Aláboyún méjì, ọmọdé wà lára àwọn èèyàn tó jóná níbi ìjàmbá ìbúgbàmù Tanker epo nílùú Ọ̀rẹ̀

Ajọ to n ri si oju popo lorilẹede Naijiria, FRSC, ẹka ipinlẹ Ondo ti kede pe eeyan mẹjọ lo padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ ijamba ibugbamu tanker epo to waye ni Ore, nipinlẹ Ondo.

Osojumikoro to ba ikọ ileeṣẹ iroyin abẹlẹ kan sọrọ ni alaboyun meji ati omode mẹta wa lara awọn eeyan to ba isẹlẹ naa lọ.

Nigba to n sọrọ, Ọga agba fun FRSC nipinlẹ Ondo, Ezekiel Son'Allah fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan yii ni padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn bu epo lẹyin ti Tanker ọhun subu.

"Ijamba naa waye nitori ere asapajude dẹrẹba ọkọ n sa, ti eeyan mẹjọ si padanu ẹmi wọn.

"Ori ko Dẹrẹba ọkọ ati ọmọ ọkọ yọ sugbọn awọn olugbe agbegbe naa ti wọn tu sita lati gbọn epo to dasilẹ jona kọja idamọn. Ati gbe oku wọn lọ ile igbokusi ti ile wosan General niluu Ore."

Awọn olugbe agbegbe to ba awọn akọroyin sọrọ ni to ogun eeyan to ba isẹlẹ naa lọ pẹlu alaboyun meji ati ọmọde mẹta , ti awọn miiran si farapa yanayana.

Ko ki i se gbogbo awọn to ba isẹlẹ naa lọ lo lọ gbọn epo- Osojumikoro

Awọn ti isẹlẹ naa soju wọn salaye pe pupọ awọn to ba isẹlẹ naa lọ lo jẹ awọn ti wọn kọja lọ lasiko ti isẹlẹ naa waye

Susan Jerry, Olugbe agbegbe naa fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan kan to ba isẹlẹ naa lọ ni wọn jẹ awọn to n gbọn epo lasiko naa.

"O to ogun eeyan to jona kọja ila. Alaboyun meji ati ọmọde mẹta."

Olugbe miiran, Tijani Diekola ni dẹrẹba tanker lo sọ ọkọ rẹ nu, to si bọ si koto ni bi ago mẹrin abọ lọjọ Aiku

O ni awọn eeyan wa nibi isẹlẹ ijamba naa, ti wọn n gbọn epo titi ti ibugbamu naa fi waye ni ago mẹfa irọlẹ.

"Ni arọ yii, mo ba eeyan mẹwaa to ti jona ti awọn to sumọ tanker naa ko si se damọ mọ. Awọn ẹsọ FRSC ko wọn si apo.

"O seni laanu, obinrin kan to n dana lọwọ padanu ẹmi rẹ lasiko ti n ikan idana rẹ gbana to si jona.

"Alaboyun kan naa to fẹ sọda pẹlu ọmọ mẹta, ti wọn si jọna kọja ila. Ko si ẹni to le du ẹmi wọn."