You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Látọ̀dọ̀ èmi Alhaja tuntun...! Wo ọ̀rọ̀ Mercy Aigbe àtàwọn gbajúmọ̀ òṣèré míì láti ilé ọdún Eid
Gẹgẹ bi pọpọṣinṣin ọdun Eid ṣe n lọ lọwọ ti oniruuru ajọyọ si n lọ lọtun losi, bẹẹ naa ni awọn gbajumọ oṣere fakọyọ nile ọdun lọtẹ yii pẹlu iru ara ti wọn da ninu imura.
Pataki julọ ni iru awọn ọrọ iwuri ti wọn fi sita si awọn ololufẹ wọn tori pe ẹni ti ọdun ba ba laye lo n ṣọpẹ.
Bo tilẹ jẹ awọn eniyan n pariwo pe ilu le lasiko yii to bẹẹ ti awọn miran ko lanfani yala lati san owo ọkọ tabi owo baalu gọbọi tabi ti owo to le ra ẹran agbo ko tilẹ pe, awọn oṣere fiimu Yoruba to jẹ ololufẹ wọn ṣi fi ọrọ itunu ranṣẹ si wọn lati gbogbo ibi ti wọn wa ti wọn ti n ṣe ọdun.
Alhaja Mercy Aigbe
Fun igba akọkọ, oṣerebinrin to jẹ ẹlẹsin Kristẹni tẹlẹ, Mercy Aigbe amọ to ti yipada si ẹsin Musulumi bayii tori igbeyawo rẹ si Alhaji Kazeem Adeoti naa ti wa de ayipada orukọ rẹ ati ẹsin lori bayii nipa lilọ si Hajj to n waye lọwọ yii ni Mecca ti orukọ rẹ lootọ si ti wa di Alhaja Minna (pẹlu H) gẹgẹ bo ṣe maa n pe ara rẹ.
Alhaja Mercy ni: “Eid Mubarak latọdọ Alhaji Kazeem Adeoti ati emi Alhaja tuntun.
Ọlọrun yoo jẹ ki gbogbo ẹbọ wa ati adura wa jẹ itẹwọgba gẹgẹ bi Ibadah”.
Mercy Aigbe to jẹ pe o tẹle ọkọ rẹ, Kazeem Adeoti lọ si ilu rẹ, Oro nipinlẹ Kwara fun ọdun to kọja ni oun ṣaaro ilu Oro lakoko ileya ti ọtẹ yii.
Idi eyi ni wipe oun ati ọkọ rẹ rinrinajo lọ si Hajj ti ọdun yii ibẹ si ni ọdun ileya ti ba wọn.
Femi Adebayo Salami
Ko si asiko ọdun ti gbajugbaja oṣere, Femi Adebayo ati ẹbi rẹ kii lọ si ilu Ilorin nipinlẹ Kwara lati lọ ba baba rẹ toun naa jẹ agba oṣere fiimu Yoruba, Adebayo Salami ti ọpọ eeyan mọ si Ọga Bello lati jọ ṣe ọdun Ileya.
Bakan naa ni awọn oṣere mii a maa dara pọ mọ wọn nibi ọdun naa.
Femi Adebayo fi ọpọ aworan sita to si kọ akọle sori rẹ pe: “ Idile ni ohun gbogbo”.
Bakan naa ni oṣere naa fi ikini ọdun rẹ ranṣẹ si gbogbo eniyan to si gbadura pe ẹmi yoo ṣe ọpọlọpọ ọdun.
Iyabo Ojo
Bo tilẹ jẹ pe ẹlẹsin Kristẹni ni gbajugbaja oṣere, Iyabo Ojo amọ oun gaan ko gbẹyin gẹgẹ bo ṣe fi ikini rẹ ranṣẹ si gbogbo mumini ati mumina.
“Barika de Sallah si gbogbo awọn arakunrin ati arabinrin wa to jẹ Musulumi, asiko yii yoo dara fun gbogbo wa”.
Iyabo Ojo naa n ṣe eyi gẹgẹ bi iyawo ile tuntun lọọdẹ ọkọ to ṣẹṣẹ fẹ to jẹ ẹya Igbo, Ọgbẹni Paulo.
Lateef Adedimeji ati Adebimpe Oyebade
Latọdọ tọkọ-taya gbajugbaja oṣere Lateef Adedimeji ati Bimpe Akintunde, fidio ikini ku ọdun ni wọn fi sita loju opo ọkọ ati iyawo ti wọn si fi akọle rẹ ki awọn ololufẹ wọn pe wọn ku ọdun bẹẹ ni wọn gbadura pe ki wọn ri iyọnu Allah ninu gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe.
Queen Salawa Abeni
Ni ti agba olorin Waka nni Queen Salawa Abeni, fidio diẹ lara waasi ati irun pipe to waye ni Yidi ni mama fi sita to si tun fi adura lee lori pe: Alihamidulilah, mo dupẹ pe mo wa laye lonii lati ri ayẹyẹ ọdun Eid el Kabir. Ogo ni fun Allah.
Adebimpe Akintunde
Ẹ ṣaa mọ pe iyawo aṣẹṣẹgbe ni gbajugbaja oṣere Adebimpe Akintunde ti ẹ mọ si Wasila Coded. Ko tii ju ọjọ melo kan lọ to ṣe igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ tuntun to jẹ Alafa torinaa lati ile ọdun pẹlu awọn eeyan ọkọ rẹ ni ikini rẹ ti wa to si tun pa atẹjade rẹ kan pọ mọ didupẹ lọwọ gbogbo awọn to wa ba oun ati ọkọ rẹ ṣe ajọyọ igbeyawo wọn.
“Ọdun Eid dun pẹlu idile Muhammad Rosululai. Ẹ ṣeun gan fun ifẹ ti ẹ fi han ati ikini ku oriire ti ẹ fi ranṣẹ. Ire ayọ ko ni wọn nile gbogbo wa”.
Wasila kede pe oun ti di iyawo Alfa bayii.
Cute Abiola
Gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Cute Abiola ni tirẹ tọrọ aforijin pe oun ko tete fi awọn aworan sita fun awọn ololufẹ rẹ tori o mọ pe wọn ti n reti rẹ.
“Ẹ ma binu o, Data mi lo tan tẹlẹ tori naa ni mo ṣe sare lọ ra oni N500 ki n baa le bukun oju opo yin.
“Ki Ọlọrun Ọba ṣilẹkun idunu fun yin ki o si mu ala yin ṣẹ. Eid Mubarak si ẹyin ati mọlẹbi yin”.