You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Ọmọ mẹ́rin ni mo kó lọ sí àpèje Ibadan, mẹ́ta ló bá mi wálé"
Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ lẹyin iṣẹlẹ apeje to gba ẹmi ọpọ ewe niluu Ibadan, awọn obi ti ọrọ naa kan ti n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ si wọn.
Ọkan lara awọn obi to ṣalaye ọrọ fun BBC nipa ayẹyẹ Olori Naomi Silekunola ni ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Musiliu.
Musiliu sọ fun BBC pe iyawo oun lo ko awọn ọmọ awọn mẹrin lọ sibi apeje to waye l'Ọjọruu, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024 naa.
''Aago marun-un idaji ni iyawo mi kuro nile pẹlu awọn ọmọ wa mẹrin, wọn lọ sibi apeje naa to fẹẹ waye nileewe Islamic High School, Basorun, Ibadan.
''Igba to di aago meje aabọ aarọ lo pe mi lori foonu, pe Sofia, ọmọ wa to jẹ ọmọ ọdun mẹwaa ti daku.
''Iyawo mi sọ pe wọn ti gbe e lọ sile iwosan, lemi naa ba sare gba ibi ayẹyẹ naa lọ.
''Ọjọ keji ni wọn pe mi lati ọsibitu, pe Sofia ti ku. Ọjọbọ yẹn naa la sinku rẹ, a ti gba fun Allag gẹgẹ bii Musulumi''
Obi miran to tun padanu ọmọ kan ninu mẹta to ko lọ sibi apeje naa ni Arabinrin Mariam Salawu.
Ọmọ mẹrin lo ni oun naa ko lọ sibi apeje Naomi, ṣugbọn ọkan ninu wọn, Ayomide; ọmọ ọdun mẹfa, di oku nibi ti wọn ti tẹ ẹ pa.
Báwo ni àtẹ̀pa ṣe bẹ̀rẹ̀ gan-an?
Arabinrin Mariam Salawu ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, sọ bo ṣe ṣẹlẹ fun BBC.
''Ero pọ gan-an to wa sibi eto naa, ọpọ eeyan ni wọn ko raye wọle.
''Awọn to tete de raye wọle, ṣugbọn ọpọ eeyan to de lẹyin igba naa ni wọn ko jẹ ki wọn wọle mọ.
" Nigba ti Oriyomi Hamzat to ni ileeṣẹ redio Agidigbo FM, de, o ṣilẹkun lati wọle.
''Anfaani naa ni awọn to wa nita lo, ti wọn bẹrẹ si i ti ara wọn bi wọn ṣe n rọ wọlẹ, nigba naa ni atẹpa yii bẹrẹ.
''Awọn to fipa wọle lo da wahala naa silẹ. Ka ni wọn ṣilẹkun fawọn to ti debẹ laaago marun-un lati wọle ni, ọmọ kankan ko ba ma ku.
"Aago mẹfa aarọ ko ti i lu ti Oriyomi naa fi de, ẹṣọ oju ọna ko ṣilẹkun fun un, Oriyomi ja kọkọrọ naa gba lọwọ ẹ, o si ṣilẹkun wọle.
''Nigba to ṣilẹkun naa ni awọn eeyan bẹrẹ si i tira wọn wọle, ti wọn si n ṣubu leri ara wọn, Oriyomi naa waa bẹrẹ si i ran wọn lọwọ.
''Nigba ti mo maa fi ri ọmọ mi, wọn ti tẹ ẹ mọlẹ pa, o ti ṣegbọnsẹ sara, o si ti ku.''
Mariam Salawu lo ṣalaye bẹẹ.
Àwọn wo ni ọlọ́pàá kó sí áhámọ́ lórí íṣẹ̀lẹ̀ yìí?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣalaye l'Ọjọbọ, pe awọn ti fi ofin gbe olori tẹlẹ, Naomi Silekunola Ogunwusi ati awọn ti wọn jọ gbe eto naa kalẹ.
Ninu atẹjade ọlọpaa ni wọn ti sọ pe ọmọ marundinlogoji (35) lo ku ninu ajalu naa.
Ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ pe awọn ọmọ mẹfa lo tun n gbatọju lọwọ.
Yatọ si Naomi to ṣagbatẹru eto naa, awọn ọlọpaa ṣalaye pe awọn ti mu ọga ileewe ti eto ọhun ti fẹẹ waye naa.
Wọn fi kun un pe awọn ti taari ẹjọ yii si ẹka to n ri si ipaniyan nipinlẹ Oyo, eyi to wa ni Iyaganku.