Kí ló wà nínú orin tí Eedris Abdulkareem fi rán Seyi Tinubu sí bàbá rẹ̀ tí NBC fi gbẹ́sẹ̀ lé e?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n mojuto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, National Broadcasting Commission (NBC), ti fofin de awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ - redio ati tẹlifisan – pe wọn ko gbọdọ gbe orin "Tell Your Papa", ti ogbatarigi akọrin takasufe, Eedris Abdulkareem, gbe sita lori afẹfẹ.

Ajọ NBC sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹrin pe, orin naa ni awọn ọrọ to tọka abuku si ẹnikan.

Orin naa ti akọle rẹ tumọ si "Sọ fun baba rẹ" ni ede Yoruba, ni NBC sọ pe o tapa si abala ofin 3.1.8, to nii ṣe pẹlu igbohunsafẹfẹ.

Abala ofin naa lo n mojuto gbigbe orin tabi aworan ti ko 'bojumu, tabuku tabi tako igbeaye awujọ' jade lori afẹfẹ.

Ninu atẹjade ọhun, oludari ẹka to n tọpinpin awọn nnkan to n jade si ori afẹfẹ, Susan Obi, sọ pe botilẹ jẹ pe orin naa ti tan kaakiri ori ayelujara, sibẹsibẹ, awọn ọrọ inu rẹ ko ba ilana iṣẹ igbohunsafẹfẹ to ni laari mu.

Ki lo wa ninu orin "Tell Your Papa"?

Ninu orin to n da ariyanjiyan silẹ ọhun, eyi ti Eedris Abdulkareem gbe sita ninu ọsẹ yii, lo ti n pe orukọ Seyi Tinubu, ọmọ Aarẹ Bola Tinubu, wi pe ko ba baba rẹ sọrọ lori ọrọ aje ati igbeaye to nira fun awọn ọmọ Naijiria.

Ninu orin naa to fi sita lọjọ aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, Abdulkareem ṣapejuwe inira ti awọn ọmọ Naijiria n koju lojoojumọ.

Orin naa jade lẹyin ọsẹ diẹ ti Seyi Tinubu rinrinajo lọ si awọn ipinlẹ kan ni Ariwa Naijiria, nibi to ti pin ounjẹ ati awọn nnkan miran.

Ninu ọkan lara awọn irinajo naa si ipinlẹ Adamawa, ni Seyi Tinubu ti gboriyin fun baba rẹ, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi "aarẹ to ti i dara julọ ninu itan Naijiria".

Ninu ọrọ orin naa, Abdulkareem sọ pe ki Seyi sọ fun baba rẹ pe "ilu le".

"Sọ fun baba rẹ pe, awọn eeyan n ku. Sọ fun baba rẹ pe, eleyi kọja jagajaga."

"Seyi, bawo ni? Wo, mo le bura pe, baba rẹ ko ṣe daadaa rara. Ileri ofo ti pọ ju. Gba ẹnu awọn ọmọ Naijiria sọrọ, ko fi iṣẹ wa jẹ fun pe, awọn ajinigbe n pa awọn ọmọ Naijiria."

"Seyi, rinrirnajo loju popo lai ko awọn ẹṣọ rẹ dani, ki wọn naa le ri imọlara inira ti awọn ọmọ Naijiria bi ti ẹ n koju. Ọkọ ofurufu aladani lo fi n rinrinajo, eto aabo to mẹhẹ kii ṣe iṣoro rẹ."

Diẹ lara awọn ọrọ orin ọhun re e.

Taa ni Eedris Abdulkareem?

Oduu ti kii ṣe aimọ fun oloko ni Eedris Abdulkareem, lagbo orin kikọ ni Naijiria.

Abdulkareem gbajumọ fun kikọ awọn orin to nii ṣe pẹlu eto oṣelu, igbeaye awujọ ati aṣa, ni Naijiria.

Ọdun 1974 ni wọn bi Eedris Turayo Abdulkareem Ajenifuja.

Gẹgẹ bi akọrin takasufee, o darapọ mọ ẹgbẹ akọrin The Remedies laarin ọdun 1997 si 2002 ti ipinya de si aarin wọn.

Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni i da kọrin. Lara awọn orin to kọ lọdun 2002 ni Mr. Lecturer, eyi to fi koro oju si iwa bi awọn olukọ ile-ẹkọ giga ṣe ma n beere fun ibalopọ lọwọ awọn akẹkọọ lati fun wọn ni maaki.

Igba akọkọ kọ ree ti Eedris Abdulkareem wọ wahala ijọba nitori orin kikọ

Lọdun 2004, Abdulkareem gbe orin kan to pe akọle rẹ ni "Jagajaga". Ninu orin naa lo ti bu ẹnu atẹ lu iwa ibajẹ to wa ninu iṣejọba Aarẹ Olusegun Obasanjo to wa ni iṣakoso lasiko naa. O tun mẹnuba inira ti awọn ọmọ Naijiria n koju.

Orin naa bi Obasanjo ninu debii pe, o fi ofin de e lori redio ati tẹlifisan.

Wahala naa le titi ti Eedris Abdulkareem fi sa kuro niluu, to si lọ ṣe atipo ni orilẹede Ghana fun ọdun diẹ ko to o tun pada si Naijiria.

Eyi ko da Abdulkareem duro. Lọdun 20025, o tun gbe orin miran sita to pe akọle rẹ ni "Letter to Mr President".

Ninu orin tuntun naa lo tun ti sọrọ si Aarẹ Obasanjo, lori ọrọ iwa ibajẹ to pọ ninu iṣejọba Naijiria.