You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayé O,wo bí ọlọ́pàá ṣé hú òkú arábìnrin yìí nínú iyàrá ẹni tó lọ sìn ní gbèsè 50k
Ọlọpaa ni ipinlẹ Bayelsa ti bẹrẹ si ni ṣe iwadii arakunrin kan Joseph Fekala lori ẹsun pe o pa arabinrin kan ti wọn hu oku rẹ jade ninu iyara rẹ ladugbo Okaka.
Iroyin taa gbọ ni pe Kate Oguoh ẹni ọdun marundinlọgbọn naa lọ sin Joseph ni gbese ẹgbẹrun lọna aadọta Naira owo aṣọ ti o ra lọwọ rẹ.
Ibẹ naa ni wọn larakunrin yi ti yin Kate lọrun to si sin oku rẹ sinu iyara rẹ.
Baba Kate, Dick Oguoh,sọ pe iṣẹ aṣọ tita yi ni Kate n ṣe lẹyin igba to pari ẹkọ rẹ ni Fasiti Novena.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ni Ọjọbọ ọjọ Kejidinlogun oṣu Keje ọdun 2022 ni iyawo rẹ pe latio sọ pe Kate ko gbe ipe lori ẹrọ alagbeka rẹ lati aarọ titidi irọlẹ tawọn ti n pe.
O ni oun sọ fun iya Kate pe ko ma jaya wi pe o ṣeeṣe ki o jẹ ''network problem.''
O ni bi ilẹ ba mọ ki wọn wa lọ.
''Lowurọ oni nigba taa tọ ipasẹ rẹ lọ si Okaka nibi to s fun mama rẹ pe oun n lọ sin gbese owo lọwọ ẹni to jẹ ni gbese, o jẹ iyalẹnu lati ri iru ibi to wa''
''Iyawo mii sọ fun mi pe arakunrin to jẹ ẹ ni gbese N50,000 to si kọ lati san owo naa nitori gbogbo igba to ba pe lori ago, kii gbe ipe rẹ''
O tẹsiwaju pe oun beere lọwọ arakunrin naa pe ''nibo ni ọmọ mi wa?.Mo tun bi leere pe nibo ni ọmọ mi wa. O ni oun ko mọ ibi ti ọmọ mi wa''
Nigba ti wọn ko ri esi to tẹ wọn lọrun gba lọdọ rẹ, ni baba Kate ba sọ fun iyawo rẹ pe ko duro koun lọ fẹjọ sun lagọ ọlọpaa.
O ni agọ ọlọpaa lawọn wa ti iyawo oun n pe pada pe wọn ti ri oku ọmọ wọn nibi to pa to si sin si ninu iyara rẹ.
Ọgbẹni Oguoh sọ pe oun gbe awọn ọlọpaa pada wa si ile naa ti wọn si hu oku ọmọ rẹ jade ninu iyara naa ki wọn to gbe lọ si ile iwosan.
Ninu fọnran fidio kan taa ri, niṣe lawọn eeyan rọ yika adugbo ibi ti wọn ti ri oku Kate.
Awọn eeyan pada ṣuru bo afurasi naa ti wọn si dawọ jọ da bantẹ iya fun kawọn ọlọpaa to gba lọwọ wọn.
Ẹwẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni Bayelsa sọ pe awọnm ti gbe afurasi naa Joseph Fekala lọ si ẹka iwadii ọtẹlẹmuyẹ to wa ni olu ilu Bayelsa, Yenagoa.