You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló fa ìwọ́de tí ìròyìn sọ pé ó ti gba ẹ̀mí èèyàn mẹ́rìndínlógún báyìí ní Kenya?
Ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan ni Kenya, Amnesty Kenya, ti sọ pe ko din ni eeyan mẹrindinlogun (16) to ku, ti ọpọ si farapa lasiko ti wọn n ṣewọde tako Aarẹ orilẹede naa, William Ruto.
Adari Amnesty Kenya, Irungu Houghton, sọ fun BBC pe lasiko ti awọn eeyan naa koju awọn ọlọpaa ti ko fẹ ki ifẹhonuhan naa waye ni wọn pade iku ojiji pẹlu ibọn ti wọn yin mọ wọn.
Ifẹhonuhan yii waye l'Ọjọruu, ni Nairobi, olu ilu Kenya ati awọn agbegbe mi-in, lẹyin ọdun kan ti iwọde agbayanu waye, nibi ti ọpọ eeyan ti ku latari ofin owo ori ti Aarẹ Ruto ṣe nigba naa.
Ariwo "Ruto must go", to tumọ si pe Aarẹ Ruto gbọdọ fi ipo olori ilu naa silẹ ni awọn olufẹhonuhan naa n pa.
Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ilu naa ko ti i sọ iye eeyan to ba rogbodiyan Ọjọruu naa lọ, ẹgbẹ awọn dokita ati tawọn amofin Kenya ati ẹgbẹ to n ri si iṣẹ ọlọpaa, kede ninu atẹjade wọn, pe ko din ni eeyan mẹjọ to ku ninu awọn olufẹhonuhan.
"Ninu eeyan irinwo (400) to farapa, awọn mẹtalelọgọrin (83) ni wọn nilo itọju ara ọtọ, awọn mẹjọ si fara gba ọta ibọn. Ọlọpaa mẹta wa lara awọn to farapa naa "
Bẹẹ ni atẹjade apapọ naa wi.
Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ William Ruto rọ awọn to n fẹhonu han lati fiye denu.
O ni ko si ibo mi-in ti wọn le lọ bi wọn ba ko hila-hilo ba Kenya.
Kí ló fa rògbòdìyàn gan-an?
Ofin afikun owo ori ti Aarẹ Ruto ṣe loṣu Kẹfa ọdun 2024, eyi ti awọn ọdọ tako lo kọkọ fa wahala lorilẹede Kenya.
Ida kan aabọ, (1.5%) ni Ruto paṣẹ pe ki awọn araalu bẹrẹ si I san loṣooṣu, kijọba le fi ṣeto awọn ile olowo pọọku.
Bakan naa ni wọn fi owo ori le burẹdi ti araalu n jẹ, ati awọn afikun miran.
Eyi lo mu awọn ọdọ tu sita, wọn si tun gba ori ẹka TikTok lọ lati lodi si ofin naa.
Awọn ọdọ ṣalaye pe owo ori gọbọi ni ijọba n gba lọwọ araalu tẹlẹ, ko si sohun kan ti awọn ri jẹ bii ere.
Wọn koju awọn ọlọpaa to n yin taju-taju, wọn si wọde ni olu ilu, Nairobi.
Ifẹhonuhan naa nipa lori awọn agbegbe ọrọ aje ni Kenya, awọn eeyan si ku sinu ifẹhonuhan ọhun.
Iwadii BBC ṣafihan aworan to le ni ẹgbẹrun marun-un, to fi han pe awọn ti wọn yinbọn pa ko ni nnkan ija lọwọ lasiko iwọde naa.
Ni iranti awọn to di oloogbe naa ni wọn ṣe tun bẹrẹ iwọde mi-in to waye l'Ọjọruu ọsẹ yii.
Bakan naa ni iku Albert Ojwang, ẹni to ku si ahamọ ọlọpaa laipẹ yii, n bi awọn eeyan Kenya ninu.
Ṣaaju ni awọn ọlọpaa ti sọ pe oloogbe naa lo huwa to fa iku rẹ ninu ahamọ, ki ayẹwo oku too fidi rẹ mulẹ pe iku naa waye lẹyin ti wọn lu u lalubami ni.
Iku to pa ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Boniface Kariuki, lasiko iwode to tako ijọba lọsẹ to kọja, tun jẹ idi miran ti awọn eeyan fi n fi ẹhonu han
Ti nnkan ko si rọgbọ ni Kenya lasiko yii.