Bàbá mi ló san owó ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jí mi gbé ní Kogi, kìí ṣe NYSC – Àgùnbánirọ̀

    • Author, Frey Lindsay
    • Role, BBC News

“A gbọ iro ibọn, awakọ wa duro. Wọn si ni ki gbogbo wa sọkalẹ pe ki a doju bolẹ, lẹyin naa ni wọn ko wa lọ sinu igbo.”

Ọrọ to jade lẹnu Patience ti a fi orukọ abisọ rẹ bo laṣiri ree nigba to n sọrọ nipa aṣale ti oun atawọn kan ko sọwọ ajinigbe lọdun 2023 nipinlẹ Kogi.

Agọ awọn agunbanirọ, NYSC, ni Patience n lọ lati sin ilu fun ọdun kan ṣaaju iṣẹlẹ yii.

Lẹyin ti awọn ajinigbe naa paṣẹ fun Patience atawọn eeyan to ku ki wọn wọ inu lọ ni wọn bẹrẹ si n gba gbogbo dukia ọwọ wọn.

Lẹyin naa ni ọkan lara awọn ajinigbe ọhun ni ki Patience pe baba rẹ, ko si sọ fun pe ogun miliọnu naira ni awọn yoo gba ki wọn to tu oun silẹ.

Amọ baba Pastience sọ fun ajinigbe naa pe “Mo sọ fun pe, ti mo na ni ogun miliọnu naira, o ko ni ri ọmọ mi jigbe.

“Nitori ṣe ni yoo lọ si papakọ ofurufu lati lọ si ipinlẹ ti ẹ ti ji gbe pẹlu awọn ẹṣọ alaabo, mi o ni irufẹ owo bẹẹ o.”

Awọn to rọrun lati ji gbe

Fun ọpọlọpọ eeyan, ohun to dara ni NYSC amọ ni bayii ti iṣẹlẹ ijinigbe bẹrẹ si n peleke si, awọn akẹkọọjade ti n bẹru agunbanirọ ki wọn ma baa ji wọn gbe.

Laarin ọdun mẹwaa sẹyin, ko din ni ọgọrin agunbanirọ ti awọn ajinigbe ti jigbe gẹgẹ bii atẹjade ajọ Nigerian Foundation for Investigative Journalism.

Bo tilẹ jẹ pe iye awọn agunbanirọ naa ko to iye eeyan 4,427 ti wọn ji gbe lọdun to kọja, iṣoro ọtọ lo n koju awọn agunbanirọ ọhun.

Igbagbọ wa pe owo wa lọwọ awọn obi awọn agunabnirọ ọhun.

Onimọ kan nipa eto abo, Ikemesit Effiong sọ pe awọn ajinigbe n ri awọn agunbanirọ gẹgẹ bii awọn ti wọn le tete jigbe ni irọrun.

Ai si aabo to peye

Ọpọ awọn ọdọ ni Naijiria lo ti lọ sori ayelujara lati fi ehonu wọn han lori bi wọn ko ṣe le kọ lati ṣe agunbanirọ ati bi ijọba ṣe kuna lati daabo bo wọn.

Lọdun 2021, aworan kan fa ori ayelujara ya, eyii ti wọn ni o kilọ fun awọn agunbanirọ to ba n gba awọn oju ọna kan pe ki wọn murasilẹ lati san owo itusilẹ fun awọ ajinigbe.

Ileeṣẹ iroyin BBC kan si ajọ NSYC lori aworan naa amọ o kọ lati fesi fun wa.

Amọ ninu oṣu Kẹta ọdun yii, adari ajọ NYSC, Yusha’u Ahmed sọ pe awọn agunabnirọ gbọdọ sin ilu nibi ti wọn ba gbe wọn lọ.

O ni “Ẹ fi ọwọ pataki mu eto abo yin, ki ẹ si maa ṣe gbogbo ohun to wa ninu iwe pelebe ọwọ yin.”

Ṣugbọn ni ti Patience ti wọn jigbe ni ibẹrẹpẹpẹ agunbanirọ rẹ, awọn obi rẹ lo wa ọna lati gba itusilẹ rẹ, kii ṣe NYSC.

Ọjọ mẹsan an gbako ni ọdọbinrin naa atawọn akẹgbẹ rẹ lo ni ahamọ ajinigbe ki wọn to gba itusilẹ.

Lẹyin ti baba rẹ dunadura pẹlu awọn ajinigbe naa tan ni wọn to tu silẹ.