Instagram wọ́gilé ojú òpó 63,000 táwọn èèyàn fi ń lu jìbìtì ìbálòpọ̀ àti owó

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ Meta to ni Instagram ti kede pe oju opo ẹgbẹrun mẹtalelọgọta (63,000) lawọn ti fagile bayii, nitori jibiti ibalopọ ati ti owo ti awọn to ni wọn n fi wọn lu.

L’Ọjọru, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje ọdun 2024 ni ileeṣẹ Meta sọ eyi di mimọ ninu ikede wọn.

Meta ṣalaye pe awọn to n lo oju opo naa maa n lo fọto ẹtan, eyi ti yoo jẹ ti arẹwa obinrin.

Yatọ si eyi, awọn ẹlẹtan naa yoo kọkọ fi fọto ihoho tiwọn ranṣẹ si ẹni ti wọn ba fẹẹ lu ni jibiti tabi ba lorukọ jẹ.

Meta ṣalaye pe wọn yoo waa ni ki ẹni naa fi fọto ihoho tiẹ naa ṣọwọ sawọn.

Bi ẹni yii ba finu tan wọn to si fi fọto ihoho tiẹ naa ranṣẹ, wọn yoo bẹrẹ si i dunkooko mọ ọn.

Wọn yoo ni awọn yoo ju fọto naa soju opo ayelujara bi ko ba fi owo nla ranṣẹ.

Ibanilorukọjẹ ni wọn n lo awọn fọto mi-in fun bii Meta ṣe ṣalaye, eyi to ti mu awọn ẹlomi-in pa ara wọn nitori itiju.

Wọ́n wọ́gile ojú òpó Facebook 5,700 pẹ̀lú

Awọn alaṣẹ Meta to n dari Facebook tun ṣalaye pe oju opo Facebook ẹgbẹrun marun-un-le-ni ẹẹdẹgbẹrin (5,700) ni awọn tun gbẹsẹ le fun ẹsun kan naa.

Ẹkọ nipa bi wọn yoo ṣe lu eeyan ni jibiti owo nla loju opo yii ni awọn eeyan kan n kọ awọn mi-in lorii Facebook, bi Meta ṣe wi.

Awọn oju opo ti wọn fi n lu jibiti bayii ni Meta sọ pe awọn gbe ẹsẹ le, ti awọn to n lo wọn ko ni i le ṣi wọn mọ.

Awọn eeyan kan ti ni idaamu ọkan, itiju si ti mu ki awọn mi-in pa ara wọn nitori iwa ibanilorukọjẹ ti wọn koju lori ayelujara.

Ninu oṣu karun-un, ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Murray Dowey, pa ara rẹ nitori awọn ọdaran to n lepa ẹmi rẹ lori ayelujara.

Ninu oṣu karun-un kan naa, ikọ iroyin BBC ṣe alabapade iwe kan ti wọn fi n kọ awọn eeyan ni jibiti lilu lori ayelujara.

Ó kan àwọn ọmọ Yahoo náà

Nigba ti wọn n ṣalaye awọn eeyan ti ọrọ yii kan, Meta sọ pe ọwọ awọn ọmọ Yahoo lawọn ba ninu awọn akanti ẹtan naa.

’Yahoo Boys’ bi wọn ṣe pe wọn.

Meta sọ pe awọn Yahoo Boys yii lewu pupọ, orukọ wọn si ti wa lori iwe awọn eeyan ti wọn ko mọ ju jibiti lọ.

Ileeṣẹ mẹta sọ pe ọlọkan-o-jọkan imọ ẹrọ igbalode ni awọn lo lati mọ awọn oju opo to n fi ọrọ ifẹ lu jibiti ọhun.

Gẹgẹ bi ilana tuntun ti wọn kede loṣu kẹrin, Meta sọ pe bo ti wu ki akanti meji ti maa ba ara wọn ṣe to, awọn ko ni fi akede atẹjiṣẹ han loju opo awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹtala si mọkandinlogun.