OGUN 2023: INEC fi orúkọ Adelanwa rọ́pò Otegbeye fẹ́gbẹ́ òṣèlú ADC

Iroyin to tẹ wa lọwọ ti jẹ ko di mimọ pe ajọ eleto idibo n’ipinlẹ Ogun ti yọ orukọ oludije Biyi Ọtẹgbẹyẹ kuro gẹgẹ bi oludije s’ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC.

INEC ni pe Adelanwa Mayẹmilọla Micheal ni wọn fi rọpo Ọtẹgbẹyẹ, gẹgẹ bi ojulowo oludije s’ipo gomina ati Ọlatunji Suliat Nike gẹgẹ bi igbakeji rẹ labẹ asia ẹgbẹ naa.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ, wọn ni aṣẹ ile ẹjọ ni ajọ INEC tẹle, ti wọn fi rọpo Ọtẹgbẹyẹ pẹlu orukọ ẹlomiran.

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?

Bẹ o ba gbagbe, Ọtẹgbẹyẹ ni gomina n’ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ẹni to tun jẹ aṣofin lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa lọwọlọwọ n ṣatilẹyin fun Otegbeye.

Koda, o tun kede rẹ sita wi pe ẹni toun yoo tẹle niyẹn ninu eto idibo gomina to n bọ n’ipinlẹ ọhun.

Iwadii fihan pe Adelanwa lo gba fọọmu lati jade du ipo gomina ipinlẹ Ogun, ko to di pe ẹgbẹ naa pada ṣe ipade pẹlu Biyi Ọtẹgbẹyẹ.

ti wọn si tọwọ bọwe adehun pe ẹni ti Amosun nifẹẹ si l’awọn yoo lo gẹgẹ bi ọmọ oye, eyi to mu ki wọn fa a kalẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla, ọdun yii ni ile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abẹokuta paṣẹ pe Ọtẹgbẹyẹ ati awọn oludije mọkandinlogun s’ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ko lẹtọọ lati jade labẹ asia ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu Labour lo pe ẹjọ ọhun, nibi ti wọn ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu ADC wi pe wọn ko tẹle ilana ofin eto idibo, iyẹn Electoral Act tuntun.

Kini o ṣokunfa idajọ ile ẹjọ?

Ọsẹ diẹ lẹyin idajọ yii ni ile ẹjọ kan naa tun paṣẹ pe ki ajọ INEC yọ orukọ Ọtẹgbẹyẹ atawọn oludije naa kuro ninu awọn ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2023, ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu APC pe.

Ọkan pataki lara awọn oṣiṣẹ ajọ INEC n’ipinlẹ Ogun, ẹni to sọ pe ka fi orukọ bo oun laṣiri, n’igba to n ba BBC YORUBA sọrọ laarọ oni,

o ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ẹjọ ṣi n lọ lọwọ lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu ADC, sibẹ, aṣẹ to ba wa lati ilu Abuja l’awọn yoo tẹle n’ipinlẹ Ogun.

Ẹni naa “Abuja nikan lo le fun wa ni orukọ awọn to maa dije.

Aṣẹ ti wọn ba gbe wa fun wa la maa tẹlẹ n’ipinlẹ Ogun.

Idi niyẹn ti wọn fi sọ pe ami idanimọ ẹgbẹ lo maa wa lori iwe idibo, kii ṣe orukọ awọn to ba jade du ipo.

“To ba jẹ pe lati Abuja lo ti wa, wọn maa fi lẹta gbe e nidii, ṣugbọn to ba jẹ pe ‘aṣẹ ile ẹjọ’ ni wọn kọ siwaju orukọ ẹni ti wọn gbe jade, o tunmọ si pe ẹjọ ṣi n lọ lọwọ lori ẹ niyẹn.”

Kini awọn agba ẹgbẹ sọ lori eyi?

Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu ADC lorileede Naijiria, Ọnarebu Razaq Eyiowuawi, nigba to n ba BBC YORUBA sọrọ jẹ ko di mimọ pe orukọ ẹni to wa lori iwe latilẹ niyẹn, ko to di pe awọn fi orukọ Ọtẹgbẹyẹ rọpo ẹ, lẹyin t’awọn tọwọ bọ iwe adehun.

Ọbarebu Eyiowuawi, ẹni to tun jẹ alaga ẹgbẹ naa lẹkun Guusu-Iwọ-Oorun Naijiria sọ pe o ṣee se ki ajọ INEC gbe orukọ naa jade, ati pe nitori idajọ ile ẹjọ giga to waye laipẹ yii si ni.

Ọkunrin naa fi ye wa pe oun nigbagbọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun t’awọn gbe ẹjọ naa lọ yoo da awọn lare, ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ yoo si di ọmọ oye awọn lẹgbẹ ADC

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Adelanwa Mayẹmilọla Micheal ni orukọ to wa nibẹ ko to di pe a ṣe ayipada, ẹni to gba fọọmu gomina naa niyẹn, ko to di pe a fi orukọ Biyi Ọtẹgbẹyẹ sii. Nitori idajọ ile-ẹjọ giga ni wọn ṣe da orukọ naa pada.

“A ni igbagbọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ti a pe ẹjọ si bayii maa gba ẹbẹ wa,

Biyi Ọtẹgbẹyẹ si maa pada di ọmọ oye wa.

Fun awa lẹgbẹ ADC, Ọtẹgbẹyẹ lẹni ti a fẹ, a si nigbagbọ pe laipẹ yii, lagbara Ọlọrun, o da mi loju pe a maa bori.”