You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni Jonathan sọ nípa Buhari àti Boko Haram tó di ariwo?
Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Ebele Jonathan, ti ṣalaye kikun nipa ọrọ to sọ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ọdun 2025, lori Oloogbe Muhammadu Buhari ati ikọ Boko Haram.
Ọjọ naa ni iroyin kan gbode, pe Jonathan sọ pe oun ro pe Buhari yoo ṣẹgun Boko Haram pẹlu bi ikọ naa ṣe yan an gẹgẹ bii alagbawi fun ijọba Naijiria ni.
Ati pe oun ko mọ pe rogbodiyan ikọ apaayan naa yoo di asiko yii.
Ilu Abuja, nibi ifilọle iwe kan "Scars: Nigeria's Journey and the Boko Haram Conundrum", ti ọga ologun Naijiria nigba kan, General Lucky Irabor, kọ ni a gbọ pe Jonathan ti sọrọ naa.
Lẹyin ọrọ yii ni agbenusọ Buhari lasiko ijọba rẹ, Garba Shehu, sọ pe ki Jonathan yee sọ ohun ti ko ri bẹẹ nipa Oloogbe Muhammadu Buhari.
Lojuo po X rẹ, Garba Sheu sọ pe ki Jonathan dẹkun lilo orukọ Oloogbe Buhari lati wa ipo aarẹ to tun fẹ pada si ni 2027.
Agbẹnusọ Buhari naa sọ pe Muhammad Yusuf tabi Abubakar Shekau, ti wọn jẹ olori Boko Haram nigba naa ko figba kankan pe
Buhari lati ṣoju wọn lọdọ ijọba Naijiria.
Àlàyé Jonathan
Lati fọ ohun ti Jonathan sọ lọjọ Ẹti to di aroye yii si wẹwẹ, Olugbani-nimọran pataki rẹ,Ikechukwu Eze, fi atẹjade alaye kan sita lọjọ Satide, ọjọ kẹrin oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Ninu atẹjade naa ni Goodluck Jonathan ti ṣalaye pe wọn ṣi oun gbọ ni.
"A fẹ ko ye wa yeke pe itumọ mi-in ni wọn fun ohun ti Aarẹ tẹlẹ sọ. "Ko si igba kan ti Ọmọwe Jonathan sọ pe aarẹ tẹlẹ, Buhari, ni nnkan kan pẹlu awọn Boko Haram,tabi ṣe atilẹyin kankan fun wọn.
"Ọrọ ti Ọmọwe Jonathan sọ wa fun lati ṣalaye ọna arekereke ti awọn Boko Haram ti n tọ lati ibẹrẹ aye wọn.
"Koko ti Ọmọwe Jonathan fẹ fi alaye rẹ ṣe nipa Boko Haram ni pe ẹlẹtan ni wọn, wọn si maa n saba lo orukọ awọn eeyan nla lati da rugudu silẹ, ki wọn fi gba agbara oṣelu, ki wọn si jẹ kawọn araalu ma ṣe nigbagbọ ninu ijọba.
"Ohun ti Jonathan sọ ni pe to ba jẹ pe loootọ ni Buhari jẹ aayo awọn Boko Haram, to le ba wọn dunaa-dura, ki lo de ti wọn ko dẹkun iwa ika ọwọ wọn nigba ti Buhari di aarẹ?"
Atẹjade naa fi kun un pe Jonathan paapaa mọ, pe Buhari duro tan lati ṣẹgun Boko Haram lasiko ijọba rẹ, ati pe asiko kan wa ti ikọ naa dọdẹ Buhari funra rẹ gan-an lati mu un.
Wọn fi kun un pe bi Jonathan ṣe fẹ ki Boko Haram dopin ni Buhari naa sapa rẹ lati jẹ ki alaafia jọba ni Naijiria.
"Ọfiisi aarẹ Naijiria tẹlẹ yii rọ gbogbo eeyan lati ma ṣe gba aṣigbọ ọrọ to n lọ lode yii gbọ.
"Ọmọwe Jonathan duro lori alaafia, iṣọkan ati iduro ṣinṣin ijọba awaarawa ni Naijiria.
"Igbagbọ rẹ ni pe ilọsiwaju orilẹede yii da lori ṣiṣẹ ododo nipa idojukọ rẹ, ki i ṣe lati maa gbe ahesọ ọrọ kiri nitori oṣelu lasan"
Bẹẹ ni atẹjade Jonathan ṣalaye.