You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo èèyàn mẹ́wàá tí ọlọ́pàá ta níbọn lọ́dún 2022
Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lo maa n mu igbe bọnu lórí bàwọn ọlọ́pàá ṣe máa ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀.
Eyi si lo mu kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa bèèrè fún àtúntò iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, amọ síbẹ̀ ìpànìyàn látọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ń peléke si ni.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí si ló fa ìwọ́de tí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà ṣe nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2020 tí wọ́n pè ní #EndSARS.
Iwde yii si ni wọn fi n pè fún ìdádúrò àwọn ọlọ́pàá ni ẹ̀ka to n gbogun ti iwa idigunjale (SARS).
Eyi ko si sẹyin bí wọ́n ṣe máa ń lọ àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ gbà lórí owó wọn àti pípa àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́.
Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù Kẹwàá ni ìjọba àpapọ̀ kéde pípa ẹ̀ka yìí rẹ́.
Sùgbọ́n lẹ́yìn ọdún méjì ti iwọde yii waye, kò fẹ́ ẹ̀ sí ìyàtọ̀ lórí ìdí tí wọ́n fi pawọ́n rẹ́ nítorí káká kó sàn lára ọmọ ìyá àjẹ́, ojoojúmọ́ ní ìròyìn ìpànìyàn látọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ń wáyé.
BBC Yorùbá wá ṣe àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn mẹ́wàá tí ọlọ́pàá yìnbọn mọ́ nínú ọdún 2022 nìkan.
Bolanle Raheem
Ní ọjọ́ Àìkú, ọja ọdún Kérésìmesì ní Bolanle Raheem, tó jẹ́ agbẹjọ́rò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ ọlọ́pàá kan ní agbègbè Ajah, ìpínlẹ̀ Eko.
Bolanle Raheem ẹni ọdún mọ́kànlélógójì tó tún wà nínú oyún oṣù mẹ́fà ni ọlọ́pàá kan, Drambi Vandi yìbọn pa lásìkò tó ń bọ̀ láti òde pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.
Dramdi Vandi, ASP ọlọ́pàá tó yìbọn pa Bolanle Raheem ti fojú ba ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Ẹtì, ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kejìlá tí adájọ́ tó sì ń kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn.
Adájọ́ Adeola Olatunbosan ní kí Vandi lọ máa ṣe fàájì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ná títí ìgbọ́jọ́ yóò fi tẹ̀síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Gafaru Buraimoh
Ọlọ́pàá kan tó jẹ́ ìǹsìpẹ́kítọ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá Ajiwe, Ajah ni ìròyìn ní ó ṣekúpa Buraimoh tó ń gbé ní Happy Estate, Ajah.
Ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́ ọjọ́ keje oṣù Kẹwàá ọdún 2022 ni Buraimoh ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀ lásìkò tó ń kúrò ní ilé ìtajà kan níbi tí ìbọn ọlọ́pàá ti lọ bá a.
Àwọn ọlọ́pàá náà ni wọ́n ń lé àwọn tó ń ṣe bàràǹdà epo bẹntiróòlù ní agbègbè náà tí wàhálà sì bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí ẹnìkan lára àwọn tó ń ta epo lọ́nà àìtọ́ kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá rí epo bẹntiróòlù òun gbà.
Nígbà tó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin ní ọwọ́ ti tẹ ọlọ́pàá tó ṣiṣẹ́ láabi náà tí ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀.
Àmọ́ títí i àsìkò yìí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò fi ojú ọlọ́pàá tó ṣekúpa Buraimoh hàn sóde.
Toba Adedeji
Adedeji, akọ̀ròyìn tó ń ṣiṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ ni ìbọn ba lásìkò tó lọ kọ ìròyìn níbi ètò ìwọ́de kan tí àwọn ọ̀dọ́ kan ń ṣe ní ìlú Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun.
Ní orí afárá Olaiya ni àwọn ọ̀dọ́ náà péjọ sí láti kọrin arò lórí akẹgbẹ́ wọn kan tí ọlọ́pàá ṣekúpa lọ́nà àìtọ́.
Kò ju bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ tí àwọn ẹni náà ń fẹ̀hónú hàn ni àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀ tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Nígbà tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Toba Adedeji ní ọ̀nà méje ni wọ́n ti rán ibi tí ìbọn ti ba òun nítan.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Osun ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ títí di òní wọ́n ò fi ojú ọlọ́pàá tó yìbọn náà hàn.
Koleosho Abayomi
Lásíkò tí àwọn ọlọ́pàá Eko ń gbèrò láti fòfin kí ọ̀kadà má rìn ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Eko ni ìbọn ọlọ́pàá ti bá Abayomi ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ aṣọ́nà ní Lekki Penisunla II.
Àmọ́ ori kó Abayomi yọ lọ́wọ́ ikú nítorí ó kàn farapa lásán níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko nígbà tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ló san gbogbo owó tí wọ́n fi tọ́jú Abayomi nílé ìwòsàn.
Paul Durowaiye
Nítorí omi inú ọ̀rá ni ọlọ́pàá kan ṣe pa Durowaiye ní ìpínlẹ̀ Kogi ní ọjọ́ Kejìlélógún oṣù kìínì ọdún yìí.
Óṣójumíkòró sọ wí pé Durowaiye mu omi inú ọ̀rá tó jẹ́ ti ọlọ́pàá náà tí inú sì bí ọlọ́pàá ọ̀hún kó tó di wí pé ó yìbọn pa Durowaiye.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kogi, Edward Egbuka ní ìwádìí àwọn fi hàn pé ọlọ́pàá náà dá ààbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni náà ni nígbà tí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn.
Igwe Odinaka àti Chikere Obieche
Ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kẹrin ní ọlọ́pàá kan tó ti mu ọtí yó yìbọn pa àwọn méjéèjì yìí níbi ayẹyẹ ọjọ́ìbí kan ní agbègbè Gowon Estate, ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn méjéèjì náà ló jẹ́ oníṣòwò fóònù ní Computer Village, Ikeja tí ìbọn ọlọ́pàá tó ń gbìyànjú láti ṣe ìwúrí fún ẹni tó ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí ṣèṣì ṣíná ìbọn bá àwọn tó ń jó.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọlọ́pàá tó yìbọn náà kò ní lọ láì fojú winá òfin, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò sọ ohunkóhun mọ́ láti ìgbà náà di àsìkò yìí.
Godsent Obhafuoso
Obhafuoso ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀ lásìkò tó lọ bá ọ̀gá rẹ̀ ṣòkú ìyá rẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Esan North, ìpínlẹ̀ Edo lọ́jọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹjọ, ọdún 2022.
Obhafuoso ni wọ́n ní ó ń bá ọ̀gá rẹ̀ ṣa owó tí wọ́n ń na tó sì tún ya fídíò lọ́wọ́ fún ọ̀gá rẹ̀ ni ìbọn ti ọlọ́pàá kan yìn ti lọ ba òun àti ayàwòrán kan tí Obhafuoso sí pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí wọ́n fi máa dé ilé ìwòsàn Irrua.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Edo, Abutu Yaro fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ àmọ́ títí di òní àwọn ẹbí Obhafuoso kò ì tíì rí ìdájọ́ gbà lórí ikú rẹ̀.
Oliver Ezra Barawani
Ní ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹfà ni ọlọ̀pàá kan pa Barawani, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ẹ̀kọ́ pgíga fásitì ìpínlẹ̀ Taraba, lásìkò tó ń wakọ̀ pẹ̀lú ọ̀gá rẹ̀, Liu tó jẹ́ alága ìjọba ìbílẹ̀ kan.
Ní oríkò àyẹ̀wò àwọn ọlọ́pàá ní Kpanti Napo lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jalingo ni ìròyìn ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Emmanuel Joseph
Níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ni ọlọ́pàá kan ti yìbọn pa Joseph lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún ní Cultural Center, Calabar.
Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí Saviour Nyong àti igbákejì abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà, Joseph Bassey tí wọ́n dìjọ ń díje dé ibi ètò ìdìbò náà tí wọ́n sì ń tahùn síra wọn.
Ìròyìn ní ìjà náà ló ṣokùnfà bí ọlọ́pàá ṣe yìbọn ba Joseph láyà tó sì kú lójú ẹsẹ̀.
Kò yẹ kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá máa bo àwọn ọlọ́pàá tó bá tàpá sófin
Ẹ̀wẹ̀, àwọn agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní kò yẹ kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá máa bo àwọn ọlọ́pàá bá ń ṣiṣẹ́ láabi báyìí mọ́lẹ̀.
Wọ́n ní níṣe lọ yẹ kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá máa fi ojú wọn hàn aráyé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tí wọ́n bá mú àwọn afurasí ọ̀daràn.
Wọ́n fi kun pé kò sí nínú òfin tó de iṣẹ́ ọlọ́pàá pé tí ọlọ́pàá bá ṣẹ̀ sí òfin kò yẹ kí wọ́n fi ojú rẹ̀ hàn.