You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìgbeyàwó ọ̀pọ̀ èèyàn tó wáyé ní ṣọ́ọ̀ṣì kan níbi tí ọkùnrin ti ń fẹ́ ju ìyàwó kan lọ
- Author, Khanyisile Ngcobo
- Role, BBC News, Zuurbekom
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Iyawo Evelyn Sekgalakane ree to wọ aṣọ funfun to n rin pẹlu Shirley Molala ti yoo di iyaale rẹ nibi eto igbeyawo ọlọpọ eeyan to waye nile ijọsin kan to faye gba ki ọkunrin ni iyawo meji tabi ju bẹẹ lọ.
Lesiba Molala to jẹ ọkọ iyawo lo wa lẹyin wọn nibi eto igbeyawo ọhun to waye ni ṣọọṣi International Pentecostal Holiness Church (IPHC) niluu Johannesburg.
Igbeyawo marunlelaadọta lo waye nile ijọsin naa lọjọ ayẹyẹ Ajinde to kọja lọ.
Meje ninu awọn igbeyawo yii lawọn ọkọ ti n fẹ iyawo mii le eyi to wa nile wọn, amọ, awọn ọkọ iyawo yoku lanfaani lati fẹ iyawo mii to ba wu wọn lọjọ iwaju.
Loorekoore ni ọrọ n jade ni ṣọọṣi nibi eto igbeyawo ọhun wi pe Ọlọrun faye gba ki ọkunrin ni ju iyawo kan lọ.
Shirley to jẹ iyawo keji Molala ti wọn ti jọ fẹ ara wọn fun ọdun mẹẹdọgbọn sọ pe oun fẹran igbeyawo ti ọkunrin ba fẹ ju iyawo kan lọ tori o wa ninu iwe mimọ Bibeli.
Iyawo akọkọ Molala eyi to ti ku bayii lo mu Shirley wa, nigba ti iyawo kẹta naa darapọ mọ ẹbi Molala amọ oun naa fi idile yii silẹ lasiko ti aawọ kan ṣẹlẹ ninu ijọ.
''Awa iyawo mẹtẹẹta jọ n ṣe ajọṣepọ debi wi pe a maa n wọ iru aṣọ kan naa.
Ninu ẹbi Molala ni mo ti kọ ẹkọ yii, idi niyẹn ti emi naa fi ko Evelyn mọra.
Bi ẹrọ gbohun-gbohun ṣe n ke lala ni ni ẹgbẹẹgbẹru eeyan to wa nibi eto igbeyawo naa n pariwo pẹlu idunnu.
Bayii lawọn ọkọ ati iyawo tawọn eeyan tori wọn pejọ wọ inu ṣọọṣi ti aṣọ si n pe aṣọ ranṣẹ.
Ṣaaju ki wọn to wọle sinu ile ijọsin lawọn oṣiṣẹ ṣọọṣi maa ti kọkọ ṣe ayẹwo aṣọ ti wọn wọ lati ri pe aṣọ ti wọn wọ ko fi ara silẹ.
Awọn oṣiṣẹ ṣọọṣi si ri pe awọn iyawo fi aṣo bo ori wọn ki wọn to jẹ ki wọn wọle.
Lara ofin ile ijọsin naa ni pe awọn ọkunrin ko gbọdọ jokoo pọ pẹlu obinrin, ọtọọtọ laye wọn.
Molala sọ fun BBC wi pe ''nigba ti mo darapọ mọ ijọ yii ni mo mọ pe ọkunrin le fẹ ju iyawo kan lọ.
Bakan naa ni mo tun gbọ pe ile ijọsin yii ko faye gba ki obinrin ati ọkunrin maa fẹ ara wọn.
Lẹyin naa ni mo ri pe iyawo kan ko le to fun mi, ti mo si pinnu lati fẹ iyawo mii.''
Igba mẹta ni iru igbeyawo yii maa n waye lọdun nile ijọsin yii lasiko ọdun Ajinde, ninu oṣu Kẹsan an ati oṣu Kejila.
Adari ijọ Leonard Frederick G. Modise naa wọ inu ṣọọṣi lẹyin tawọn ọkọ ati iyawo ti wa ni ijokoo.
Tilu tifọn ni wọn fi ki adari ijọ naa kaabọ pẹlu ẹbi rẹ sibi ayẹyẹ igbeyawo naa.
Akọroyin BBC ba Molala ati Evelyn sọrọ ṣaaju ki eto igbeyawo ọhun to bẹrẹ.
Evelyn sọ fun BBC pe bi wọn ba gun ẹṣin ninu oun, wọn o le kọ ẹsẹ.
Isin fun eto igbeyawo naa pari ni bii ago mẹwaa alẹ pẹlu adura lati ẹnu alufaa ijọ naa, Ọgbẹni Modise fawọn ọkọ ati iyawo tuntun.
Nibi eto igbeyawo ni aṣọ ti maa n pe aṣọ ranṣẹ ni South Africa, amọ, siso ọpọ eeyan ninu igbeyawo lẹẹkan ṣoṣo ko wọpọ.
Bo tilẹ jẹ wi pe ofin faye gba ki ọkunrin ju iyawo kan lọ ni South Africa, kootu adugbo ni wọn ti maa ṣe iforkọsilẹ iru igbeyawo bẹẹ, ayẹyẹ iru igbeyawo yii kii si waye ni ṣọọṣi.
Amọ, awọn eeyan mọ ijọ IPHC gẹgẹ bii ijọ ilẹ Afirika to da duro ti o si maa so awọn eeyan pọ ninu iru igbeyawo bẹẹ niwọn igba ti wọn ba ti forukọ silẹ pẹlu ijọba.
Oṣiṣẹ ijọ IPHC kan, Mpho Makwana sọ fun BBC pe ''ijọ yii maa n kawọn eeyan nipa fifẹ ju iyawo kan lọ.
Ijọ naa si ti gbọrẹgẹjigẹ sii ju bi o ti ri lasiko ti wọn ṣẹṣẹ da a silẹ niluu Soweto lọdun 1962 lọ, awọn ọmọ ijọ wa ti le ni miliọnu mẹta bayii.''
Lọdun 1991 ni Molala sẹ igbayawo pẹlu aya rẹ akọkọ, lẹyin ọdun mẹfa to darapọ mọ ijọ naa
Lẹyin ọdun mẹsan an ni Molala ati iyawo rẹ sọ asọyepọ lori ati gbe iyawo mii fun Molala, ti wọn si fẹnu ko lori Shirley ẹni ọdun mẹtalelogun.
Evelyn sọ pe o gba oun lakoko diẹ koun to faramọ pe koun fẹ ọkunrin to ti ni iyawo nile tẹlẹ.
Evelyn to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogoji dagba sinu ile ijọsin IPHC, amọ, o fi ijọ naa silẹ fun igba kan ti o si bimọ mẹta fun ẹlomiran ko to pada sinu ijọ naa.
Ni bayii ti Molala ti ṣe igbeyawo pẹlu rẹ, gbogbo ọmọ ti Evelyn ti bi tẹlẹ ti di ọmọ rẹ eyi to jẹ ki Molala ni ọmọ mẹtala bayii.
Aṣa orilẹede South Africa faye ki ọkunrin ni ju iyawo kan lọ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ni ko faramọ ki ọkunrin ni ju iyawo kan lọ.
Ọjọgbọn Musa Xulu to jẹ onimọ nipa aṣa ati ẹsin ni South Africa sọ pe o ṣee ṣe ki eeyan ri awọn ti wọn ti lugbadi arun HIV/AIDS ni ibẹrẹ ajakalẹ arun naa lara iru awọn igbeyawo yii.
Ọgbẹni Makwana ni ijọba IPHC ti ṣe ifilọlẹ igbimọ kan lati bi ọdun mẹwaa sẹyin eyi to n ṣayẹwo fawọn to ba fẹ ṣe igbeyawo lati mo bo ya wọn larun HIV/AIDS.
O ni ijọ IPHC ko ni so awọn to ba larun HIV/AIDS pọ ti ayẹwo ba ti fidi rẹ mulẹ.
Ọgbẹni Makwana fikun ọrọ rẹ wi pe ọkunrin ati obinrin ti wọn ṣe igbeyawo gbọdọ fi esi ayẹwo wọn han ara wọn.
O ni eyi ni ko jẹ ki awọn ọkọ ati iyawo to n kọ ara wọn silẹ pọ lẹyim igbeyawo.
Ọjọgbọn Xulu ni ijọ IPHC to idaji ilana rẹ da lori Bibeli nigba ti iadji yoku da lori aṣa Afirika mọ bi wọn ṣe maa n yanju aawọ to a suyọ ninu irufẹ awọn igbeyawo bayii.
Makwana ni ijọ IPHC maa n ṣeto to fẹsẹ rinlẹ fawọn to ba fẹ fẹ ara wọn sile ni kete ti ijọ ba ti mọ.
Ọpọ awọn lọkọ laya ni kii mọ ara wọn rara ki wọn to bẹrẹ irinajo ifẹ wọn.
Iru awọn tọkọ taya bẹẹ ni Freddy Letsoalo ẹni ọdun marundinlogoji ati Rendani Maemu ẹni ọdun mọkanlelọgbọn.
Awọn naa wa lara lọkọ laya ti wọn ṣe igbeyawo ni Zuurbekom lasiko ọdun Ajinde to lọ.
Nibi eto igbeyawo kan lawọn mejeeji ti kọkọ pade ara ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin.
Nigba to ya ni wọn di ọrẹ lori aapu Facebook, nibi ti wọn o gbọdọ ki ara wọn ju ọjọ ibi lasan lọ.
Loṣu Kejila ọdun 2024 ni Letsoalo sọ fun ẹbi rẹ ati igbimọ alaṣẹ ijọ IPHC pe oun nifẹ ẹ Maemu lati fi ṣe aya.
Maemu ni ''mi o kọkọ mọ pe o nifẹ mi, inu mi dun nigba ti mo mọ.
Mo bẹrẹ si ni ro nipa bi ọjọ igbeyawo mii yoo ṣe ri.
Iran Maemu wa si imuṣẹ nigba ti wọn so awọn mejeeji pọ gẹgẹ bii lọkọlaya.
Bi awọn mejeeji ti n dawọọ igbeyawo wọn ni wọn tun jọ gbagbọ wi pe Letsoalo le fẹ iyawo keji lọjọ iwaju.