Àdó olóró búrẹ́kẹ lásìkò ìjọsìn àwọn Kátólíìkì, èèyàn mẹ́rin kú, 42 farapa

O kere tan, eeyan mẹrin lo ti jade laye latari ibugbamu kan to waye lasiko ti adura ijọ katoliiki n lọ lorilẹ-ede Philippines.

Aarọ oni ọjọ Aiku ni ibugbamu naa dun nile ẹkọ Mindanao State University, to wa niluu Marawi, eyii ti awọn Musulumi pọ si julọ lorilẹ-ede naa.

Yatọ si awọn mẹrin to jade laye yii, eeyan mejilogoji mii tun farapa yanayana.

Awọn alaṣẹ ilu ti iṣẹlẹ naa ti waye ti sọ pe nnkan ti n pada bọ sipo bayii.

Ẹwẹ, olori ileeṣe ọlọpaa lagbegbe naa, Brig Gen Allan Nobleza ni ẹgbẹ awọn Musulumi kan, Daulah Islamiyah-Maute Group ni awọn fura si pe o ṣeeṣe ko lọwọ ninu ikọlu naa.

Nobleza ni mọkanlan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Musulumi naa lo ku lasiko ti wọn kọlu awọn ọmọ ogun orilẹ-ede ọhun lọjọ Ẹti to kọja ni ilu Datu Hoffer Ampatuan, ti ko jina si Marawi.

O ni o ṣeeṣe ki wọn ṣe ikọlu si awọn olujọsin naa lọna ati gbẹsan awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to jade laye.

Aarẹ Ferdinand Marcos Jr ti bu ẹnu atẹ ikọlu ọhun, eyii to juwe gẹgẹ bii iṣẹ ọwọ awọn atọhunrinwa agbesunmọmi.

Lẹyin naa lo ke si awọn araalu lati lọ fi ọkan wọn balẹ nitori ọwọ yoo tẹ awọn to ṣiṣe laabi naa laipẹ ọjọ.

Nigba ti wọn n sọrọ lori ohun to fa ibugbamu naa, awọn alaṣẹ ni o ṣeeṣe ko jẹ ado oloro ‘grenade’ ni awọn to ṣiṣẹ naa lo.

Nnkan bii ida 80% awọn eeyan orilẹ-ede naa lo jẹ Katoliki, wọn si maa n lo ọgba awọn ile ẹkọ giga fun isin wọn lọpọ igba.