Èsì tí Mínísítà tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ fọ̀ rèé lẹ́yìn tí fọ́nrán fídíò ibi tó ti gba owó lọ́wọ́ oníṣòwò ọmọ China lu síta

Minisita ilẹ okere lorileede Zambia Stanley Kakubo ti kọwe fipo silẹ lẹyin ti fọnran fidio kan lu sita nibi to ti n gba owo lọwọ oniṣowo ọmọ orileede China kan.

Stanley Kakubo ko sọ pe oun kọ lo wa ninu fidio naa. Kaka bẹẹ, o sọ pe ''wọn fi ẹsun ibanilorukọ jẹ kan oun ni lori idunadura owo''

O sọ pe oun kọwe fipo silẹ ki ijọba baa le kọju mọ iṣẹ to yẹ dipo awuyewuye ọrọ to wa nilẹ.

Ninu fidio taa n wi yi, wọn ṣafihan awọn ọkunrin meji kan ti wọn joko kọju si ara awọn ti wọn si n ka owo dọla ati woo ilẹ Zambia Kwacha ti wọn ko kalẹ.

A ko ribi ri oju wọn daada ṣugbọn fọnran yii dagboro ru loju opo ayelujara tawọn eeyan si n sọ pe o dabi ẹni pe arakunrin Kakubo ati oniṣowo ọmọ orileede China kan lo wa ninu rẹ.

Awọn eeyan kan bẹrẹ si ni beere pe kilo de ti wọn ko ṣe fi owo naa ranṣẹ sinu aṣunwọn wọn ati pe ṣe wọn si san owo ori to yẹ lẹyin igba naa.

Bakan naa lawọn eeyan bẹrẹ si ni ri aworan awọn iwe kan taa le fidi rẹ mulẹ loju opo ayelujara.

Ninu rẹ la ri eleyi to sọ pe wọn ṣe paṣiparọ ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla laarin oniṣowo ọmọ Zambia kan ati ileeṣẹ iwakusa orileede China kan.

A tun ri iwe mii to ṣe pe ọjọ ti wọn kọ sori rẹ jẹ ọjọ Kẹjọ oṣu Keje ọdun 2022 ti wọn si sọrọ nipa apapọ owo to jẹ ẹgbẹrun lọna igba dọla.

Ninu iwe to kọ lati fi iṣẹ silẹ arakunrin Kakubo ko jiyan nipa fọnran fidio tabi awọn iwe ti wọn buwọlu yii.

Kaka bẹẹ, o sọ pe ''wọn fẹ ba oun lorukọ jẹ ni lori idunadura laarin ileeṣẹ aladani mọlẹbi rẹ ati oniṣowo tawọn ṣi jijọ ni ibaṣepọ to mọranyin''

O sọ pe oun kọwe fiposilẹ ''ki ijọba baa le gbajumọ ilakaka rẹ lati mu igbe aye to dẹrun ba awọn ọmọ orileede Zambia'' ṣugbọn oun yoo si jẹ ọmọ ile aṣofin.

''Nigba to ba ya, a o pese ẹkunrẹrẹ alaye lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ to waye laipẹ yi''

Bẹẹ ni ileeṣẹ iwe iroyin Lusaka Times ṣe jabọ.

Igba akọkọ kọ ni yi ti awuyewuye yoo waye lori Minisita naa

Aarẹ Hichilema tẹwọ gba iwe ifiposilẹ ti o fi ranṣẹ to si loun mọ riri ipa ribi ati ipo aṣaaju ti Ọgbẹni Kakubo dimu.

Igba keji ree ti ọrọ yoo da lori alabahun Ọgbẹni Kakubo.

Lọdun to kọja wọn fẹsun kan wi pe o gba abẹtẹlẹ lẹyin ti wọn ri to jade ninu ọfisi ileeṣẹ simẹnti ilẹ China kan pẹlu apamọwọ.

O tako ẹsun yi ti aarẹ si gbelẹyin rẹ nipa sisọ pe iwe kalẹnda lo gba kuro nibẹ.

Awọn ileeṣẹ China jẹ oniṣowo pataki ni Zambia.

Ileeṣẹ aṣoju China ni Zambia sọ pe lọdun 2022 o le ni ẹgbẹta oniṣowo China to doko owo pẹlu owo to le biliọnu mẹta dọla ni Zambia

Ọgbẹni Kakubo ni minisita akọkọ ti yoo kọwe fipo silẹ lati igba ti aarẹ Hakainde Hichilema dori oye loṣu Kẹjọ ọdun 2021.

Lara ipinnu to ṣe ni pe oun yoo koju ajẹbanu ṣugbn awọn alatako a maa naka aleebu si pe awọn alatako lo n doju le.

O ni ẹsun yi ko ri bẹẹ.

Ninu esi tirẹ si ikọwefiposilẹ Kakubo, aarẹ tẹlẹ Edgar Lungu sọ pe o yẹ ki wọn ṣewadii rẹ lori ẹsun ajẹbanu.

''Kii ṣe pe mo ni Kakubo jẹbi.Ohun ti mo n sọ ni pe ti ki ba ṣe pe aarẹ n fọwọ bo awọn kan mọlẹ nijọba rẹ, o yẹ ki wọn ṣe iwadii Kakubo ti o ba si di dandan, ki wọn gbe lọ sile ẹjọ''