalode ti wọn n pe ni ‘prosthetic legs’ laipẹ lati lee maa rin kiri.
‘Alọ la ri, a ko ri abọ lori ijẹjọ awọn agbebọn ti ọwọ ti tẹ’
Lara awọn ti ori ko yọ ninu ikọlu buruku to waye ni ijọ aguda St. Francis nilu Ọwọ ni arabinrin Veronica.
Lẹyin oṣu mẹwaa ti ikọlu naa ti waye, oun atawọn aburo rẹ ko tii bọ lọwọ ọgbẹ ọkan adanu wọn lasiko iṣẹlẹ naa.
“Ko si ọgbẹ ọta ibọn kankan lara mama mi lasiko ikọlu naa, ṣugbọn mo gbagbọ pe ijaya iṣẹlẹ naa lo gba ẹmi iya mi sinu ijọ naa.”
Veronica wa lara awọn to jọsin lasiko ti wọn ṣi ile ijọsin naa pada lẹyin oṣu mẹwaa ti iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn bi o ṣe wọ inu ile ijọsin naa lọjọ naa ni ara rẹ bẹrẹ si ni ṣe bakanbakan.
“Lati igba ti mo ti lọ nigba ti wọn ṣi ile ijọsin naa pada, emi o lọ mọ nitori titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ara mi ṣi n ṣe bakan.”
O ni oun ko mọ iye owo ti ijọba le fun awọn to le rọpo iya oun.
Awọn alaṣẹ ijọba atawọn ileeṣẹ agbofinro ti kede pe ọwọ ti ba awọn afurasi kan fun lilọwọ ninu ikọlu naa, amọṣa lẹyin oṣu mẹwaa ko tii si iroyin lori ijẹjọ wọn eleyi ti ko dun mọ ọpọ awọn eeyan ti ọrọ kan ninu rara.