You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin tó di ìlúmọ̀ọ́ká níbi àjọ̀dún Ojude Oba ṣàlàyé bí ó ṣe lùgbàdì arun jẹjẹrẹ tí kò gbóògùn
Awọn ọlọgbọn eeyan maa n sọrọ kan wi pe bi ẹmi ba wa, ireti n bẹ.
Bẹẹ gan an lọrọ ri pẹlu Ọgbẹni Farooq Oreagba to di ilumọọka lori ayelujara lẹyin ti fọto rẹ nibi to ti gun ẹṣin wọ ibi ajọdun Ojude Oba ti ọdun 2024 lu ori itagun ayelujara pa.
Ọgbẹni Oreagba wọ aṣọ ofi nla olomi ọsan ati alawọ ewe, bẹẹ ni o wa ilẹkẹ pupa sọrun pẹlu ago lọwọ.
Oreagba tun de fila aṣọ ofi ti o wọ bakan naa, koda o tun wọ awo soju pẹlu siga lẹnu rẹ.
Bi Ọgbẹni Oreagba ṣe ro dẹdẹ kan dudu yii ni o ṣe gun ẹṣin ti wọn wọ oriṣiiriṣii aṣọ alaranbara fun bakan naa.
Bayii ni Ọgbẹni Oreagba n da gọjọ-gọjọ lori ẹṣin ti o ṣi di awo ma lee lọ fun ọpọ eeyan nibi ajọdun Ojude Oba niluu Ijebu Ode nipinlẹ Ogun.
Ọpọ eeyan lo pin fidio ati fọto Oreagba to jẹ oju ni gbese yii kaakiri ori ayelujara.
Oreagba sọrọ lori bo ti lugbadi arun jẹjẹrẹ ti ko gboogun
Oreagba sọ ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan Arise pe loṣu Keji ọdun 2014 ni awọn dokita sọ foun pe oun ni arun jẹjẹrẹ inu egungun eleyii ti ko gboogun.
O ni ''ni ṣe ni mo n ṣọra ṣe bi mo ṣe n gun ẹṣin tori ti mo ba ṣeesẹ, egungun mi le ma to mọ tori arun jẹjẹrẹ inu egungun ni mo ni.
Kete ti mo mọ pe mo ni arun jẹjẹrẹ ti ko gboogun ni ayipada ba iwoye mii.
Nitori pe mi o mọ igba toku fun mi lati lo laye ti iku yoo fi de.
Mo ni lati ṣe akọsilẹ bi gbogbo nnkan ti ṣe pataki fun mi si, ẹbi ni nnkan akọkọ to ṣe pataki fun mi julọ.
Amọ, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o ti pe ọdun mẹwaa ti mo ti ni arun naa bayii.
Ko si ti to asiko fun mi lati lọ bayii.
Ohun ti mo ṣakiyesi ni pe nigba ti mo kuro nibi iṣẹ ti mo n ṣe tẹlẹ ni ileeṣẹ ‘’Nigerian Exchange,’’ lọdun 2010, adinku ba ọrẹ mi lati miliọnu marun un si miliọnu kan.
Nigba ti mo lugbadi arun jẹjẹrẹ lọdun 2014, adinku tun ba iye ọrẹ ti mo ni lati miliọnu kan si ẹgbẹrun un lọna ọgọrun.
Ẹkọ ti mo kọ ninu eyi ni pe a ni lati ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu awọn ọrẹ wa.
Mo maa gbe igbe aye mi bi ẹni pe mi o ni ri ọla - Oreagba
Oreagba ni oun gbe leti okun fun ọdun mẹrin gbako niluu Eko, lai nile nibi kankan niluu Eko.
''Bi mo ṣe di ilumọọka jẹ iyalẹnu fun mi, ayaworan to ya fọto mi lo jẹ ki n di ilumọọka.''
Ọgbẹni Oreagba to jẹ onimọ nipa idikowo nile ifowopamọ sọ pe ''oriṣiiriṣii iṣẹ ọna lo wa lara mi, ọkan wa ti mo kọ ọrọ kan pe mo n gbe igbe aye mi lojoojumọ bi ẹni pe mi o ni ri ọla, tori naa ma dami lẹjọ.
Ọlọrun nikan lo le dami lẹjọ, mo tun kọ nipa oriṣii awọn ọrẹ mi ati bẹẹ bẹẹ lọ.''
Ọgbẹni Oreagba sọ pe oun maa n gbawọn eeyan to larun jẹjẹrẹ ni imọran.
O ni ''emi gan fun ra mi ṣe iṣẹ abẹ ti wọn fi paarọ mundun-mundun inu egungun mi loṣu Kẹjọ ọdun 2014.
Mo gba itọju ‘’kẹmo’’ fun ọjọ mọkanlelogun loṣooṣu fun ọdun mẹjọ.
Amọ, mi o gba itọju kẹmo fun arun jẹjẹrẹ mọ bayii, mo ti sanra pada.
Mo si n gbe igbe aye mi, mo si ti pada sẹnu iṣẹ mi tori mi o le maa lọ sibi iṣẹ lojoojumọ nigba ti mo n gba itọju.
Ọpọ eeyan lo maa n bi mi leere wi pe ṣe lootọ ni mo larun jẹjẹrẹ, wọn saba maa n bi mi wi pe kilode ti inu mi fi maa n dun.
Mo maa n dawọn lohun pe inu mi maa n dun tori mo wa laye, eyi to tumọ si pe ti ẹmi ba wa, ireti n bẹ.
Ibukun lati ọdọ Ọlọrun ni gbogbo ọjọ ti mo ba ti ri laye jẹ.
Mo maa n gbiyanju lati gbawọn eeyan niyanju lori arun jẹjẹrẹ lati le fun wọn ni ireti.''