Ogójì ọdún sẹyìn ní ọmọ wá kú ṣùgbọ́n arákùnrin yí gbè awọ àti orúkọ rẹ̀ wọ tó sì gbé ilẹ bàbá wà tà

Ile ẹjọ kan ni India ti ran arakunrin kan lẹwọn lẹyin ti wọn lo jẹbi pe o n pe ara rẹ ni ọmọ awọn mọlẹbi olowo kan to ti ku lati nkan bi ogoji ọdun sẹyin.

Bawo lo ṣe hun ete yi faduru ọdun yi ti aṣiri ko fi tu?

Ki si ni awọn mọlẹbi sọ nigba ti wọn pada mọ pe eeyan kan wa to n jẹ orukọ ọmọ awọn to ti dawati lati ogoji ọdun sẹyin?

Akọroyin BBC Soutik Biswas se iwadii ọrọ yi to si jo gbogbo rẹ papọ bi iṣẹlẹ yi ṣe waye.

Oṣu Keji ọdun 1977 ni ọdọmọkunrin kan ṣadede poora nigba to n dari ile ẹkọ pada ni ilu Bihar .

Kanhaiya Singh lorukọ rẹ o si jẹ ọmọ kan ṣoṣo ti baba olowo kan lagbegbe Nalanda bi.

Mọlẹbi lo n dari pada lẹyin to kọ idanwo tan ni wọn si lọ si agọ ọlọpaa lati fẹjọ sun pe awọn n wa.

Gbogbo igbiyanju lati wa arakunrin yi ja si pabo ti eleyi si ko iporuru ọkan ba baba rẹ .

Koda o tọ awọn aduhunṣe kan lọ ti wọn si sọ fun pe ọmọ rẹ wa laye ati pe ko ni pẹ yọju.

Ni osu kẹsan ọdun 1981,arakunrin kan to to ogun ọdun yọju si abule kan ti ko fi bẹẹ jina pupọ si ibi ti Kanhaiya n gbe.

Arakunrin yi wọ aṣọ saffron to si n kọrin tọrọ bara.

O sọ fawọn eeyan ilu yi pe ọmọ ọlọla loun jẹ ati pe abule awọn ko jina si ibẹ.

iroyin yi lo de si eti igbọ baba olowo ti ọmọ rẹ sọnu to si gbera lọ yọju wo ni abule yi.

Awọn alabagbe rẹ to tẹle lọ sọ pe ọmọ rẹ ni arakunrin naa.

Nitori pe oju baba yi ko riran daada, o gba to si sọ pe oun yoo gbe pada lọ sile lati maa tọju rẹ.

Bayi ni akọsilẹ to wa lọdọ awọn ọlọpaa nipa bi baba yi ṣe gba arakunrin naa gẹ́gẹ bi ọmọ rẹ to sọnu.

Asiri tu ?

Lẹyin ọjọ mẹrin iyawo baba olowo yi kẹfin pe ọmọ rẹ ti pada de ile.

Oun ati ọmọ rẹ obinrin Vidya pada si abule amọ iyalẹnu lo jẹ ti wọn ri pe ẹni tawọn ri kii se ọmọ awọn to sọnu.

Lara idanimọ ti iya ọmọ sọ pe ko si lara arakunrin yi ni apa kan to wa ni apa osi ori ọmọ rẹ.

Bẹẹ ni ko da olukọ rẹ kan mọ nigba to ri.

Toun ti gbogbo ẹri wọnyi, baba ọmọ arakunrin Singh sọ pe ọmọ oun ni arakunrin naa.

Lẹyin ọjọ diẹ, iyawo baba yi Ramsakhi Devi lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọ́paa pe eeyan n parọ pe oun ni ọmọ rẹ.

Wọn mu arakunrin naa to si lo osu kan lẹwọn ki wọn to gba beeli rẹ.

Ohun to ṣẹlẹ lẹyin igba naa lagbara

Ogoji ọdun to tẹle jẹ eleyi ti arakunrin yi fi n pa irọ orisirisi to si fi rapala titi to fi sọ ara rẹ di ara ọmọ inu mọlẹbi naa.

Toun ti pe wọn gba beeli rẹ, o se awọn ayederu iwe idanimọ , o lọ si ile ẹkọ fasiti, o gbe iyawo lori orukọ ti kii se tiẹ koda o tun bimọ.

Awọn ayederu iwe idanimọ yi lo fi n dibo,o fi san owo ori, o gba kaadi idanimọ orileede o tun gba iwe aṣẹ lati le fi ra ibọn to si ta acre mẹtadinlogoji ilẹ baba olowo yi.

O kọ lati se ayẹwo idanimọ ẹjẹ DNA pẹlu ọmọ obinrin baba olowo yi ki wọn fi le mọ boya lootọ ọmọ iya ni wọn.

O gbe igbesẹ kan to ya ile ẹjọ lẹnu nipa pe o mu iwe ẹri pe oun ti ku wa ki wọn baa fi ma mọ eeyan to jẹ.

Mi o pe ara mi ni ọmọ to sọnu, o wu baba naa lo gba mi wọle

Lẹyin ọpọ ọdun ti o ti bimọ tiẹ to si ti di agbalagba, ọrọ naa pada de iwaju adajọ.

Ni ile ẹjọ ti wọn ti ṣẹjọ yi, arakunrin Gosain sọ fun adajọ pe oun ko sọ pe oun jẹ ọmọ baba olowo.

Nigba ti adajọ ni ko ṣalaye ibi to wa lasiko ti ọmọ yi fi sọnu, ko ri esi to daju fọ fun adajọ.

O ni baba naa ''arakunrin Singh lo gba mi wọle mi o parọ pe emi ni ọmọ rẹ.''

Asẹyinwea asẹyinbọ adajọ gbe idajọ ẹwọn ọdun meje kalẹ le Gosain lori to si ni o hu iwa ọdaran nipa pipe ara rẹ ni ẹni ti ko jẹ.

Ejọ yi ṣafihan pe eto idajọ orileede India mẹhẹ diẹ nipa pe o le ni ogoji ọdun ki wọn to pada wa ribi mu ẹni to huiwa ọdaran yi.

Amọ ṣa awọn kan sọ pe kii ṣe Gosain nikan lo nikan da ọran yi bi kii se pe awọn kan lẹdi apo pọ pẹlu rẹ lati fi parọ fun baba olow Singh pe oun ni ọmọ rẹ to sọnu.

Titi di oni, ko si ẹni to mọ ibi ti ọmọ baba olowo naa gangan poora si.