You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé a lè fòfin de ọmọdé láti lo ojú òpó ayélujára, ọjọ́ orí wo ló yẹ́ kí ọmọdé bẹ̀rẹ̀ lílò rẹ̀?
Ko to iṣẹju marun-un ti ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtala kan ti orukọ rẹ n jẹ Isobel, fi ja irawọ ofin 'ma lọ si ori ayelujra'' ti orilẹede Australia fi de awọn ọmọde.
Atẹjiṣe kan lo wọ ori foonu rẹ lati oju opo Snapchat to jẹ ọkan lara oju opo mẹwaa ti ijọba ilu naa fofin de.
Atẹjiṣẹ naa kilọ pe ko ni i le lo oju opo naa mọ bi ko ba si aridaju pe ọjọ ori rẹ ti le ni mẹrindinlogun (16).
"Niṣẹ ni mo mu fọto mama mi kan, mo si lẹ ẹ mọ oju kamẹra yẹn, o si jẹ ki n wọle lọwọ kan. O tun ki mi pe mo ṣeun ti mo jẹ kawọn mọ ọjọ ori mi."
Isobel lo ṣalaye bẹẹ "Mo tiẹ gbọ pe ẹnikan ti lo oju Beyonce ri". Ọmọ ọdun mẹtala naa lo ṣafikun bẹẹ.
Lati ọjọ kẹwaa oṣu Kejila, awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to mẹrindinlogun (16) lorilẹede Australia ko ni i le maa lo oju opo ayelujara mọ.
Gẹgẹ bi ijọba Australia ṣe wi, fifi ofin de awọn ọmọde yii jẹ ofin agbaye onipele akọkọ ti ọpọ obi naa mọ nipa rẹ.
Wọn ni ohun to wa fun ni lati da aabo bo awọn ọmọ naa nipa awọn ohun to le ṣakoba fun wọn.
Awọn nnkan bii idunkooko mọ ni lori ayelujara, ati pe ijọba fẹ ki wọn ni ẹkọ nipa awọn nnkan wọnyi, ki wọn si le sun bo ṣe yẹ kọmọde sun, ki irori wọn le peye bo ṣe yẹ fun ọmọde.
Bo tilẹ jẹ pe mama to bi Isobel, iyẹn Mel, gba a laye lasiko kan lati maa lo oju opo TikTok ati Snapchat, to si maa n mojuto ohun tọmọ rẹ n ṣe lawọn oju opo naa, ireti rẹ tipẹ ni pe ofin ti wọn fi de wọn yii yoo le jẹ ki awọn obi le fi aala si ohun ti awọn ọmọ wọn n ṣe lori ayelujara.
Ireti naa si ti n wa si imuṣẹ pẹlu bi ọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ ati awọn ọmọ funra wọn ṣe n fọnrere aabo ti ofin yii yoo mu ba wọn, eyi ti gbogbo aye n wo finni-finni, ṣugbọn to n mu ẹru ba awọn ileeṣẹ to kan.
Báwo ni wọn yóò ṣe ṣòfin náà?
Labẹ ofin ti wọn kede loṣu Kọkanla ọdun 2024 naa, ko ni i si ijiya fun obi ati awọn ọmọ wọn fun pe wọn n lo oju opo ayelujara.
Kaka bẹẹ, awọn oju opo naa ni wọn gbọdọ gbe awọn igbesẹ kan lati ri i daju pe awọn to n lo o to ẹni ọdun mẹrindinlogun, o kere ju niyẹn, tabi ki wọn san owo itanran to to A$49.5m (US$33m, £25m), fun ẹsun to buru ju ninu awọn ẹsun yii bi wọn ba lufin rẹ.
Ileeṣẹ ijọba kan to gbiyanju igbesẹ yii wo nibẹrẹ ọdun yii sọ pe ofin to le fẹsẹ mulẹ ni, ṣugbọn gbogbo ẹ kọ lo ṣee fọkantan.
Wọn ni ilana to n sọ nipa ara ẹni lo ṣiṣẹ ju, ṣugbọn iyẹn naa tun ni i ṣe pẹlu fifi awọn iwe aṣiri nipa ara ẹni kalẹ.
Ọjọ ori ti ko ṣee fidi rẹ mulẹ loju opo ayelujara naa si tun jẹ iṣoro kan to n koju igbesẹ yii, bẹẹ ni a ko le fi oju lasan mọ ọjọ ori ọmọde nigba mi-in.
Sibẹ, abọ iwadii naa sọ pe o ṣee ṣe ki wọn lo ilana ẹrọ igbalode lati mọ ọjọ ori.
"Ti o ba lọ sile itaja ti wọn ti n ta ọti, ti wọn wo ọ lati oke dele, ti wọn ko si le sọ boya ọjọ ori rẹ to tabi ko to lati ra a, wọn yoo beere fun awọn nnkan idanimọ rẹ lati fidi rẹ mulẹ, bẹẹ naa lo ri fun eyi."
Tony Allen, olori lẹka to n ri si ọjọ ori ni UK (Age Check Certification Scheme) lo sọ bẹẹ lẹyin iwadii.
Abajade tiwọn naa mu ariyanjiyan dani. Awọn ọmọ igbimọ oludamọran meji lo tako wọn.
Wọn ni iwadii won ni magomago ninu, o si tun kojubọ ọrọ aye awọn ẹni ẹlẹni . Bo si tilẹ jẹ pe iwadii naa ṣalaye ọna ti awọn ọdọ le fi bọ mọ awon idena ofin yii lọwọ, wọn ko gbiyanju rẹ wo.
Ọgbọ́n ju agbára lọ
Oriṣiiriṣii ọgbọn lo ti lu ori ayelujara pa nipa bi awọn ọmọde Australia ṣe le doju ofin ọjọ ori naa bole.
Awọn ọlọpọlọ to n gbe e jade sọ pe ilana ẹrọ igbalode lo le koju ofin ijọba wa.
Wọn ni awọn ilana onifọto, iru eyi ti Isobel sọ pe oun lo, ko yẹ ko le ja irawọ ijọba bẹẹ.
BBC beere eyi lọwọ Snapchat, agbẹnusọ wọn kan si dahun pe ọpọ igba ni ileeṣẹ naa ti n fi ero ọkan rẹ han nipa iṣoro to le wa fun ọrọ ọjọ ori yii, ati bi wọn yoo se fi ẹsẹ rẹ mulẹ.
" Ọkan lara awọn ipenija naa ree. Ogun ti ko duro ni lati ri i pe ayipada n wa lojoojumọ."
Luc Delany, ọga kan ni K-ID, to maa n yẹ iwe awọn eeyan wo ni Snapchat lo ṣalaye bẹẹ lorukọ oju opo naa.
''Ó dá mi lójú pé òfin yẹn kò ní í ṣiṣẹ́''
Isobel, pẹlu iriri to ti ni, sọ pe o da oun loju pe ofin yẹn ko ni i ṣiṣẹ.
"Bi wọn tiẹ pada fi ofin de mi, ma a yaa wa oju opo miran ti maa lo ni." .
Eyi yẹ fun ajọsọ, iya rẹ, Mel, lo salaye bẹẹ .
Ẹru to n ba Mel ni pe awọn oloju opo le gbe ilana yii gba apa ibomiran, ti yoo jẹ ko ṣoro fun awọn ọmọ lati ri oju opo miran lo.
Stephen Scheeler, ẹni to lewaju Facebook ni Australia ati New Zealand laaarin 2013 si 2017, wa lara awọn to ni awọn ileeṣẹ oloju opo le ma jẹ ki ofin naa ṣiṣẹ, ati pe owo itanran ti wọn fi si i kere si ohun ti wọn le ṣe.
"Fun apẹẹrẹ, Facebook le pa owo yẹn kaakiri agbaye laarin wakati meji. Owo idakọmu ni."
Bẹẹ ni Stephen Scheeler wi.
Àwọn ọ̀dọ́ méjì ti pe ẹjọ́ sí kóòtù tó ga jùlọ
Ipenija kan to tun wa fun igbesẹ yii ni ti ọrọ ofin. Awọn ọdọ meji kan ti pe ẹjọ si kootu to ga julọ lorilẹede naa.
Awọn ọdọ naa sọ pe ofin yii ko tọna, ilana ofin apaṣẹ waa si ni.
Bakan naa nii Alphabet to ni YouTube ati Google, naa ti n ṣalaye awọn ipenija rẹ. Awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan ati awọn amofin kan naa si ti n sọ pe awọn ko fara mọ ọn pẹlu.
Awọn obi kan ti inu n bi lori ofin yii naa sọ pe awọn ṣaa fẹ kijọba mọ pe ko tọna. Wọn ko fẹ ki awọn ọmọ wọn wa ninu igbekun ki wọn too le lo oju opo ayelujara.
"Ki ofin yii too le ṣiṣẹ, ki i ṣe dandan ko jẹ pe o digba ti ida ọgọrun-un (100%) ọmọ ko ba le lo ayelujara."
Ọgbẹni Allen lo ṣalaye bẹẹ. "
To ba ti kan bii ida 80% ninu wọn, awọn to ṣẹku naa yoo tẹle e.."
N jẹ yoo din ewu ku ?
Yatọ si pe boya ofin naa yoo ṣiṣẹ, ohun ti ọpọ n beere ni pe ṣe o yẹ ko waye rara debi ti yoo ṣiṣẹ.
Wọn ni akọkọ ni pe ofin naa yoo mu ki awọn ọmode maa lọ si abala to buru julọ lori ayelujara.
Ṣe o le di wọn lọwọ lati ma lọ si oju opo ti wọn ti n ba ara wọn sọrọ, nibi ti wiwọ ẹgbẹkẹgbẹ ti le waye, ṣugbọn ti ofin yii ko si mu ẹnu lọ sibẹ.?
Awọn ọmọde ṣi tun le lọ si ọpọ oju opo bii TikTok ati YouTube, lai tiẹ dani oju opo tiwọn, eyi to jẹ ewu gidi nitori awọn nnkan to maa n wa loju opo naa ati awọn ipolowo -
ọpọ oju opo lo ti n din awọn nnkan wọnyi ku nibi to ba ti jẹ pe ọmọde lo ni i.
Ọpọ lo n sọ pe awọn oju opo kan ti mu owo ni koko ju ohun to yẹ ki wọn gbe sibẹ fun ọmọde lọ, ṣugbọn awọn eeyan kan n so pe eyi ko ri bẹẹ.
Wọn ni awọn oju opo nla ki i ṣe bẹẹ, fun apẹẹrẹ, oju opo Facebook ni aago kan to maa n dun nigba ti agbalagba kan ba n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ọmọ kekere ju.
Bí òfin yìí kò bá tilẹ̀ ní í fi gbogbo ara pé tan, yóò sì ṣe ohun tó yẹ lára wọn.
Imọ ijinlẹ sayẹnsi lori ayelujara ati ilera wọnu ara wọn pupọ, ojoojumọ ni a si n ko ẹkọ si i lori rẹ.
Awọn iṣẹ iwadii kan sọ pe esi gidi kan ko le ti ara ofin yii jade, paapaa fun awọn ọmọ to wa lati ọdọ awọn akọ to n fẹ akọ, abo to n fẹ abo ati awọn eeyan ti ibalopọ wọn ko tọna to bẹẹ. (LGBTQ)
Ọpọ eeyan lo ti ni ilana to daa ju to yẹ ki ofin yii gba ni pe ki wọn fi ipa mu awọn oloju opo yii lati mọ ohun to le ṣakoba fun awọn ọdọ naa.
Wọn ni ki wọn din agbara rẹ ku, ki wọn si maa kọ awọn ọmọde naa ni awọn ohun to jẹ otitọ ile aye ti wọn yoo ba pade ninu irinajo wọn.
Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ, Anika Wells, ṣo fun BBC pe ijọba oun fẹ ṣe awọn nnkan yii pẹlu.
O ni bi ofin yii ko ba tilẹ ni fi gbogbo ara pé tan, yoo ṣi ṣe ohun to yẹ lara wọn.
"Eyi kọ ni iwosan, ilana itọju ni, ilana itọju ko si pin, ọtun yoo maa de si i ni."