You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iṣẹ́ dẹndẹ ló kù ní ṣíṣe lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dámiláre - Adeleke
Gomina ipinlẹ Osun, Sẹnetọ ademola Adeleke, ti sọ pe ipe si iṣẹ ni bi ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, ṣe dajọ pe oun ni ojulowo gomina ti ilu dibo yan ninu idibo gomina ipinlẹ Osun, lọdun 2022.
Ọjọ Iṣẹgun ni idajọ naa waye niluu Abuja.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ, nile rẹ to wa niluu Ede, nipinlẹ Osun, Gomina Adeleke sọ pe Ọlọrun lo gba ẹri oun jẹ nile ẹjọ, pe ibo to jẹ otitọ ni wọn di fun oun.
Adeleke ni oun gboriyin fun awọn adajọ to da ẹjọ naa, nitori pe wọn ko ṣe magomago.
“Ipinlẹ Osun ti di awokọṣe rere pe idajọ ododo ṣi wa ni Naijiria.”
O ni bi ile ẹjọ ṣe fi ẹsẹ ijọba oun mulẹ jẹ ipe fun iṣẹ ati fifun araalu ni ere ijọba awaarawa.
“Mo fi ara mi ji fun iṣejọba rere to gbooro. Ma a si jẹ gomina to ni ifẹ araalu lọkan.”
Adeleke padà la Oyetola mọ́lẹ̀ nílé ẹjọ́! Àwọ́n ẹ̀sùn Oyetola tí ilé ẹjọ́ yí dànù rèé
Ile ẹjọ giga julọ to wa ni ilu Abuja ti kede wipe Ademola Adeleke ni ojulowo gomina ipinlẹ Osun.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ lati ile ẹjọ to ga julọ nilu Abuja, gbogbo ẹjọ ti wọn da lo gbe ọwọ gomina Ademola Adeleke soke pe oun lo jawe oluborigẹ́gẹ́ bii gomina ipinlẹ Osun.
Ki ni awọn aridaju ti adajọ gbe jade?
- Ilé ẹjọ́ tí ni ẹsùn tí wọ́n fi kan Gómìnà Ademola Adeleke nípa lílo ayédèrú ìwé ẹ̀rí kò fẹsè múlẹ̀.
- Ilé ẹjọ́ tún ní àwọn ẹlẹrìí tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló nílé ẹjọ́ nípa pé wọ́n ṣe àlùmọ̀kọ́rọ́yí ìbò (Over voting), kò yege láti jẹrìí.
- Bakan naa, Ilé ẹjọ́ tún faramo ìdájọ tí ilé ẹjọ kòtẹ́milọ́rùn dá, láti yí ohun ti ìgbìmọ̀ tó ń rí sí awuyewuye nípa ètò ìdìbò(election Tribunal) gómìnà ti wọ́n dá ní Òsogbo nù.
- Ilé ẹjọ́ tún ní àhesọ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni pé,màgò-mágó wà nínú ìdìbò gómìnà tí wọ́n di.kò sí ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Ilé ẹjọ́ kún fọ́fọ́ l'Abuja láti mọ ta ni yóò borí láàrín Adeleke àti Oyetola
Bi igbẹjọ yoo ṣe bẹrẹ lori abajade idibo to gbe gomina Ademola Adeleke wọle ni ipinlẹ Osun, BBC Yoruba ti wà ní ilé ẹjọ́ gíga jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (Supreme court) nílùú Abuja.
Níbi ni ìdájọ lórí ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun wáyé làárín Ademola Adeleke àti Adegboyega Oyetola yóò ti waye.
Gbogbo inu ile ẹjọ naa ti kun fọfọ bayi bẹẹ si ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP naa ti wa nikalẹ.
Òní lòní ń jẹ́! Ìdájọ́ lórí ẹní tó jáwé olúborí láàrín Adeleke àti Oyetola yóò wáyé lónìí
Lónìí, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Karùn-ún ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn Supreme Court yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí awuyewuye tó ń wáyé lórí ipò gómìnà Osun.
Ìgbìmọ̀ Adájọ́ ẹlẹ́ni márùn-ún èyí tí Adájọ́ John Okoro ṣáájú rẹ̀ mú òní láti fi ṣe ìdájọ́ náà lẹ́yìn tí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ti fi atótónu wọn ránṣẹ́.
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, All Progressive Party, APC ló ń tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Abuja èyí tó ní Ademola Adeleke gangan ni ojúlówó gómìnà tí àwọn ènìyàn dì ò yàn.
Ile ẹjọ giga to wa nilu Abuja yoo si gbe idajọ kalẹ lori igbẹjọ idibo laarin Gboyega Oyetola egbe òṣèlú All Progressives Congress (APC) ati Ademola Adeleke ti ẹgbẹ Peoples Democratic Party(PDP).
Idajọ yi jẹ eleyi ti awọn ara ilu ati ọpọ awọn ọmọ Naijiria n reti tọkan tọkan.
Oyetola n beere lọwọ ile ẹjọ to ga julọ pe ki ile ẹjọ fi ọwọ rọ idajọ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ ṣaaju.
Ile ẹjọ to ga julọ yoo sọ ni pato ibi ti ọrọ ẹni ti yoo dari ipinlẹ naa yoo ja si.
Adeleke ni ile ẹjọ kede pe o jaweolubori ninu idibo to waye loṣu Kẹjọ ọdun 2022.
Ẹgbẹ oṣelu APC ni ki ile ẹjọ to ga julọ da ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn nù, kí wọ́n sì gba ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò, èyí tó ní Oyetola ló jáwé ètò ìdìbò tó wáyé ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022.
Ṣáájú ni ilé Kòtẹ́milọ́rùn èyí tí Adájọ́ Mohammed Shuaibu ṣáájú rẹ̀ ní ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Osun kò lẹ́tọ̀ọ́ láti yí èsì ìbò padà.
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní kò yẹ kí ìgbìmọ̀ náà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn pé ìbò dídì kọjá iye tó jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láì tẹ̀lé ẹ̀rọ BVAS àti àkọ́ọ́lẹ̀ ìwé tí orúkọ àwọn olùdìbò wà.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Osun nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ pé Oyetola ni ẹni tó jáwé olúborí ìbò náà ní àjọ elétò ìdìbò kò tẹ̀lé òfin lórí ètò ìdìbò ọ̀hún.
Bawo ni ọrọ ṣe bẹrẹ?
Idibo si ipo gomina nipinlẹ Ọṣun waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2022. Lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keje ọdun 2022 ni ajọ INEC kede Ademọla Adeleke to dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi gomina ati olubori ibo naa.
Adeleke moke ni ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ninu ijọba ibilẹ Ọgbọn to wa ni ipinlẹ naa.
Gboyega Oyetọla to jẹ oludije APC moke ni ijọba ibilẹ mẹtala.
Lapapọ, Adeleke ko ibo ẹgbẹrun mẹtalenirinwo ati ọọdunrin o le aadọrin ati ẹyọkan (403,371), Oyetọla si ko ibo ẹgbẹrun lọna ọọdun o le marundinlaadọrin ati mẹtadinlọgbọn (375, 027)
Ile ẹjọ to gbọ awuyewuye idibo kede Oyetọla gẹgẹ bi gomina dipo Adeleke
Lẹyin ikede esi idibo ni Oyetọla gba ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo gomina nipinlẹ Ọṣun lọ lati tako esi ibo ti ajọ INEC kede.
Lọjọ karun oṣu kẹjọ ọdun 2022 ni Oyetola gba ile ẹjọ lọ nilu Osogbo lati wọgile esi to kede Adeleke gẹgẹ bi olubori ibo naa.
O ni ọpọ kotọ lo waye lasiko ibo ọhun ati pe Adeleke ko lẹtọ lati dije nitori “ayederu iwe ẹri lo fi dije”.
Bakan naa lo rọ ile ẹjọ naa pe ko kede oun gẹgẹ bi ẹni gan an ti ilu dibo yan ni ipinlẹ Ọṣun.
Adeleke naa ko igbimọ agbẹjọro mejilelaadọta jọ lati gbẹjọ rẹ ro, Oyetọla ṣa aadọta agbẹjọro jọ lati gbọ ẹjọ tirẹ.
Lẹyin ọpọ atotonu ati awijare, igbimọ adajọ mẹta ile ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ igbimọ ọhun.
Labẹ idari onidajọ, Tetse Kume pari igbẹjọ lọjọ kẹtala oṣu kini ọdun 2023 ki o to fi idajọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kini kan naa.
Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ to gbọ awuyewuye esi ibo gomina nipinlẹ Ọṣun naa wọgile esi ibo to gbe Adeleke wọle gẹgẹ bii gomina.
Ile ẹjọ naa ni INEC ko tẹle iwe ofin Naijiria ati iwe ofin eto idibo Naijiria.
Adeleke naa gba ile ẹjọ Kotẹmilọrun lọ
Idajọ ti igbimọ to n gbẹjọ esi idibo yi gbe kalẹ ko tẹ Adeleke lọrun.
Ọrọ pọ ṣugbọn ni ṣoki, o gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ ni Abuja to si mu idajọ pe o jare pada bọ.
Idajọ yi sọ pe oun ni ẹni to jaweolubori ati pe atotonu ti awọn agbẹjọro Oyeleke gbe wa ni paapa lori awọn aaye kan ti wọn ti di kọja dedee ibo to yẹ ko fẹsẹ mulẹ rara.
Fun idi eyi adajọ ni Adeleke ni ẹni to jaweolubori.
Kete ti ile ẹjọ kotẹmilọrun kede pe Ademola Adeleke lo jaweolubori ni awọn abẹṣinkawọ Oyetola ti sọ pe idajọ yi ko yanrantin.
Eleyi lo mu ki wọn morile ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria.
Saaju asiko yi,ni oṣu kini ni igbimọ to n gbọ ẹjọ lori awuyewuye esi idibo kede pe Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola lo bori ibo.
Tijo tayọ lawọn alatilẹyin rẹ fi gba esi yi amọ ko pẹ pupọ ki ile ẹjọ kotẹmilọrun to sọ fọwọ rọ idajọ yi sẹgbẹ kan to si ni Adeleke lẹni to jaweolubori.
Amọ nilẹ oni to mọ,ati Adeleke ati Oyetola,awọn mejeeji yoo maa reti ibi ti ọpa ẹbiti yoo resi nipa idajọ ile ẹjọ to ga julọ.
Lẹyin idajọ yi, ko si anfaani mọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun kankan lati ọdọ ẹnikẹni to ba fidirẹmi.
Bi Adeleke ba fi le wọle yoo lanfaani lati pari saa ọlọdun mẹrin rẹ akọkọ.
Ayafi ti ẹgbẹ oṣelu APC ba gbe Oyetola kalẹ ninu idibo mii ni wọn yoo tun lanfaani lati koju ara wọn.
BBC Yoruba yoo maa mu bi nkan ba ṣe n lọ tọ yin wa lori idajọ to lamilaaka yi.