You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀rẹ́ Mojisola Awesu tí wọ́n bá òkú rẹ̀ lórí àkìtàn ní Ilorin sọ bí olóògbé ṣe rìnrìnàjò ìkẹyìn
L'Ọjọru, ọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun 2025, ni gọngọ sọ nile-ẹjọ giga kan to filuu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ṣe ibujokoo lori igbẹjọ iku Mojisola Awesu ti wọn ba lori akitan ni Ilorin lọjọ kẹsàn-án, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024.
Lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ ni DPP Idowu Ayọọla, to ṣoju fun ijọba ko awọn ẹlẹri wa lati wa jẹri tako awọn meje ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku Mojiṣọla Awesu.
Ẹlẹri akọkọ ni ASP Yusuf Dauda, to ṣe alaye fun ile-ẹjọ pe lọjọ kin-in-ni, osu kẹsan-an, ọdun 2024, ni insipẹkitọ Kamalud-deen, ko gbogbo awọn afurasi naa wa si ọdọ oun fun iforukọsilẹ lori awọn ẹsun ipaniyan, ṣiṣe bi ẹri ṣe poora, ṣiṣọ oku nu si akitan ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni o wa pẹlu Iphone 11 pro kan, IPhone kan, sokoto kekere, ẹwu polo kan, kaadi idanimọ fasiti Summit ti wọn kọ orukọ Adebayọ Joshua H si lara ti oun si kọ gbogbo rẹ kalẹ sinu iwe.
Gbogbo awọn ẹri naa ni o ko wa sile-ẹjọ.
Ẹlẹri keji, ni Ogungbenro Blessing, to n gbe ni niluu Ọffa, ni oun ṣẹṣẹ pari iwe nile-ẹkọ Health Technology n'ilu Ọffa ni, oun ati Mojiṣọla ni awọn jọ n gbe lagbegbe Gbọmi, awọn si jẹ ọrẹ kori-kosun.
O ni lọjọ kẹrin, osu Kẹjọ, ọdun 2024, ni oun àti Mojiṣọla jọ wa ninu ile, o si gba ipe lori ago, ti ẹni naa si n beere pe oun pẹlu ta lo wa ninu ile.
"Mojiṣọla si dahun pe oun pẹlu Blessing ni.
"Ẹni naa ni ko jade sita ka wọn le ṣọrọ dáadáa sugbọn mi o mọ ohun tí wọn sọ.
"Nigba ti Mojiṣọla wọle pada lo sọ pe Timilẹyin lo pe oun, o ni Timilẹyin sọ pe Adebayọ Happiness ni oun nilo ọbinrin ti yoo ṣe bii ọrẹbinrin oun nibi ayẹyẹ ikẹkọ pari eyi ti Fasiti Summit ati Fasiti Al-Hikmah fẹ ṣe papọ niluu Ilọrin.
"O ni Timilẹyin sọ pe ọla pe ọdọ ọrẹkunrin oun loun wa ni oun ko nile lọ.
Lẹyin eyi ni Happiness ati Mojiṣọla bẹrẹ si fi foto ara wọn ranṣẹ si ara wọn, Mojisọla si fi foto han mi pe ọmọ pasitọ Ogunṣẹ ni oun fẹẹ lọ ba.
"Ni irọlẹ ọjọ naa, Mojiṣọla mura pe oun fẹ maa lọ, mo ni ma maa pe e, ki oun naa maa pe mi.
"Nigba to lọ tan, mo pe e, o si ni oun ti de ilu Ajaṣẹ, mo si ni to ba de ọhun ko pe mi, o si pe mi pe oun ti de ọdọ Happiness.
"Nigba to di nnkan bii aago mejila oru kọja diẹ, o fi atẹjiṣẹ ranṣẹ pe nibi toun wa, ara oun ko balẹ, o ni otẹẹli aye atijọ ni o gbe oun lọ.
"Mojiṣọla ni Happiness n fa igbo to si n pariwo pe ko jẹ ki ara oun balẹ rara, sugbọn oun yoo farada iṣoro naa di aago marun-un idaji ti oun yoo si maa lọ si ọdọ ọrẹ oun kan, pe toun ba si fẹẹ kuro oun yoo pe ki oun to lọ.
"Sugbọn mo pẹ ji laarọ ọjọ kejì, mi o ri ipe rẹ ni mo fi wa pe aago rẹ, ko lọ (line) bisi lo n sọ ti ilẹ ọjọ naa fi su. Ni ọjọ keji ni Timilẹyin, pe mi pe ṣe mo ti ri Mojiṣọla, mo si ni mi o ri o.
"Mo tun nọmba Mojiṣọla pe, ko tun lọ, mo wa ni ki Timilẹyin pe Happiness nigba to jẹ pe ọdọ rẹ lo lọ, sugbọn Happiness ni Mojiṣọla ti kuro lọdọ oun, oun wa nọmba ọrẹ rẹ to ni oun fẹẹ lọ, mo lọ wo nọmba lori tiktok iyẹn naa sọ pe ko wa sọdọ oun.
Lẹyin eyi ni mo mu ẹsun lọ si ileeṣẹ ọlọpaa, ni ọjọ kẹrin ọjọ naa ni awọn Ọlọpaa sọ pe ṣe mo da Mojiṣọla mọ, wọ́n fi aworan oku ẹ han mi, mo si daku.
Adajọ Ibrahim Yusuf, ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2025 , gẹgẹ bii ọjọ ti igbẹjọ yoo tẹ siwaju.
Bawo ni Mojisola ṣe di awati?
Ọlọpaa sọ ninu atẹjade naa pe ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ni wọn fi to ileeṣẹ naa leti pe oloogbe ọhun di ẹni ti wọn n wa.
O ni "Lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, ni nnkan bii aago mẹrin abọ irọlẹ, omidan kan, Blesson O, to n gbe lagbegbe Gbomi, niluu Offa, nipinlẹ Kwara sọ fun wa pe alabagbe oun ninu yara kan naa, Omidan Mojisola Awesu, ẹni ọdun mọkanlelogun to jẹ akẹkọọ Kwara State College of Health Technology, ti di awati lati ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹjọ.
"Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Mojisola gba ipe lati ọdọ Omidan kan ti orukọ rẹ n jẹTimileyin, to ni ko yọju sibi ode ariya kan ti yoo waye ni fasiti Summit ati Al-HikmaH, niluu Ilorin.
"Omidan Timileyin fa Mojisola le Ọgbẹni kan to n jẹ Adebayo Happiness lọwọ, to jẹ akẹkọọ fasiti Summit, ti Adebayo si ni ko ba oun lọ ode ariya nibi ti yoo ti dibọn gẹgẹ bii ọrẹbinrin oun ti oun yo si fun ni ẹgbẹrun marundinlogun naira."
Ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti oloogbe ọhun yoo de ibẹ, o pe alabagbe rẹ pe ile itura ti Adebayo Happiness fi oun si ko tẹ oun lọrun ati pe ko si ayẹyẹ kankan to n waye nibẹ.
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, lẹyin to fi ọrọ naa ranṣe si alabage rẹ tan ni ẹrọ ilewọ rẹ ku ti ko si si aaye lati kan si mọ.
Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye siwaju si pe awọn ti tare ọrọ naa lọ si ẹka CID fun iwadii ni kikun.
Kọmiṣọna ọlọpaa, CP Victor Olaiya si ti ṣeleri lati tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.