Wo bí ìgbẹ́jọ́ ọkùnrin tó ní kí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yọ Tinubu nípò ṣe lọ l'Abuja

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti yi ẹjọ ti oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu HDP, Ambrose Owuru, pe wi pe ki ile ẹjọ naa yọ Aarẹ Bola Tinubu nipo danu.

Ọgbẹni Owuru pe ẹjọ wi pe Tinubu ko koju oṣuwọn lati jẹ aarẹ Naijiria tori ẹsun gbigbe oogun oloro ti wọn fi kan an lorilẹede Amẹrika.

Ile ẹjọ sọ pe ẹjọ ti ọkunrin pe ko lẹsẹ nlẹ.

Koda, ile ẹjọ to ga julọ tun sọ pe ki Ọgbẹni Owuru lọ san faini miliọnu marun un.

Adajọ Uwani Musa-Aji lo paṣẹ wi pe ki Owuru san owo yii.

Yatọ si sisan faini yii, ile ẹjọ tun paṣẹ fun ẹka ile ẹjọ to ga julọ to maa n gba ẹjọ silẹ wi pe ko gbọdọ gba ẹjọ kankan lọwọ Ọgbẹni Owuru mọ.

Nibi igbẹjọ ọhun, Owuru to ni ọdun 1984 ni oun di agbẹjọro ni Naijiria fẹ duro funra rẹ nile ẹjọ lati sọrọ gẹgẹ bi agbẹjọro.

Ọgbẹni Owuru wọ aṣọ awọn agbẹjọro, o si de fila tawọn amofin maa n de nile ẹjọ, ṣugbọn ile ẹjọ paṣẹ wi pe ki o jade ki o si lọ bọ aṣọ ati fila to wọ ki ile ẹjọ to le fun lanfaani lati duro funra rẹ nile ẹjọ.

Lẹyin to ṣe ohun ti ile ẹjọ sọ fun un ni wọn beere lọwọ rẹ wi pe ki lo tun n wa nile ẹjọ lẹyin ti ile ẹjọ ti yi ẹjọ to pe danu tẹlẹ ni igba mẹta ọtọtọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa rọ ile ẹjọ to ga julọ lati gbọ ẹbẹ rẹ, gbogbo atotonu rẹ ni wọn yi danu.

Koda, ijokoo awọn adajọ ile ẹjọ to ga julọ naa dunkoko lati fẹjọ rẹ sun ajọ LPDC to maa n bawọn agbẹjọro to ba tasẹ agẹrẹ wi.

Ẹjọ ti Ọgbẹni Owuru pe Tinubu ko lẹsẹ nlẹ - Ile ẹjọ

Adajọ Aba-Aji ni ihuwasi Owuru ko jọ ti agbẹjọro to ti n ṣiṣẹ fun bii ogoji ọdun gẹgẹ bi o ti sọ.

Ile ẹjọ koro si ọkunrin naa wi pe o kan fi akoko awọn ṣofo lasan lori ẹjọ ti ko lẹsẹ nlẹ to pe ni.

Ṣaaju igbẹjọ naa, amofin agba, Bode Olanipekun (SAN), to ṣoju Tinubu nile ẹjọ ti kọkọ pe akiyesi ijokoo ile ẹjọ naa si oniruuru ẹjọ ti Owuru ti pe tẹlẹ eyi ti ile ẹjọ ti yi danu.

Olanipekun sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹjọ ti Ọgbẹni Owuru ṣẹṣẹ pe Aarẹ Tinubu ko lẹsẹ nlẹ rara.

Ẹwẹ, ile ẹkọ kotẹmilọrun ti kọkọ paṣẹ pe ki Owuru san ogoji miliọnu naira fun Tinubu, ajọ INEC ati atawọn mii lori bi o ti pe wọn lẹjọ.

Ẹjọ ti Owuru pe da lori ẹsun pe Tinubu ko koju oṣuwọn lati di ipo aarẹ orilẹede Naijiria mu ati fifi ipa gba ipo aarẹ Naijiria eyi to lodi sofin.

Yatọ si Tinubu, awọn mii ti Ọgbẹni Owuru pe lẹjọ papọ ni aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Muhammadu Buhari, Agbẹjọro agba ni Naijiria ati ajọ eleto idibo INEC.

Ọgbẹni Owuru sọ pe ẹjọ toun pe tẹlẹ ko ba ti yọ Buhari nipo, amọ, o ni ile ẹjọ to ga julọ ni ko gbọ ẹjọ naa.

O tun sọ fun ilẹ ẹjọ wi pe ki o yọ Tinubu nipo nitori o san $460,000 fun orilẹede Amẹrika lori ẹsun to ni ṣe pẹlu gbigbe oogun oloro.

Ọgbẹni Owuru tun rọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lati kede oun gẹgẹ bi aarẹ lẹyin to ba yọ Tinubu nipo tan.

Lẹyin o rẹyin, ile ẹjọ to julọ ni Naijiria pada yi ẹjọ ti Ọgbẹni Owuru pe danu.