Adigunjalè wọ ilé Aubameyang, wọ́n lùú, wọ́n tún kó dúkìá rẹ̀

Aubameyang

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn adigunjale ji awọn nkan olowo iyebiye ko lọ nile agbabọọlu Barcelona, Pierre-Emerick Aubameyang, ni owurọ ọjọ Aje.

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa sọ pe ọkunrin mẹrin to di ihamọra nkan ija oloro lo wọ ile agbabọọlu naa, ti wọn si fi ipa mu lati ṣi ilẹkun ibi to n ko awọn nkan olowo iyebiye pamọ si.

Nibẹ ni wọn ti ko awọn ẹṣọ ara to ko sibẹ lọ.

Iroyin sọ pe awọn adigunjale naa dunkooko mọ Aubameyang ati iyawo rẹ.

Bakan naa ni iroyin naa sọ pe wọn lu u lasiko ikọlu naa.

Igba akọkọ kọ niyii ti adigunjale wọ ile awọn agbabọọlu ni orilẹ-ede Spain.

Eyi to ṣẹlẹ yii si ni igba keji ti wọn wọ ile Aubameyang ni Castelldefels laarin oṣu meji pere.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe igba akọkọ waye nigba ti agbabọọlu naa ati idile rẹ ko si nile.

Awọn agbabọọlu Barcelona miran ti ole ti wọ ile wọn ni Gerard Pique, Ansu Fati, Jordi Alba, Samuel Umtiti ati Coutinho.