You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn alátakò lò ń dìtẹ̀, mi ò sọ pé dandan ni ìbò fún APC ní 2027-Sego, Alaga NURTW Eko
Ọrọ to gbe Alaga ẹgbẹ awọn onimọto (NURTW), ẹka ti ipinlẹ Eko, iyẹn Alhaji Mustapha Olanrewaju ti gbogbo eeyan mọ si Sego, de ileeṣẹ atọpinpin DSS, ti mu ki ọkunrin naa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gan-an.
Iroyin to kọkọ gbode da le ori fidio kan to ṣafihan Alhaji Sego, nibi to ti ni ẹnikẹni to ba ṣe aṣiṣẹ, to dibo fun ẹgbẹ oṣelu miran yatọ si APC ni 2027 yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Ninu fidio naa ni Sego ti ni APC ni ẹgbẹ awọn, ẹni to ba si lodi si i yoo ba awọn nibẹ lati jiya rẹ.
Fidio yii lo di ariwo, pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n sọ pe idunkooko mọni ni ọrọ ti ọga onimọto naa sọ yii.
Ọpọ eeyan lo koro oju si ọrọ naa, ti wọn ni o lodi labẹ ofin Naijiria lati maa paṣẹ pe ẹgbẹ kan ni awọn eeyan gbọdọ dibo fun, niwọn igba ti ofin ti fi aaye sile fun kaluku lati ṣe ẹgbẹ oṣelu to ba wu u.
Ewu to rọ mọ ọrọ Sego, ati iwoye pe ọrọ naa le da rogbodiyan silẹ lo fa a to fi di ohun ti DSS ranṣẹ pe Alaga awọn onimọto Eko naa si, lati waa sọ ti ẹnu rẹ.
Nigba to si de lati ọdọ awọn DSS lo ṣe fidio mi-in to fi ṣalaye pe:
"Irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi, ọ́rọ́ NURTW ni mò ń sọ"
Nigba to n ṣalaye ninu fidio keji lẹyin to ti ọfiisi awọn DSS de, Sego sọ pe:
"Mo ti wa lọdọ awọn DSS lati aarọ, mo ṣẹṣẹ kuro nibẹ ni nnkan bii aago meje ni. Wọn ṣẹṣẹ gba beeli mi.
"Mo gbọ pe awọn kan n sọ pe nitori mo sọrọ si awọn eeyan kan ni wọn ṣe ranṣẹ pe mi. Ahesọ lasan niyẹn, ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ni mo n sọ.
"Gbogbo wa la mọ pe gbogbo ẹgbẹ naa lo ni alatako tiẹ, bi awọn oloṣelu ṣe ni alatako, ti awọn mẹkaniiki naa ni tiwọn lo ṣe ri.
"Awọn alatako NURTW ti wọn o fẹ ki n ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ mi lo wa nidii ọrọ yii.
"Wọn n wa ọna ti wọn maa fi da ẹgbẹ yii ru, awọn ni mo n ba wi ti mo si n jẹ ki gbogbo aye, ati ọlọpaa ati DSS mọ, pe ẹgbẹ alaafia ni NURTW."
O fi kun un pe ibajẹ lasan lo wa nidii ọrọ yii, nitori kaluku ni aaye wa fun lati ṣe ẹgbẹ to ba wu u.
Sego sọ pe asiko to yẹ koun wa lọfiisi, koun maa mojuto ọrọ awọn onimọto loun fi wa lọdọ awọn DSS, ti wọn n fi ọrọ wa oun lẹnu wo. O ni eyi fi han pe awọn ọlọtẹ to fẹẹ fi ogun afi-akoko-ẹni-ṣofo ba oun ja ni wọn wa nidii ọrọ naa, ti wọn si fẹẹ da NURTW Eko ru.
Nígbà tí MC Oluomo náà sọ ohun tó jọ bíi èyí ní 2023
Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti iru iṣẹlẹ bayii yoo waye laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ipinlẹ Eko, nitori ẹgbẹ oṣelu APC.
Loṣu Kẹta ọdun 2023, lasiko ti ipolongo ibo n lọ lọwọ, Alaga ẹgbẹ State Parks Management Committee, Alhaji Musiliu Akinsaya (MC Oluomo) naa sọrọ to di awuyewuye bi eyi.
Ninu fidio kan loju opo Twitter igba naa, ni MC Oluomo ti n dunkooko mọ awọn ẹya Igbo to wa nipinlẹ Eko, pe wọn gbọdọ dibo fun APC, bi bẹẹ kọ, ki wọn ma wulẹ jade dibo rara.
"Ọrọ ija kọ, awa Yoruba ni ka kọkọ debẹ ka si kọkọ dibo. Ti a ba ti dibo tan, a o maa wo ohun ti ẹ maa ṣe, nitori a ti bẹ yin.
"Ti ẹ ba lọ ṣe aṣiṣe kan, Iya Chukwudi, sọ fun wọn, ti ẹ ko ba ni i dibo fun wa, ẹ yaa jokoo sile."
Ọrọ yii di ariwo nigba naa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko si ni awọn koro oju si i, nitori ofin ko faaye gba iru ẹ.
Ni ti Sego to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ yii naa, ẹ o ranti pe awọn ẹya Igbo ti wọn jẹ ọmọlẹyin Peter Obi, oludije ipo aarẹ, ti ni ki ijọba ma ṣe wo ọrọ naa niran rara.
Wọn lo yẹ ki wọn fi ọwọ ofin mu Sego to sọ iru ẹ ni.
Kí ni ofin sọ nipa ẹtọ lati dibo fun ẹgbẹ to ba wu eeyan, ati idunkooko mọ eeyan lati dibo fun ẹni ti ko wu u?
Lati mọ oju ti ofin fi wo ọrọ yii, ati ẹtọ ọmọniyan labẹ ofin lati dibo fun ẹgbẹ to ba wu u lasiko ibo, BBC News Yoruba, ba Amofin Kayode Akinsola, ọga ẹka ẹkọ nipa imọ ofin ni Chrisland University, Abeokuta ati agbẹjọro lorilẹede Naijiria, sọrọ.
"Ọrọ ti Adari awọn onimọto l'Eko sọ jẹ ohun to yani lẹnu, ti ko si si ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin orilẹede Naijiria .
"Ofin orilẹede Naijiria, ori ogoji rẹ, sọ pe ẹnikẹni lo ni anfaani lati darapọ mọ ẹgbẹ yoowu, tabi ẹgbẹ oṣelu yoowu to ba wu u lati inu ọkan rẹ.
"Ti awọn to jẹ adari ẹgbẹ onimọto ba n sọ pe o di dandan pe ki wọn darapọ pẹlu ẹgbẹ kan, eyi jẹ ohun ti ko dara, o si n pe fun iwa jagidijagan.
"Ti a ba ri irufẹ ẹni to n pe, pe ẹgbẹ oṣelu kan ni ki wọn dibo fun, ko dara rara"
Bẹẹ ni Amofin Kayode Akinsola kasẹ ọrọ naa nilẹ.
Kí ni ofin INEC wí lórí ọ̀rọ̀ yìí?
Ninu alakalẹ ofin ajọ eleto idibo Naijiria, Independent National Electoral Commission (INEC), iwa to lodi sofin ni lati paṣẹ fun ẹnikan pe ẹgbẹ osẹlu kan lo gbọdọ dibo fun.
Fifi ipa mu eeyan lati dibo, jẹ iwa to lodi sofin ajọ eleto idibo ilẹ Naijria gẹgẹ bo ṣe wa loju opo wọn .
Ofin wọn ti i ṣẹ "The Electoral Act of 2022, sọ pe idibo jẹ ohun to wu eeyan lati tẹlẹ lọkan rẹ , ki i ṣe ohun ti a fi ipa mu un lati ṣe.
Lilo agbara lori ẹlomi-in lati dibo fun ẹgbẹ kan si jẹ iwa ọdaran labẹ abala 128 ofin INEC.
Koda, owo itanran miliọnu kan naira tabi ẹwọn ọdun mẹta ni INEC sọ pe ẹni to ba jẹbi ẹsun yii yoo fi gbara.