Mo pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipa tó yẹ kí n kó nínú fíìmù nítorí àwọn kan sọ pe mo burẹ́wà – Funke Akindele

Gbajugbaja oṣere tiata ati oludari ere agbelewo, Funke Akindele ti ṣalaye bo ṣe padanu ọpọlọpọ ipa to yẹ ki o ko ninu fiimu nitori bi awọn eeyan ṣe sọ pe o burẹwa.

Akindele lo sọ ọrọ naa ninu ifọrwerọ kan, eyii ti Toke Makinwa ṣe atọkun rẹ.

O ṣalaye pe oun padanu awọn ipa pataki ninu awọn fiimu agbelewo ti ede Yoruba nitori bi oun se ri ni gba naa.

Akindele fi kun pe oṣerebirin Iyabo Ojo lo ṣe iranlọwọ fun oun lakoko ti awọn oludari ere ba ja oun kulẹ lasiko ti wọn ba n pe awọn oṣere tiata miran, ti wọn si kọ oun silẹ nitori pe oun ko rẹwa.

Oludari fiimu ‘Jenifa Diary’ naa sọ siwaju si pe awọn atọkun maa n fun oun ni awọn ipa kekeke, eyii to maa n gba omi loju oun.

Funkẹ Akindele gba awọn ọjẹ wẹwẹ nidi isẹ tiata nimọran pe ki wọn maṣe tẹti si gbogbo ohun ti awọn eeyan ba n sọ si wọn amọ ki wọn ni afojusun rere ninu iṣẹ ti wọn yan laayo.

O ṣe afikun pe ti ohun ba le de ipo ti oun wa lonii ko si eeyan kankan ti ko le de ipo agba nidi iṣẹ to ba n ṣe.

Funke ni awọn to ṣẹṣẹ n bọ loke gbọdọ ni afojusun rere pe awọn yoo doke lọjọ kan.

O ni “Mo ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ ki n to de ipo ti mo wa yii.”

“O le ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ yii ṣugbọn ti o ba fẹ tayọ lẹnu isẹ tiata, o ni lati ṣiṣẹ karakara, o ṣi gbọdọ nifẹ iṣẹ ti o yan laayo.”

“O maa koju ọpọlọpọ iṣoro loju ọna ati ga ṣugbọn ti o ba le pa ọkan pọ, ti o dẹ fi ara balẹ wa a de ibi ti o n lọ.”

Akindele tẹsiwaju pe “Ara nnkan ti mi o ṣe ki n lọ sile ijo ni pe mi o mọ bi wọn ṣe n farapamọ.”

O pari ọrọ rẹ pe “Ẹ maa ba ọpọlọpọ ijakulẹ pade ṣugbọn ti ẹ ba rọju ti e ṣi mọ ohun ti ẹ n ṣe, ẹ maa di ibi giga.”